TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Fídíò tí àwọn ènìyàn pín tí ó ṣe àfihàn ilé olókè tó ga gan-an kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìṣẹlẹ (earthquake) tí ó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Taiwan
Share
Latest News
Did Tinubu attend same school as Alexander Zingman? Here is what we know
FACT CHECK: No, Nigeria didn’t deploy peace support mission to Israel
FACT CHECK: Did lawmakers skip the national anthem during Tinubu’s Democracy Day speech?
FACT CHECK: Did a military coup oust Paul Biya as Cameroon’s president?
FACT CHECK: Ndume erred. 22 governors didn’t endorse Jonathan in 2015
Rárá, Pope Leo kò bẹ Tinubu kó tú Nnamdi Kanu sílẹ̀ ní àtìmọ́lé
Ḿbà, Pope Leo áyọghị Tinubu kà ọ́ tọ́pụ̀ Nnamdi Kanu nà ǹgá
No, Pope Leo no beg Tinubu to release Nnamdi Kanu
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Fídíò tí àwọn ènìyàn pín tí ó ṣe àfihàn ilé olókè tó ga gan-an kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìṣẹlẹ (earthquake) tí ó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Taiwan

Yemi Michael
By Yemi Michael Published April 15, 2024 5 Min Read
Share

Àwọn ènìyàn kan ti sọ pé Fídíò kan tí ó ṣe àfihàn àwọn ilé tó ga gan-an ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìṣẹlẹ tó kọlu orílẹ̀-èdè Taiwan.

Nínú fídíò yìí, àwọn ilé olókè gogoro ń wó lulẹ̀. Àwọn tí ó ń gbé ní agbègbè ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi igbe ta. 

Àwọn ènìyàn ti wo/rí Fídíò tí kò tó idamẹrin ìṣẹ́jú kan yìí tí ẹni kan fi sí orí X (ohun ìgbàlódé tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀) ní ọna ẹgbẹ̀rún marun-leniaadọta. Wọ́n pín ín ní ọ̀nà ọgbọ́n, wọn fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí nígbà mẹtadinlaadọọrin. Wọ́n sì fi pamọ́ láti lè kàá nígbà mìíràn ní ìgbà mẹtalelọgbọn. 

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ni wọn ti wó lulẹ̀ lẹ́hìn ìgbà tí ìṣẹlẹ yìí ṣẹlẹ̀,” @patrickhsu0906, ẹni kan tí ó ń lo X ló fi ọ̀rọ̀ yìí ṣe àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn tí wọn ń lo X ni wọn pín fídíò yìí. Wọn sì sọ pé ti ìṣẹlẹ orílẹ̀-èdè Taiwan ni.

“ÌṢẸLẸ TAIWAN NÍ ARIGBUNGBUN ÌLÀ-OÒRÙN ÉṢÍÀ (ASIA): Ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó bani nínú jẹ́ ni a ti rí àwọn ilé olókè gogoro tí wọ́n ń wó lulẹ̀. 

Ìṣẹlẹ yìí, èyí tí ó ba àwọn ilé jẹ ni ìṣẹlẹ tí ó pọ̀ jù ní ọdún marunlelogun sí ìgbà yìí. Ó sì kan àwọn ènìyàn lára ní àwọn ibì kan ní orílẹ̀-èdè China, Philippines àti Japan.

“Taipei, Taiwan, ìṣẹlẹ ṣẹlẹ̀ nibẹ, èyí tí ó kó jìnnìjìnnì bá àwọn ènìyàn, tí ó sì kọlu ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè Taiwan ní àárọ̀ ọjọru  tí ó sì pa ènìyàn mẹsan, tí ó sì pa àwọn ènìyàn bíi ẹẹdẹgbẹrun àti mẹtalelọgọta lára. Báyìí ni àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ iná (Fire Department) ní Taiwan ṣe wi,” báyìí ni ẹlòmíràn kan tí ó ń lo X, tí a mọ̀ sí @ZubairSpanish ṣe wí nínú ọ̀rọ̀ tí ó fi sí orí X. 

ÌṢẸLẸ TÓ ṢẸLẸ̀ NÍ TAIWAN 

Ní ọjọru, ìṣẹlẹ kan kọlu Taiwan, ó sì wó àwọn ilé. Ènìyàn mẹsan ló kú. Àwọn ènìyàn tí wọn ju ẹgbẹ̀rún kan lọ ló fi ara pa. 

