Àjọ tó ń rí sí ààbò àwọn awakọ̀, àwọn tí wọ́n ń rìn lójú ọ̀nà tí ọkọ̀ ń rìn àti ètò ìrìnà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí a mọ̀ sí Federal Road Safety Commission (FRSC) ti ṣàlàyé pé fídíò kan tí ó se afihan ẹnì kan tí ó ń wa kẹkẹ maruwa níbi tí ó ti ń bá àwọn òṣìṣẹ́ àjọ elétò ìrìnà yìí jà ní Benin, ní Ìpínlẹ̀ Edo, jẹ́ fídíò tí ó ti pẹ.
Nínú ọ̀rọ̀ kan ni ọjọ́rú, ọjọ́ kọkanlelogun, ọdún 2025, Olusegun Ogungbemide, agbẹnusọ fún FRSC, sọ pé ọjọ́ kẹrindinlogun, oṣù keje, ọdún 2025, ni ènìyàn kan se fídíò yìí, tí àwọn ènìyàn ti pín kiri ní ojú ọ̀nà Benin sí Sapele (Benin-Sapele road), ní Ìpínlẹ̀ Edo àti wí pé àwọn ti yanjú ọ̀rọ̀ yìí.
O sọ pé àwọn ènìyàn mọọmọ pin fídíò yìí láti le jẹ́ kí àwọn ènìyàn púpọ̀ lọ sí orí ibi ayélujára wọn.
“Àwọn ènìyàn ti pe àkíyèsí FRSC sí fídíò kan tí àwọn ènìyàn ń pín lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára (social media platforms), èyí tí ó se afihan ẹni kan tí ó ń wa kẹkẹ maruwa (tricycle), tí kò wọ aṣọ, níbi tí ó ti ń dójú ìjà kọ àwọn òṣìṣẹ́ FRSC, ẹni yìí sìí n ba ọkọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ yìí jẹ́ ní ojú ọ̀nà Benin sí Sapele, ní Ìpínlẹ̀ Edo,” báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí se sọ.
“Pípín ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ọgbọ́n ti àwọn ènìyàn dá láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn púpọ̀ lọ sí ibi tí wọ́n ti máa ń gbè nnkan/ọ̀rọ̀ jáde lórí ayélujára, si àwọn ènìyàn lọ́nà, àti fa wàhálà lórí ọ̀rọ̀ tí ó ti ní ìyànjú.”
Ogungbemide sọ pé onikẹkẹ maruwa yìí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adeshina Adeyẹmọ fojú ba ilé ẹjọ́ níwájú F. Ojehumen, adajọ àgbà ti Evbuoriaria Magistrate Court, ni Benin, pẹ̀lú keesi tí nọ́mbà rẹ̀ jẹ́ MEV/117C/2020.
Ogungbemide sọ pé ilé ẹjọ́ ti dá ẹjọ́ tí ó yẹ fún Adeyẹmọ, ní ọjọ́ kìíní, oṣù kìíní, ọdún 2021, wọn si sọọ sí ẹ̀wọ̀n fún ìwà búburú. yìí. Ó fi kún ọ̀rọ̀ ẹ pé FRSC tí kó àwọn ènìyàn jọ láti wá ìdí ọ̀rọ̀ naa ati lati mọ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n wà nínú fídíò yìí.
“Lẹ́hìn ìwádìí, FRSC dá ẹjọ́ àwọn òṣìṣẹ́ wọn méje tí wọ́n wà nínú fídíò yìí, wọ́n sì dín ipò wọn kù nítorí ìwà búburú tí wọ́n hù nígbà wàhálà yìí,” báyìí ni agbẹnusọ àwọn elétò ìrìnà yìí se sọ.
“Ara ìyà tí wọ́n tún fi jẹ wọn ni pé wọ́n gbé wọn lọ sí ibòmíràn láti ṣe iṣẹ́ láti fi hàn pé àwọn kò gba ìwà pàlàpálá láyè.”
Ogungbemide sọ pé FRSC yóò fi ìyà tó bá yẹ jẹ àwọn oníwà radarada. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé fídíò tí ó ti pẹ yìí lè si àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ́nà, ó sì lè jẹ́ kí wọ́n gbàgbọ́ pé laipẹ ni Ìṣẹ̀lẹ yìí ṣẹlẹ̀.
“FRSC rọ àwọn ènìyàn pé kí wọ́n rí fídíò yìí gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ fídíò tó ti pẹ, tí àjọ elétò ìrìnà ti yanjú ẹ̀, pẹ̀lú ìyà tó tọ́ sí àwọn òṣìṣẹ́ oníwà pàlàpálá yìí,” báyìí ni agbẹnusọ yìí se sọ.
Ogungbemide ṣèlérí pé FRSC yóò ri dájú pé ààbò tó péye wà fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ń lo ojú ọ̀nà tí àwọn ọkọ̀ ń rìn.
Ó tún bẹ àwọn ọmọ Nàìjíríà pé kí wọ́n fi ọwọ́ so ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ agbófinró, ó sì ṣèlérí pé FRSC yóò máa ṣètò ààbò ojú ọ̀nà tí àwọn ọkọ̀ ń rìn bó se yẹ.