Fídíò kan tí Olumulo kan tí a mọ̀ sí Hichief Sunny Odogwu lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ ti sọ pé ilé ẹjọ́ tí a gbekalẹ láti yanjú aawọ ìbò sọ pé Kennedy Pela, Ólùdíje nínú ẹgbẹ́ òsèlú àwọn òṣìṣẹ́ ni ó ṣe àṣeyọrí nínú ìbò Gómìnà ní ọdún 2023 ní Ìpínlẹ̀ Delta.
Wọ́n fi Fídíò ìṣẹ́jú mẹ́fà náà síta ní ọjọ́ kọkanlelọgbọn, oṣù kẹjọ.
“KÉRE O: Ilé ẹjọ́ kotẹmilọrun sọ wí pé Ken Pela, Ólùdíje fún Ipò Gómìnà nínú ẹgbẹ́ òsèlú àwọn òṣìṣẹ́ (Labor Party-LP) ni ó ṣe aseyege nínú ìdíje fún Ipò Gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Delta,” báyìí ni àkòrí atẹjade tí àwọn ènìyàn wò/rí ní ìgbà ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin, tí wọ́n fèsì sí ní ọna igba ó lé ní ọgọ́ta àti mẹ́fà, tí wọ́n sì fẹ́ràn ní ọ̀nà ẹẹdegbèje ṣe wí.
Olumulo yìí sọ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n rí fídíò yìí kí wọn pín in.
ISARIDAJU
Nínú atẹjade tí kò pẹ sẹhin tí TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe, ilé ẹjọ́ kotẹmilọrun ní Abuja pàṣẹ pé kí ilé ẹjọ́ kan ní Ìpínlẹ̀ Delta tí a gbekalẹ láti yanjú àríyànjiyàn ìbò Gómìnà gbọ ẹjọ́ Pela.
The Independent National Electoral Commission (àjọ tí ó ń ṣàkóso ọ̀rọ̀ ìbò ní Nàìjíríà) sọ wí pé Sheriff Oborevwori, Ólùdíje nínú ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party (PDP) ni ó ṣe àṣeyọrí nínú ìbò tí a ṣe ni ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kẹta ní Ìpínlẹ̀ náà.
Ólùdíje yìí ní ìbò ọọdunrun ó lè ní òjìlénígba ó dín mẹ́fà tí ó sì fi ìdí Ovie Omo-Agege, Ólùdíje fún Ipò Gómìnà nínú ẹgbẹ́ òsèlú All Progressives Congress (APC), ẹni tí ó ní ìbò òjìlénígba àti ìgbà ó dín mọkandinlọgbọn rẹ mi.
Pela gbé ipò kẹta. Ó ní ìbò ẹgbẹrun mejidinlaaadọta ó lé ní mẹtadinlọgbọn nígbà tí Great Ogboru, Ólùdíje fún Ipò Gómìnà nínú ẹgbẹ́ òsèlú All Progressives Grand Alliance (APGA) ṣe ipò kẹrin pẹ̀lú ìbò ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá ó lé ní ookanlelogun.
Pela àti ẹgbẹ́ Òṣèlú rẹ̀ kọ ìwé ipẹjọ láti lè sọ pé àwọn Ólùdíje yòókù tí wọ́n ṣe ipò Kínní ati èkejì tí a sì fi ẹ̀sùn afọwọra kan tí wọ́n ko sì tẹle òfin ìdìbò kò yẹ kí wọ́n kopa ninu ìdìbò náà.
Wọ́n ní kí ilé ẹjọ́ náà kéde Pela gẹ́gẹ́bí ẹni tí ó se àṣeyọrí tàbí kí wọ́n fagile ìbò náà kí wọ́n sì tún-un ṣe.
ÌDÁJỌ́ ILÉ ẸJỌ KOTẸMILỌRUN
Nígbà tí ilé ẹjọ́ kọ́kọ́ wo ẹjọ́ yìí, Damian Dodo, agbẹjọro fun Gómìnà àti igbakeji rẹ̀ sọ pé wọn tí pá ẹjọ́ ẹgbẹ́ òsèlú àwọn òṣìṣẹ́ tì.
Ó ní wí pé olupẹjọ kò lo ọjọ́ méje tí òfin sọ fún ìpẹjo àkọ́kọ́ tí ó wáyé ní ọjọ́ kọkàndínlógún kí ìparí ẹjọ́ tó wáyé.
Asiwaju àwọn agbẹjọro fún Gómìnà àti igbakeji rẹ̀ sọ pé olupẹjọ pe ẹjọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ma gbọ ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù karùn-ún, kí ẹjọ́ tó wá sopin. Nípa ìdí èyí, ẹjọ́ tó pè yìí kò dáa tó. Ó yẹ kí a daanu ni.
C.H. Ahuchaogu, alaga àwọn tí ó ń jókòó lórí ẹjọ́ náà da ẹjọ́ náà ni nígbà tí ó ń ṣe ìdájọ́.
Ọ̀rọ̀ yìí bí Pela àti ẹgbẹ́ Òṣèlú àwọn òṣìṣẹ́ nínú. Wọ́n sì kọri sì ilé ẹjọ́ kotẹmilọrun.
Ni ọjọ́ kọkanlelọgbọn, oṣù kẹjọ, ilé ẹjọ́ kotẹmilọrun dáhùn sí ọ̀rọ̀ yìí. Wọ́n sì ní pe ki àwọn adajọ tún yẹ ọ̀rọ̀ náà wò.
BI A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Atẹjade tí ó sọ pé ilé ẹjọ́ tí a gbekalẹ láti yanjú aawọ ìbò sọ pé Pela ni ó ṣe àṣeyọrí gẹ́gẹ́bí Gómìnà nínú ìdíje fún Ipò Gómìnà Delta kìí ṣe òótọ́.