Àwon kan tí a mọ̀ sí Taiwan’s Central Weather Administration (CWA) sọ pé ilẹ̀ jíjìn kan ní Philippines ló fà ìṣẹlẹ náà.

Bíótilẹ̀jẹ́pé ìṣẹlẹ kò fi bẹ́ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ ní Taiwan, àwọn ènìyàn ní ti ọjọru yìí ló pọ̀ jù ní ọdún marunlelogun sí ìgbà yìí. 

Ìṣẹlẹ tí kò tó eléyìí tí ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1999, èyí tí ó fa ikú fún àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjì àti irínwó, tí ó sì pa àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ní ọna ọgọ́rùn-ún lára

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé ló bà jẹ́. Taiwan jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ìṣẹlẹ lè kọlu.

ÀYẸ̀WÒ 

TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe ayẹwo ọ̀rọ̀ yìí lórí InVid, ibi tí a ti máa ń ṣe àyẹ̀wò fídíò. A ríi pé fídíò yìí ti wà lórí orí ayélujára láti ọjọ́ kẹtadinlọgbọn, oṣù kẹjọ, ọdún 2021 lórí ìwé ìròyìn kan tí a mọ̀ sí Yunan information platform, ibì kan tí wọn ti máa ń gbé ìròyìn jáde. 

Gẹ́gẹ́bí ibi igberoyin jáde yìí ṣe wí, ilé olókè gogoro mẹẹdogun ni àwọn tí wọ́n ń rí sí ọ̀rọ̀ ilé wó lulẹ̀ ní Yunnan, ní China. 

Wọn wó àwọn ilé yìí nítorí pé wọ́n kò bá ìlànà tí ìjọba fọwọ́ sí lọ. 

Ìwé ìròyìn kan tí a mọ̀ sí USA Today náà tún fi fídíò náà sórí YouTube, ibi tí àwọn ènìyàn máa ń fi àwòrán tàbí fídíò sì kí àwọn ènìyàn lè wòó.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ 

Fídíò tí ó ṣe àfihàn àwọn ilé gogoro tí wọn ń wó lulẹ̀ kìí ṣe ti ìṣẹlẹ tí ó ṣẹlẹ̀ ní Taiwan.

Fídíò àwọn ilé tí àwọn tí ó n ṣàkóso ọ̀rọ̀ ilé wò lulẹ̀ ni, ní ọdún 2021, kí àwọn ilé náà má baa fa ikú tàbí pa àwọn ènìyàn lára. 

TAGGED: Taiwan. earthquake

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael April 15, 2024 April 15, 2024
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

Did Tinubu attend same school as Alexander Zingman? Here is what we know

During the launch of the renewed hope mechanisation programme in Abuja on Monday, President Bola…

June 24, 2025

FACT CHECK: No, Nigeria didn’t deploy peace support mission to Israel

A Facebook video purports that Nigeria deployed troops for a joint peace support mission in…

June 24, 2025

FACT CHECK: Did lawmakers skip the national anthem during Tinubu’s Democracy Day speech?

A viral X post claims that Nigeria’s new national anthem was not recited during the…

June 13, 2025

FACT CHECK: Did a military coup oust Paul Biya as Cameroon’s president?

Reports of a military coup in Cameroon ousting President Paul Biya have gone viral on…

June 13, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Rárá, Pope Leo kò bẹ Tinubu kó tú Nnamdi Kanu sílẹ̀ ní àtìmọ́lé

Ẹni kan tí ó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ orí ayélujára sọ pé Robert Francis Prevost, Pope Leo XIV…

CHECK AM FOR WAZOBIA
June 10, 2025

Ḿbà, Pope Leo áyọghị Tinubu kà ọ́ tọ́pụ̀ Nnamdi Kanu nà ǹgá

Ótù onye na Facebook ekwuola na Pope Leo na ụfọdụ ndị Bishop yọrọ onye isiala Bola Tinubu ka ọ tọpụ…

CHECK AM FOR WAZOBIA
June 10, 2025

No, Pope Leo no beg Tinubu to release Nnamdi Kanu

One Facebook user claim sey Pope Leo XVI and oda bishops join mouth beg President Bola Tinubu to release Nnamdi…

CHECK AM FOR WAZOBIA
June 10, 2025

A’a, Paparoma Leo bai nemi Tinubu ya saki Nnamdi Kanu ba

Wani mai amfani da Facebook ya yi ikirarin cewa Paparoma Leo na 16 da wasu limaman coci sun roki shugaban…

CHECK AM FOR WAZOBIA
June 10, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?