TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Fídíò tí àwọn ènìyàn ṣe atunpin rẹ̀ tí ó ní àwòrán ohun ìjagun kìí se ti orílẹ̀-èdè Nije
Share
Latest News
HOAX ALERT: Cross River disowns viral Cally Air ‘boobs safety’ assurance advert
Seven ways to detect an AI-generated video
BLIND SPOT: Nigeria’s shortcomings in the age of AI scams
The rise of deepfakes and the fight for digital truth
DISINFO ALERT: Health ministry debunks AI video claiming free nationwide diabetes treatment
Video wey show as ‘security operatives’ dey break into apartment no be from south-east
Íhé ńgósị́ ébé ńdị́ ǹché nà-ákpáká ụ́lọ̀ ésiteghị nà south-east
Ìṣẹ̀lẹ tí àwọn ‘òṣìṣẹ́ elétò ààbò’ fẹ́ fipá wọ ibùgbé kan kò ṣẹlẹ̀ ní gúúsù ilà oòrùn Nàìjíríà
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Fídíò tí àwọn ènìyàn ṣe atunpin rẹ̀ tí ó ní àwòrán ohun ìjagun kìí se ti orílẹ̀-èdè Nije

Yemi Michael
By Yemi Michael Published August 6, 2023 7 Min Read
Share

Fídíò kan tí àwọn ènìyàn ń pín kiri tí ó ní àwọn òṣìṣẹ́ ológun níbi tí wọ́n ti ń ṣe karími nínú aṣọ ogun àti ibi tí wọ́n ti ń fi ìmọ̀ wọn hàn gẹ́gẹ́bí àwọn jagunjagun ọmọ orílẹ̀-èdè Nije ni a ti rí.

Nínú àwòrán náà tí àwọn ènìyàn pín ní orí Tiktok, èyí tí ó jẹ́ ohun igbaworan alariya síta ni a ti rí àwọn òṣìṣẹ́ ológun tí wọ́n ń dira ogun pẹ̀lú ìbọn tí wọ́n sìí ń ṣe bí ẹni tí ó ń gbaradì tí wọ́n sì le ojú koko láàárín àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà tí wọ́n rọgba yí wọn ká pẹ̀lú ìbẹ̀rù, ìfẹ́ àti ìyanu.

Ní ọjọ́ ẹtì (Furaide), olumulo ohun ìgbàlódé ibaraẹnise ẹlẹyẹ (Twitter) tí a mọ̀ sí @VictorC26525018, ní ó gbé fídíò kan síta tí ó sì rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà kí wọ́n gbàdúrà fún àwọn jagunjagun Nàìjíríà bí wọ́n ṣe ń ṣe ìgbaradì láti lọ dojú kọ àwọn jagunjagun orílẹ̀-èdè Nije tí wọ́n ti múra sílẹ̀ gidi.

👆👉Pray for our soliders for this battle because Niger Republic military are more than ready for face their enemy. Look at this video. Say no to War. Africa fighting Africa. This is what Western people want so that they will sale their weapons 🔪 🔫🔫. Africa why. pic.twitter.com/FWukwR6RP5

— Victor Chuks (@VictorC26525018) August 4, 2023

 

“Ẹ gbàdúrà fún àwọn jagunjagun wa fún ogun yìí nítorí pé àwọn jagunjagun orílẹ̀-èdè Nije ti ṣe tán láti dojú ìjà kọ ọ̀tá wọn. Wo fídíò yìí. Ohun tí àwọn orílẹ̀-èdè òkèèrè fẹ́ràn niyii kí wọ́n lè ta àwọn nkan ogun wọn. Kí ló fa èyí ní ilẹ̀ adúláwò (Áfíríkà)? Atẹjade náà tí àwọn ènìyàn rí ní ọ̀nà tí ó ju ọgọ́rùn-ún lọ ni ó wí báyìí.

Gbadebo Rhodes-Vivour, ẹni tí ó díje fún Ipò Gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 2023 nínú ẹgbẹ́ òsèlú àwọn òṣìṣẹ́ (Labour Party) tún fi fídíò náà síta lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise ẹlẹyẹ.

Unlike some, i have only one passport and have sworn no allegiance to any other state. Nigeria is all I have.

