Fídíò kan tí a ti rí àwọn sójà (soldiers) ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n fẹ́ lọ dojú ìjà kọ wàhálà àti àwọn sójà orílẹ̀ èdè Faransé tí wọ́n ń já àwọn nǹkan sílẹ̀ ti di ohun tí àwọn ènìyàn ti pín kiri.
A rí fídíò yìí lẹ́nu àríyànjiyàn tó ń lọ lọ́wọ́ pé orílẹ̀ èdè Faransé ní erongba kan nípa Nàìjíríà.
Ní ọjọ́ alamisi, Mohammed Idris, minisita fún fífi ọ̀rọ̀ tó àwọn ènìyàn létí ní Nàìjíríà sọ pé ọ̀rọ̀ kan tí àwọn ènìyàn ń sọ pé Nàìjíríà ti fi àwọn ilẹ̀ rẹ̀ kan tọrẹ fún orílẹ̀ èdè Faransé láti máa se àkóso rẹ̀ kìí se òótọ́.
Idris sọ ọ̀rọ̀ yìí laipẹ nígbà tí àwọn ènìyàn ń sọ pé Nàìjíríà fẹ́ pawọ pọ̀ pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Faransé láti da orílẹ̀ èdè Niger Republic rú.
Ní bíi ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹhin, Mahdi Shehu, ẹni kan tí ó máa ń sọ ọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láwùjọ, sọ ọ̀rọ̀ kan tí ìdí rẹ̀ kò múlẹ̀ pé ètò àti fi ibijoko àwọn ológun orílẹ̀ èdè Faransé tẹ́lẹ̀ sì àríwá-orun Naijiria ń lọ lọ́wọ́, lẹhin ìgbà tí àwọn ọmọ ológun orílẹ̀ èdè Faransé wá rí Femi Oluyede, ẹni tí ó jẹ ọga pátápátá fún àwọn sójà (Chief of Army Staff-COAS) ní Nàìjíríà.
Àmọ́sá, nígbà tí ó ń fèsì sí ọ̀rọ̀ Idris ní ọjọ́ alamisi, Shehu sọ pé kí Idris ye pa irọ, ó ní pé kí ó ye máa sọ pé ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe òótọ́. Àwọn adarí ọ̀rọ̀ àwọn sójà sọ pé ọ̀rọ̀ yìí kì í se òótọ́.
Nínú fọ́nrán kan tí ẹnì kan fi síta pẹ̀lú atẹsita kan tí wọn tí mú kúrò lórí ayélujára, àwọn ènìyàn ní àwọn ń gbọ́ ohun kan bí ariwo níbi tí àwọn ọmọ ológun Nàìjíríà ti ń já àwọn nǹkan kan silẹ, tí ara wọn jẹ́ àpò ìrẹsì, láti inú ọkọ̀, nígbà tí àwọn ọmọ ológun orílẹ̀ èdè Faransé ń já ọkọ baalu ológun silẹ láti inú ọkọ̀ òfuurufú tí wọ́n fi máa ń kó ẹrù.
Àwọn ọkọ̀ tí àwọn ọmọ ológun wà nínú rẹ̀ ń káàkiri, ènìyàn sì lè gbọ́ ìró bàtà wọn lórí títì.
Ọkọ̀ (bọọsi) méjì, ìkan ní àsíá orílẹ̀ èdè Faransé, ni àwọn ènìyàn padà rí tí wọ́n ń gbé àwọn ọmọ sójà tí wọ́n fẹ́ lọ dojú ìjà kọ wàhálà lọ.
Sójà ọmọ Nàìjíríà kan sọ̀rọ̀ nínú fídíò náà. Ó ní àwọn sójà yìí tí kúrò níbi tí wọ́n ti lọ dojú ìjà kọ wàhálà, níbi tí wọ́n ti kọ nípa gbigbogun ti rògbòdìyàn.
Àmọ́sá, TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ríi pé fídíò yìí ti wà níta láti oṣù kìíní, ọdún 2013.
Àwọn onisẹ ìròyìn kan tí a mọ̀ sí Associated Press (AP) sọ pé àwọn sójà yìí jẹ́ ara àwọn sójà tí wọ́n fẹ́ dojú ìjà kọ rògbòdìyàn tí Economic Community of West African States (ECOWAS) fi se iranlọwọ fún àlàáfíà ní àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ECOWAS.
“Ọmọ Nàìjíríà mẹrindinlọgọjọ, ọmọ orílẹ̀ èdè Togo ọgọ́rùn-ún, ọmọ orílẹ̀ èdè Benin Republic marunlelogun àti àwọn marunlelogun mìíràn láti Benin Republic ni wọ́n ń bọ̀ ní alẹ yìí,” ọga àwọn sójà ní orílẹ̀ èdè Faransé ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nínú fídíò yìí.
Àwọn ọmọ ológun náà dé sí Senou International Airport, Bamako, Mali, èyí tí ó jẹ́ ìkan lára àwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn sójà yìí dé sí láti lé jẹ́ kí wàhálà má wà.