Ìjọ Christ Embassy sọ wi pé àwọn kò gbóríyìn fún Bọla Tinubu. Wọ́n ní irọ́ gbáà ni ọ̀rọ̀ yìí ti àwọn ènìyàn ń pín kiri lórí ẹ̀rọ ayélujára.
Àwọn ènìyàn ní Chris Oyakhilome, Oludari ìjọ yìí ni ó sọ ọ̀rọ̀ yìí.
Wọ́n ní ó ṣọ wí pé Tinubu jẹ́ arákùnrin tí ó wà láti ilé Pharaoh, tí ó rí ojú rere Ọlọ́run.
Gẹ́gẹ́bí bí ahesọ yìí ṣe wí, Tinubu, ẹni tí ó jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó tẹ́lẹ̀rí, ẹni tí àwọn ènìyàn ti ṣe inúnibíni sí ni yóò mú ìlọsíwájú dé bá Nàìjíríà.
“Lára wa se àtilẹyin fún Ọsinbajo, igbá-kejì Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà nígbà ìdíjedupò nínú ẹgbẹ́ òsèlú APC, mo sì kọ nkan ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti ṣe àtakò BAT, àti láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ pé àsìkò tó fún ẹlòmíràn,” lára ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn ṣe atunpin rẹ̀ náà ni ó wí báyìí.
“Oríṣiríṣi ìdènà ni àwọn ènìyàn ṣe fún-un. N kò tíì ṣe alabapade ẹni tí àwọn ènìyàn p’ẹgan rẹ̀ tó báyìí. Àmọ́, ó borí àwọn ìdènà. Fún bíi ọdún mẹ́jọ tí ó ran Buhari lọ́wọ́ láti jaweolubori, ojú arákùnrin náà rí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà biobakiobulẹsẹ. Áńgẹ́lì nìkan ni ó lè farada ohun tí ó là kọjá.
“Gbogbo àwọn alágbára ni ó ṣe alátakò rẹ̀, ju gbogbo ẹ lọ, ó borí. Arákùnrin yìí jẹ́ ẹni tí ó wá láti ilé Pharaoh. Ó mọ bí nkan ṣe rí, ó sì jẹ àǹfààní nínú rẹ̀. Ó mọ ohun tí ènìyàn gbọ́dọ̀ ṣe nígbà tí ó bá di ọ̀rọ̀ ìtàn. Ojú rẹ̀ ti rí.
“Arákùnrin yìí kìí se alailoye. Ó jáfáfá ju gbogbo àwọn alátakò rẹ̀ lọ. Ohun tí ó kù fún-un ni wí pé kí ó ṣe ìtọ́jú àwọn ènìyàn kì wọ́n lè sọ ìtàn rere nípa rẹ̀. Ó ṣe aapọn láti wa. Kò lee dase. Àmọ́, ó lè síwájú. Ẹ jẹ́ kí a gbárùkù ti.
Àwọn ènìyàn ti fi ọ̀rọ̀ yìí sí orí nkan ibaraẹnise ìgbàlódé ẹlẹ́yẹ (Twitter)
Imagine their congregation taking them serious 🤣🤣🤣🤣 https://t.co/o3ZOgu2xSk
— Emerald 💚 هداية (@Mz_Tosyn) March 13, 2023
"TINUBU IS OUR MOSES. HE'S THE ONE GOD CHOSE FOR THIS PERIOD. HE'LL EXCEL."
…Pastor Oyakhilome reverse .
— June12 Mandate (@Gen_Buhar) March 12, 2023
"TINUBU IS OUR MOSES. HE'S THE ONE GOD CHOSE FOR THIS PERIOD. HE'LL EXCEL."
– PASTOR OYAKHILOME
Dey don dey leave Peter obi behind.
— Qudus Akanbi Eleyi of Lagos. (@EleyiLagos) March 12, 2023
ATẸJADE LÁTI ỌWỌ́ ÌJỌ CHRIST EMBASSY: PASITỌ CHRIS KÒ SỌ OHUN TÍ Ó JỌ BÁYÌÍ
Àwọn tí ó wà ní ìdí ifiọrọtoawujọ létí tí ìjọ náà sọ fún ìwé ìròyìn TheCable pé ọ̀rọ̀ ahesọ tí wọ́n ní ìjọ náà fi òǹtẹ̀ tẹ̀ yìí tí àwọn ènìyàn pín kiri yìí kò wá láti ọwọ́ ìjọ náà.
Wọ́n fi kún un pé àwon ènìyàn ti ń pín ọ̀rọ̀ yìí láti oṣù kẹta pẹ̀lúpẹ̀lú pé ìjọ náà tí sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà pé irọ́ gbáà ni.
“Iroyin ofege. Kò sí aridaju fún un. Kò sí fídíò, kò sì ọ̀rọ̀ ohún,ó kàn jẹyọ láti ibi tí a kò lè tọ́ka sí. Kò wá láti ọwọ́ Pasitọ Chris,” atẹjade láti ọwọ́ ìjọ náà wí báyìí.