Ẹni kan tí ó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ lórí ayélujára sọ pé fídíò tí ó se afihan àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò tí wọ́n fi aṣọ borí nígbà tí wọ́n fẹ́ já wọ ibùgbé kan ṣẹlẹ̀ ní gúúsù ilà oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ní ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, oṣù keje, ọdún 2025, Uche Nworah, ẹni kan tí ó ń lo Facebook, tọ́ka sí fídíò yìí láti sọ̀rọ̀ nípa bí “ìwà jagidijagan” se ń gbilẹ̀ ní gúúsù ilà oòrùn Nàìjíríà, tí wọ́n sì ń rò pé àwọn ń ṣètò ààbò.
“A ti gba ìwà jagidijagan, karijẹnidimadaru ní gúúsù ilà oòrùn Nàìjíríà láàyè, èyí tí a ń pè ní ètò ààbò. Ẹnikẹ́ni tí ó bá di nkan ìjà mọ́ra, tí ó fi aṣọ borí tí kò ní ìtọ́nisọ́nà tó tó, tí àwọn ará ẹ tẹ́lèe, tí wọ́n lè ti gbé egbògi olóró lura lè já wọ inú ilé rẹ, kí wọ́n sì hu ìwà pàlàpálá bí wọ́n se se nínú fídíò yìí tí a kò mọ ọjọ́ tó ṣẹlẹ̀.”
“Kò sí ètò tó bójú mú nínú ohun tí wọ́n se yìí. Ohun tí wọ́n se sì lòdì sí ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn. Nígbà wo ni irú ìwà báyìí ma dópin? tí àwọn ọmọdé bá ń gbé nínú ilé yìí ńkọ́?”

Àwọn ènìyàn igba ló ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn irínwó ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn mejidinlaaadọta ló pín in.
Ẹni tí ó ń lo Facebook yìí fídíò yìí síta láàárín ìgbà tí ètò ààbò kò dára ní gúúsù ilà oòrùn Nàìjíríà.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck lo Google Lens láti se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí. Àbájáde àyẹ̀wò wa fi yé wa pé ẹni kan tí ó ń jẹ́ @MichealFrosh32, tí ó ń lo X, tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀, èyí tí ó jẹ́ ohun ìgbàlódé íbaraẹnise alámì krọọsi, ti kọ́kọ́ fi fídíò yìí síta ní ọjọ́ karundinlọgbọn, oṣù keje, ọdún 2025.
Ẹni yìí fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá tí ó pè ní “operation flush” ní Ado Èkìtì, olú ìlú ìpínlẹ̀ Èkìtì, tí wọ́n fi tipátipá wọ ibùgbé kan tí ó wà ní òpópónà Adebayọ ní olú ìlú ìpínlẹ̀ Èkìtì.

“Ní èní, Operation Flush ní Ado Èkìtì fẹ́ hu ìwà jàgùdà, ní ibi ibùgbé kan tí ó wà ní òpópónà Adebayọ, ní Ado Èkìtì, níbi tí wọ́n fẹ́ fi tipátipá wọ̀. Èyí kìí se ìgbà àkọ́kọ́ wọn, àmọ́ a ní ẹ̀rí ohun tí wọ́n se yìí, èyí tí ó máa fún wa ní àǹfààní láti jà fún ẹ̀tọ̀ wa.” Àwọn ẹni yìí sọ pé kí àwọn ènìyàn gba àwọn.
Nínú fídíò yìí, a rí àwọn ènìyàn tí wọ́n di nǹkan ìjà mọ́ra, wọ́n wọ aṣọ dúdú tí wọ́n kọ “special force” sí lára. Àwọn ènìyàn ti sọ̀rọ̀ lorisirisi nípa ọ̀rọ̀ yìí, ọ̀rọ̀ yìí sì ti kan àwọn ọlọ́pàá lára.
Lẹ́hìn wákàtí mẹrinlelogun tí wọ́n fi fídíò yìí síta, àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkìtì sọ pé àwọn kò ní orúkọ kankan tí ó ń jẹ́ “operation flush” bí ẹnì kan se sọ yìí.
Abutu Sunday, agbẹnusọ fún àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkìtì, sọ pé Joseph Eribo, kọmisọnna fún àwọn ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, ti pàṣẹ pé kí wọ́n se ìwádìí ọ̀rọ̀ yìí.
“Àwọn ọlọ́pàá Èkìtì kò jẹ́ orúkọ kankan tí ó ń jẹ́ operation flush,” báyìí ni Sunday se wí.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Ìṣẹ̀lẹ̀ inú fídíò yìí kò ṣẹlẹ̀ ní gúúsù ilà oòrùn Nàìjíríà.