A war with a people who appear to be uniting around a common interest, seeking economic freedom and a departure from over bearing western influence will have very dire… pic.twitter.com/WJ0tmLThiT

— Gbadebo Rhodes-Vivour (@GRVlagos) August 4, 2023

 

Biotilẹjẹpe kò sọ nkankan pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nije ni àwọn òṣìṣẹ́ ológun yìí, atẹsita olóṣèlú yìí ń sọ̀rọ̀ nípa ifipagba ìjọba tí ó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nije.

“Bí àwọn kan, ìwé irinna ojú Òfurufú kan ni mo ní. Mo sì ti ṣe ìbúra pé n kò ní rí ti orílẹ̀-èdè míràn rò. Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nìkan ni mo ní,” ó wí báyìí.

“ìjàkadì ogun pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ẹnu wọn kò nípa ìṣòro wọn àti iyẹra fún ìwà jíjẹ gàba lé nkan lórí àwọn orílẹ̀-èdè òyìnbó yóò kó wàhálà bá wa. Yóò sì fa aifọkanbalẹ.”

Nígbà tí à ṣàgbéyẹ̀wò atẹjade yìí, àwọn ènìyàn ti pín atẹsita Rhodes yìí ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ní igba àti mẹtadinlogun. Ó ní èsì ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún ó lé mẹta.

Awon ènìyàn sì fẹ́ràn ọ̀rọ̀ náà ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹjọ ó dín ní ookandinniigba. Wọ́n sì ti wòó ní ìgbà mílíọ̀nù méjì ó dín ní ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà igba.

Fídíò yìí tí ó ní àkòrí kan náà tún jẹyọ lórí akaunti (account) ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ (facebook) tí a mọ̀ sí Open Nigeria. Akaunti náà fi fídíò náà síta, níbi tí wọ́n ti sọ wí pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nije kò ní ohun tí wọ́n máa pàdánù.

“Mo rò pé Seyi Tinubu, Yusuf Bichi, Umar Ganduje, Hope Uzodimma, Festus Keyamo, Muhammadu Buhari, Femi Gbajabiamila, Tony Elumelu, Aliko Dangote, Akpabio, Orji Uzor Kalu àti àwọn ọmọ àwọn tí ó ṣe àtilẹyin fún òkùnkùn yóò síwájú lójú ogun láti dojú kọ àwọn ọmọ Nije, àwọn tí kò ní ohun tí wọ́n yóò pàdánù nínú ogun tí ó dojú kọ ilẹ̀ adúláwọ̀ (Áfíríkà),” báyìí ni atẹjade náà wí.

Àwọn ènìyàn fi fídíò yìí síta lẹ́nu pé Tinubu gbé ìgbéṣẹ̀ láti rán àwọn òṣìṣẹ́ ológun lọ sí orílẹ̀-èdè Nije láti lè dá rògbòdìyàn tí ifiagidigba ìjọba fà níbẹ̀ dúró.

Ààrẹ Tinubu, ẹni tí ó jẹ́ alága ẸKOWAASI (ECOWAS-Economic Community of West African States) àti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ẸKOWAASI ṣe ìpinnu láti lo agbára láti yanjú rògbòdìyàn náà níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ ìsinmi ní Abuja.

ẸKOWAASI fún Nije ní ọ̀sẹ̀ kan, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ ìsinmi tí wọ́n ṣe ìpàdé yìí kí wọ́n dá Ààrẹ Mohamed Bazoum ti orílẹ̀-èdè Nije tí àwọn òṣìṣẹ́ ológun fi tipatikuuku yọ kúrò ní ipò Ààrẹ padà sí ipò rẹ̀ tàbí kí wọ́n kabamọ.

Àmọ́sá, àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀, èyí tí orílẹ̀-èdè Russia wà nínú wọn àti àwọn mìíràn tí ọ̀rọ̀ náà kàn ti sọ pé ifiọrọweọrọ tàbí ibaraẹnisọrọ ní pẹ̀lẹ́pùtù ni ó lè mú wàhálà náà wá sópin.

ISARIDAJU

TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe àyẹ̀wò àwòrán yìí láti lè mọ ìgbà tí wọ́n fi fídíò yìí sórí ayélujára.

