Àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń lo àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára sọ pé ilé ẹjọ́ kan ní orílẹ̀ èdè Finland ti dá ẹjọ́ pé kí wọ́n tú Simon Ekpa, ẹnì kan tó ń jà fún òmìnira Biafra, tí wọ́n rán lọ sí ẹ̀wọ̀n ṣílẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n ti pín ọ̀rọ̀ yìí lórí Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ orí ayélujára àti Instagram, ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán tàbí fídíò síta.
Ọ̀rọ̀ yìí tún sọ pé ilé ẹjọ́ kan ní Finland ní kí wọ́n fún Ekpa ní àádọ́ta ẹgbẹ̀rún dọ́là owó gbàmábínú lẹ́hìn ìgbà tí àwọn ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kùnà láti wá sí ilé ẹjọ́.
Adájọ́ kan tí wọ́n kò dá orúkọ rẹ̀ ni wọ́n ní ó sọ ọ̀rọ̀ yìí lórí ayélujára.
“Ilé ẹjọ́ kan ní Finland ti dá ẹjọ́ pé kí wọ́n tú Simon Ekpa, ajàfúnẹ̀tọ́ tó ń jà fún òmìnira Biafra ṣílẹ̀ lẹ́hìn ìgbà tí ìjọba Nàìjíríà kùnà láti wá sí ilé ẹjọ́ láti fi ẹ̀rí hàn nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ọkùnrin yìí,” báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí se sọ.
“Gẹ́gẹ́bí ìdájọ́ yìí se sọ, fifi Ekpa sí àtìmọ́lé “lòdì sófin àti wí pé ọ̀rọ̀ òsèlú ni”, báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí tún sọ. Wọ́n ní ilé ẹjọ́ sì ní kí wọ́n fún un ní àádọ́ta ẹgbẹ̀rún dọ́là owó gbàmábínú nítorí pé wọ́n ran lọ sí ẹ̀wọ̀n lọ́nà tó lòdì sófin.
Àwọn ènìyàn ní lẹ́hìn ìdájọ́, olórí àwọn adájọ́ sọ pé: “Simon Ekpa ti ní àǹfààní láti rìn bí ó se fẹ́ lábẹ́ òfin Finland. Ó ní ẹ̀tọ́ láti sọ èrò ọkàn rẹ̀ àti láti jà fún ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́nà tí kò bá lòdì sófin,” báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí se sọ.
Wọ́n ní lẹ́hìn tí wọ́n fi sílẹ̀, ó sọ pé: “Wọ́n tiraka láti pa mí lẹ́nu mọ́. Àmọ́, òtítọ́ kò seé tí mọ́ ẹ̀wọ̀n. Ìṣẹ́gun yìí kì í se tèmi nìkan-ìṣẹ́gun àwọn ènìyàn Biafra àti ti àwọn ènìyàn tí wọ́n ń jà fún ẹ̀tọ́ ni,” báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí se sọ.
Ibi kan lórí Facebook tí ó ń jẹ́ “I News”, tí ó ní àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún aadọjọ àti méje tí wọ́n ń tẹ̀lée fi ọ̀rọ̀ yìí síta.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck, ti TheCable Newspaper ṣàkíyèsí pé ara àwọn ènìyàn àti àwọn ibì kan tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí síta jẹ́ àwọn alátìlẹ́hìn Ekpa.
O lè rí ọ̀rọ̀ yìí níbí, níbí àti níbí.
ÀWỌN OHUN TÍ Ó YẸ KÍ Ẹ KỌ́KỌ́ MỌ̀ NÍPA Ọ̀RỌ̀ YÌÍ
Ní ọjọ́ kìíní, osù kẹsàn-án, ọdún 2025, ilé ẹjọ́ kan ní Paijat-Hame ní Finland dá ẹjọ́ pé kí ìjọba orílẹ̀ èdè Finland fi Ekpa sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà nítorí pé ó mú àìfọkànbalẹ̀ bá àwọn ènìyàn (terrorism Offences).
Àwọn adájọ́ mẹ́ta tí wọ́n dá ẹjọ́ yìí sọ pé ó jẹ ẹ̀bi ẹ̀sùn yìí. Wọ́n ní ó lo àǹfààní pé ó ní “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń tẹ̀lée lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára” láti fa àìfọkànbalẹ̀ fún àwọn ènìyàn ní gúúsù ilà oòrùn Nàìjíríà (Southeast, Nigeria) láàárín osù kẹjọ, ọdún 2021 àti osù kọkànlá, ọdún 2024.
Ara ẹ̀sùn tí ó jẹ́ kí wọ́n rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ní jìbìtì owó orí àti àṣemáṣe tó se nípa òfin kan.
Gẹ́gẹ́bí òfin Finland se sọ, Ekpa ní ọgbọ́n ọjọ́ láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn (file an appeal case) lórí ìdájọ́ yìí. Èyí túmọ̀ sí pé kò gbọ́dọ̀ kọjá ọjọ́ kìíní, osù kẹwàá, ọdún 2025 kó tó pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.
CableCheck kò ríi dájú pé Ekpa ti pe ẹjọ́ yìí, nítorí pé Kaarle Gummerus, agbẹjọ́rò rẹ̀ kò tíì dáhùn àwọn ìbéèrè tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK TÚN SE RÈÉ
CableCheck se àyẹ̀wò àwọn ibi tí àwọn ilé isẹ́ ìròyìn ti máa ń gbé ìròyìn jáde lórí ayélujára láti lè mọ̀ bóyá ilé ẹjọ́ mìíràn ti pàṣẹ pé kí wọ́n tú Ekpa sílẹ̀ ní àtìmọ́lé bí ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn ń pín ká yìí se sọ.
A ríi pé kò sí ilé isẹ́ ìròyìn tí ó seé gbàgbọ́ tó gbé ọ̀rọ̀ yìí jáde.
Láti ìgbà tí wọ́n ti fi sí ẹ̀wọ̀n ní ọjọ́ kìíní, osù kẹsàn-án, ọdún 2025, kò sí ìròyìn tàbí ọ̀rọ̀ kankan tó sọ pé ilé ẹjọ́ kan fẹ́ jókòó lórí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ọ̀rọ̀ yìí ní Finland títí di ọjọ́ kejilelogun, osù kẹwàá, ọdún 2025.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Irọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí.