Fídíò kan tí ó ń se àfihàn Bọ́lá Tinubu, Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà níbi tí ó ti ń rọ́ kẹ̀kẹ̀ mọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n sọ pe tẹkinọlọji tàbí ọ̀nà ìmọ̀ ẹ̀rọ ni wọ́n fi se ọ̀rọ̀ rẹ̀ (artificial intelligence-AI generated-video) ti di ohun tí àwọn ènìyàn ti pín kiri lórí WhatsApp.
Nínú fídíò ìṣẹ́jú kan yìí, Tinubu sọ pé òhun yóò fi “ìyà tó tọ́ jẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n rí òhun fín yìí.”
“Mo fẹ́ jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ pé, láti ìsinsìnyí lọ, nígbàkúùgbà tí èmi Bọ́lá Tinubu bá fi ọ̀rọ̀ síta, n kò rò pé ó yẹ kí àwọn ènìyàn máa fi mí se yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n sọ pé AI ni wọ́n fi se ọ̀rọ̀ mi,” báyìí ni ẹni yìí ní Tinubu se wí.
“Mo sì wà láyé, mo sì wà láàyè, mo sì ń sin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, mo sì se tán láti se ohun tó yẹ. Ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé AI ni wọ́n fi se ọ̀rọ̀ mi yóò jẹ ìyà tó tọ́ fún àrífín yìí. A kò ńìí gba ìwà pàlàpálá tí àwọn ènìyàn rò pé ẹ̀fẹ̀ ni láyè.”
“Fún ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọmọ ọgbọ́n ọdún àti ẹ̀yin tí ọjọ́ orí yin dín ní ọgbọ́n, ẹ kò gbọ́dọ̀ pè mí lórúkọ, Ààrẹ Bọ́lá Tinubu tàbí arákùnrin Tinubu lẹ gbọ́dọ̀ ma pè mí.”
“Eléyìí kìí se ìgbéraga, àṣẹ ni. Àwọn ọmọ Nàìjíríà gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ọ̀wọ̀ tọ́ sí, kí ẹ sì máa se áwọn ohun tí ẹ ní láti se lọ́nà tó yẹ. Ó tó gẹ́.”
WhatsApp sọ pé àwọn ènìyàn ti pín ọ̀rọ̀ nípa Tinubu yìí ní “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà.”
Ẹnì kan tí ó ń jẹ́ @uncle_tarrmie lórí TikTok ló fi ọ̀rọ̀ yìí síta. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹẹdogun àti ẹẹdẹgbẹta ni wọ́n ń tẹ̀lé ẹni yìí. A ríi pé fídíò yìí kò sí lórí ojú ibi tí ẹni yìí ti máa ń fi nǹkan síta lórí TikTok nígbà tí a se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí lórí ibi yìí.
Àmọ́sá, a rí àwọn fídíò orísirísi tí wọ́n sọ̀rọ̀ tí kò dára nípa Tinubu. Lára àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni “owó àjẹmọ́nú fún àwọn alákòóso ìjọba tó pọ̀ lápọ̀jù”, ”Àwọn aláṣẹ ìjọba àpapọ̀ kí Davido àti Chioma kú oríire”, àti “Ààrẹ Tinubu dara pọ̀ mọ́ àwọn olólùfẹ́ Wizkid.”
Biotilẹjẹpe ẹni yìí sọ pé AI ni òhun fi se fídíò yìí, wọ́n ti pín lára àwọn fídíò rẹ̀ láti lè fi ọ̀rọ̀ tó àwọn ènìyàn létí.
A tún rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fídíò tí wọ́n fi AI se, àwọn èyí tó jẹ́ ara àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ máa gbé jáde ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, èyí tí wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní “Òjíṣẹ́ Ọlọ́run tí inú rẹ̀ kò mọ́”, tí ẹni yìí fi síta.
“AI ni mo fi se áwọn fídíò mi. N kò ní àníyàn láti si àwọn ènìyàn lọ́nà,” báyìí ni @uncle_tarrmie se sọ, ó sì sọ pé kí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń lo ibi íbaraẹnise orí ayélujára (social media) dara pọ̀ mọ́ òhun.