Ẹgbẹ́ òsèlú kan tí a mọ̀ sí the United Party for National Development (UPND) tí sọ pé fídíò tí àwọn ènìyàn ń pín kiri tí ó sọ pé Hakainde Hichilema, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Zambia kò ní díje fún Ipò Ààrẹ ní ẹẹkeji ní ọdún 2026 kìí ṣe òótọ́.
Nínú fídíò náà, èyí tí àwọn ènìyàn pín kiri, Hichilema wọ suutu nínú àwòrán tí asia orílẹ̀-èdè Zambia wà ní abẹlẹ rẹ̀ níbi tí ó ti ń ṣe ìkéde pé òhun kò ní díje ní ẹẹkeji nínú ìbò gbogbogbo tí ó má wáyé ní ọdún 2026.
“Mo fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú òótọ́ nípa ìṣòro tí ó ń dojú kọ wá nígbà ìjọba mi gẹgẹbi asiwaju orílẹ̀-èdè yìí. Pẹ̀lú òótọ́ ni mo fi kéde pé ń kò ní díje ní ẹẹkeji nínú ìbò gbogbogbo tí a máa ṣe ní ọdún 2026. Mo lérò pé ìpinnu yìí dára fún orílẹ̀-èdè wa,” báyìí ni ó ṣe wí.
Hichilema ti dije fún Ipò Ààrẹ ní ìgbà márùn-ún tí ó sì kùnà kí ó tó ṣe àṣeyọrí ni ọdún 2021.
Ni Orílẹ̀-èdè Zambia, àwọn ènìyàn máa ń dibo yàn Ààrẹ fún ọdún márùn-ún. Ọdún márùn-ún ni ẹẹmeji ni Ààrẹ máa ń lò.
Àyẹ̀wò tí TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe fi hàn pé irọ́ ni àwòrán yìí.
Fídíò náà jáde nígbà tí àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ nípa ìdìbò ọdún 2026.
Gẹ́gẹ́bí ó ṣe rí ní àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, nígbà ìdìbò, oríṣiríṣi àwọn fídíò àti atẹjade tí ó lè si àwọn ènìyàn l’ọna ni àwọn ènìyàn máa ń pín kiri.
Wọ́n máa ń se àwọn nkan tí a mẹ́nuba yìí láti ba ènìyàn kan ní orúkọ jẹ́ tàbí yí èrò àwọn ènìyàn padà.
Nínú ọ̀rọ̀ tí Batuke Imenda, akọ̀wé UPND, ẹgbẹ́ òsèlú tí ó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́ ní Zambia fi síta, ó pè wọ́n ní alainikanse, oníwà radarada tí wọ́n ń pín fídíò irọ́ tí ó ń sín Ààrẹ jẹ láti si awọn ará ìlú lọna.
Ó kìlọ̀ fún àwọn ará ìlú tí wọ́n ń pín fídíò tí ó pa irọ́ nípa ènìyàn tí Hichilema jẹ́ yìí.
Ìwà ibanilorukọ jẹ́ ti àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ń ṣe láti kan Ààrẹ ní àbùkù yé wa, báyìí ni atẹjade yìí ṣe wí.
“A mọ́ pé àwọn olórí ẹgbẹ́ òsèlú alátakò àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọ́n ń ṣeé láti kọ ẹhin àwọn ènìyàn sí ìjọba.
“O ye wa pé ẹ fẹ́ kí àwọn ènìyàn gba tiyín. Ṣùgbọ́n, a o fi òfin yé yín.
“Àwọn ènìyàn mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín mọọmọ hu ìwà tí kò bá òfin mu kí àwọn agbofinro lè dá sí ọ̀rọ̀ yín. Tí wọ́n bá pè yín láti fi ọ̀rọ̀ wá yín lẹ́nu wò, ariwo yín yóò pọ̀.
“Ẹgbẹ́ òsèlú UPND fẹ́ fi yé ẹnikẹ́ni tí ó wà nìdí fídíò yìí pé ọwọ́ òfin yóò bàwọ́n.”
Ààrẹ Hichilema kò tíì sọ ọ̀rọ̀ kankan nípa fídíò náà.
Àwọn Ọlọpa Zambia ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti lè mọ ibi tí fídíò náà ti jáde. Wọ́n ní àwọn yóò fi ojú àwọn oníwà pàlàpálá yìí fíná.