Àbájáde àyẹ̀wò yìí fi yé wa pé àwòrán yìí ti wà ní orí ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn máa ń fi àwòrán tàbí fídíò sì kí àwọn ènìyàn lè wòó (YouTube) láti ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹrin, ọdún 2023, ọjọ́ tí orílẹ̀-èdè Senegal ṣe ayẹyẹ ọjọ́ tí wọ́n gba òmìnira.

Àkòrí fídíò yìí ni “Ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹrin, ọjọ́ igbominira ilẹ̀ Senegal, 2023”, èyí tí ó se àfihàn àwọn jagunjagun níbi tí àwon ará ìlú tí ń ṣe ìdárayá fún wọ́n nígbà tí wọ́n ń ṣe ifiagbarahan níbi àjọyọ̀ náà.

Ìjáde àwọn ológun yìí jẹ́ àkọ́kọ́ ní Dakar, olú ìlú orílẹ̀-èdè Senegal lẹ́hìn ìgbà díẹ̀ tí nkan fi dúró, èyí tí ajakalẹ aarun kofiidi (Covid19) fà.

Rògbòdìyàn tí ó lè fa ipanilara tí ó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn òṣìṣẹ́ alaaabo àti àwọn alatilẹyin ẹgbẹ́ òsèlú alátakò tí wá yé ní orílẹ̀-èdè Senegal ní ọ̀sẹ̀ kan sẹhin kí orílẹ̀-èdè Faranse (France) tó ṣe àjọyọ̀ ọdún mẹtalelọgọta tí orílẹ̀-èdè Senegal gba òmìnira.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÍ SÍ

Fídíò tí ó ṣe àfihàn ibi tí àwọn òṣìṣẹ́ ológun tí ń ṣe karími tí àwọn ènìyàn ti pín kiri yìí kìí se òótọ́.

Àwọn jagunjagun inú fídíò yìí jẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ológun Senegal níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìjáde ayẹyẹ òmìnira ìlú Senegal.

Àsíá tí ó wà ní abẹ́lẹ̀ fídíò yìí jẹ́ ti orílẹ̀-èdè Senegal. Kìí ṣe ti Nije.

TAGGED: atunpin, àwọn ènìyàn, àwòrán, Fídíò, Ifiidiododomulẹ, Nije (Niger), ohun ìjagun, orílẹ̀-èdè

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael August 6, 2023 August 6, 2023
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

HOAX ALERT: Cross River disowns viral Cally Air ‘boobs safety’ assurance advert

The Cross River state government has disowned a viral image of a purported Cally Air…

August 15, 2025

Seven ways to detect an AI-generated video

A video announcing the launch of a free nationwide diabetes treatment recently went viral across Nigerian…

August 13, 2025

BLIND SPOT: Nigeria’s shortcomings in the age of AI scams

It sounded exactly like her, but it was not. Adeola Fayehun was thousands of miles…

August 12, 2025

The rise of deepfakes and the fight for digital truth

BY PRUDENCE OKEOGHENE EMUDIANUGHE On May 30, 2025, a 49-minute video surfaced on a YouTube…

August 12, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Video wey show as ‘security operatives’ dey break into apartment no be from south-east

One Facebook user don claim sey video wey show as hooded armed security operatives dey break into residential apartment hapun…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 7, 2025

Íhé ńgósị́ ébé ńdị́ ǹché nà-ákpáká ụ́lọ̀ ésiteghị nà south-east

Ótù onye na Facebook ekwuola na ihe ngosị ebe mmadụ na-agbaka ụlọ obibi mmadụ mere na south-east. N'ụbọchị iri abụọ…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 7, 2025

Ìṣẹ̀lẹ tí àwọn ‘òṣìṣẹ́ elétò ààbò’ fẹ́ fipá wọ ibùgbé kan kò ṣẹlẹ̀ ní gúúsù ilà oòrùn Nàìjíríà

Ẹni kan tí ó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ lórí ayélujára sọ pé fídíò tí ó se afihan àwọn…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 7, 2025

Bidiyon da ake dangantawa da ‘jami’an tsaro’ da suka kutsa cikin gida ba daga kudu maso gabas ba ne

Wani ma’abocin amfani da shafin Facebook ya yi ikirarin cewa wani faifan bidiyo da ke nuna jami’an tsaro dauke da…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 7, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?