Atẹsita kan lórí ojú ìwé ibi ibaraẹnise tí wọ́n pè ní Republicans for United States of Biafra, ti fi fídíò kan tí kì í se òótọ́, nínú èyí tí wọ́n ti sọ pé Donald Trump, Ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà sọ pé kí ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tú Nnamdi Kanu sílẹ̀ ní àtìmọ́lé.
Ibi ibaraẹnise yìí, tí ó ní àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹta ó dín ní ọọdunrun tí wọ́n ń tẹ̀lée, fi fídíò náà síta ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kejì, ọdún 2025. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ogún ni wọ́n ti rí/wo fídíò yìí, àwọn ènìyàn ìgbà ni wọ́n ti pín ín, àwọn ènìyàn ogójì ni wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, láti ìgbà tí wọ́n ti fi síta.
Nínú fídíò tí kò tó isẹju kan yìí, a gbọ́ ohùn ẹni kan tí ó jọ Trump, tó ń sọ pé òhun máa tú Kanu, olórí àwọn tí a mọ̀ sí Indigenous People of Biafra (IPOB) sílẹ̀ kúrò nínú àtìmọ́lé tí ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fi sí.
Fídíò yìí ní Trump sọ pé ìjọba òhun yóò ríi dájú pé àwọn jẹ́ kí àwọn ‘ara Biafra’ se eto láti dìbò àti ṣètò ijọba ara wọn.
Wọ́n dá ibi ibaraẹnise yìí sílẹ̀ ní oṣù kẹrin, ọdún 2020, láti lè máa pín àti se ìgbélárugẹ àwọn ohun tó níí se pẹ̀lú Biafra.
Ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kejì, ọdún 2025, ibi ibaraẹnise yìí fi fídíò kan tí wọ́n fi artificial intelligence (AI) gbé kalẹ̀ síta. Fídíò yìí ní Trump se àtìlẹyin fún bí Biafra se fẹ́ gba òmìnira láti máa se ìjọba ara wọn ní Nàìjíríà.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ THECABLE NEWSPAPER SE RÈÉ
Ayẹwo ọ̀rọ̀ yìí tí a se fi ye wa pé àwọn ènìyàn se fídíò yìí lati lè jẹ́ kí ó dàbí ẹni pé Trump ló ń sọ̀rọ̀.
Ibi ẹnu ẹni tí ó wà nínú fídíò yìí rí bálabàla, ó sì dàbí ẹni pé wọ́n gbé e lórí àwòrán mìíràn láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn rò pé Trump ló ń sọ̀rọ̀.
CableCheck ríi pé wọ́n se fídíò yìí nípa lílo wẹbusaiti (website) tí ó máa jẹ́ kí ènìyàn lè lo AI láti se fídíò, nípa lílo àwòrán àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ gbajúmọ̀.
Wẹbusaiti yìí máa ń fi àyè gba àwọn ènìyàn láti ṣe fídíò tí wọ́n fi AI ṣe, nípa lílo àwòrán Trump, Elon Musk, ẹni tí ó ti ni owó púpọ̀ nípa sise òwò tẹkinọlọji (billionaire technology entrepreneur), Barack Obama, Ààrẹ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀, Kanye West, gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé àti àwọn mìíràn.
Ohun àmúlò kan lórí wẹbusaiti yìí máa ń jẹ́ kí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lo wẹbusaiti yìí fi àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá fẹ́ sínú fídíò yìí.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Ọ̀rọ̀ yìí kìí se òótọ́.