Ẹnì kan tó ń lo TikTok, ibì kan lórí ayélujára tí áwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán tàbí fídíò síta sọ pé àwọn jihadists, àwọn tí wọ́n ń gbógun ti àwọn ènìyàn tí wọ́n rò pé wọ́n jẹ́ ọ̀tá ẹ̀sìn Ìmàle/Mùsùlùmí ni wọ́n dáná sun ilé ìjọsìn àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni kan ní àríwá Nàìjíríà.
Ẹni tó fi fídíò ọ̀rọ̀ yìí síta ń jẹ́ #WakaWakaplanet lórí TikTok. Ó fi síta ní ọjọ́ kejì, osù kọkànlá, ọdún 2025, pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé: “inúnibíni tí àwọn ènìyàn ń se sí àwọn ẹlẹ́ṣin Kristẹni ti pọ̀ sí ní Nàìjíríà.”
Wọ́n kọ ọ̀rọ̀ kan tó sọ pé “àwọn ẹlẹ́sìn Ìmàle kan ti dáná sun ilé ìjọsìn àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni kan ní àríwá Nàìjíríà” sínú fídíò yìí.
Nínú fídíò yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin tó dàbí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́, tí wọ́n wọ aṣọ ilé ẹ̀kọ́ tó jẹ́ aláwọ̀ ewé àti aláwọ̀ dúdú, àti àwọn mìíràn tí wọ́n wọ aṣọ aláwọ̀ ewé àti aláwọ̀ dúdú, àti àwọn mìíràn tí wọ́n wọ aṣọ aláwọ̀ ewé àti aláwọ̀ funfun ni a rí tí wọ́n ń sunkún nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ni wọ́n ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ọgọ́jọ ni wọ́n pín in, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí.
Ẹni yii fi fídíò yìí síta lẹ́hìn àwọn wákàtí kan lẹ́hìn ìgbà tí Donald Trump, ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà sọ fún ẹ̀ka orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti wọ́n ń rí sí ọ̀rọ̀ ogun (United States Department of War) pé kí wọ́n gbaradì fún “ìgbésẹ̀” láti pa àwọn ẹlẹ́sìn Ìmàle kan ti wọ́n ń hùwà láti kó ìjayà bá àwọn ènìyàn rẹ́ (wipe out Islamic terrorists) ní Nàìjíríà.
Trump sọ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́hìn ìgbà tí ó sọ pé Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀ èdè tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ń kọ àwọn ènìyàn lóminú (designate Nigeria as a ‘country of particular concern’), èyí tí ó jẹ́ ìdáhùn rẹ̀ nípa ẹ̀sùn tí àwọn ènìyàn kan fi sún Amẹ́ríkà pé àwọn ènìyàn kan ń pa àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni ní Nàìjíríà ní ìpakúpa.
BÍ CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
CableCheck, ti TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí lórí Google Lens. Àbájáde àyẹ̀wò wa fi hàn pé àwọn ilé isẹ́ ìròyìn kan ní Ghana ti fi fídíò yìí síta láti ọjọ́ kọkanlelọgbọn, osù kẹwàá, ọdún 2025.
TV3 Ghana, ilé isẹ́ ìròyìn amohunmaworan kan ní Ghana fi fídíò yìí síta lórí Instagram, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ orí ayélujára tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán tàbí fídíò síta.
Gẹ́gẹ́bí ilé isẹ́ amohunmaworan yìí se sọ, ìjàmbá iná yìí ṣẹlẹ̀ ní Kwapong Nursing Training College, ni Asunafo ní ibì kan tí wọ́n ń pè ní Ahafo, ní Ghana.
Àwọn ilé isẹ́ ìròyìn mìíràn tún gbé ọ̀rọ̀ yìí síta. O lè rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí níbí, níbí àti níbí.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Ọ̀rọ̀ tí ẹni yìí sọ pé Nàìjíríà ni ìṣẹ̀lẹ yìí ti ṣẹlẹ̀ kìí se òótọ́. Ghana ni ìṣẹ̀lẹ iná yìí ti ṣẹlẹ̀.