Àwọn ènìyàn ti ń pín fídíò kan kiri lórí ayélujára, èyí tó sàfihàn Aliko Dangote, alága Aliko Dangote Group, níbi tó ti ń sọ pé òhun ti se ìfilọ́lẹ̀ ètò ìdókòwò “tí wọ́n ṣètò ẹ̀ láti ran àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ọrọ̀ wọn pọ̀ si.”
Nínú fídíò ìṣẹ́jú méjì yìí, wọ́n sàfihàn Dangote níbi tó ti ń fọwọ́ sí ètò ìdókòwò yìí, èyí tí kò lórúkọ, ó sì rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọgbọ́n ọdún sókè kí wọ́n fowó sínú ìdókòwò yìí.
Àkòrí ọ̀rọ̀ yìí sọ pé: “Ètò bí àwọn ènìyàn se lè máa rówó síi tí mo ṣètò rẹ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.”
“Ní ọdún yìí, o lè kópa nínú ètò tí a lọ́wọ́ sí yìí, tí a ṣètò rẹ̀ láti ran àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ́wọ́ láti ni ọrọ̀ síi,” báyìí ni ara ọ̀rọ̀ inu fidio yìí se sọ.
“Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹbí káàkiri Nàìjíríà ni wọ́n ti ń rí àǹfààní tí ètò yìí lè fún wọn,” báyìí ni wọ́n ní Dangote sọ.
“Jẹ́ kí n jẹ́ kó yé yín, to bá dara pọ̀ mọ́ ètò yìí lónìí, o lè rí owó tó tó mílíọ̀nù méjì àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀ta àti ọgọ́ta ó lé mẹ́fà náírà ní ọ̀sẹ̀ kínní. Èyí kìí se àlá, òótọ́ ni, wàá rí òótọ́ to bá wá ìdí rẹ̀, ó ní àtìlẹ́hìn tó lè jẹ́ kí o se àṣeyọrí,” báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí se sọ.
“Bó se máa ń se rèé: wàá fi owó ìdókòwò ẹgbẹ̀rún ọọdunrun àti ọgọrin náírà sí ètò yìí, wàá sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rí owó (èrè) lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀,” ọ̀rọ̀ yìí ló tún sọ báyìí.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Àbájáde àyẹ̀wò tí Cablecheck, ti TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára se fihàn pé kò sí ilé isẹ́ ìròyìn tó seé gbàgbọ́ tó gbé ọ̀rọ̀ yìí síta. Irú ọ̀rọ̀ báyìí jẹ́ ìròyìn tí àwọn ilé isẹ́ ìròyìn tí wọ́n seé gbàgbọ́ máa fi síta tó bá jẹ́ òótọ́.
Àyẹ̀wò tí a tún se fi hàn pé wọn se àyípadà sí fídíò yìí ni kò lè dàbí ẹni pé Dangote ń sọ̀rọ̀ nípa ètò ìdókòwò yìí.
Nígbà tí a wo ibi ẹnu ẹni tó ń sọ̀rọ̀ nínú fídíò yìí, a rí pé wọ́n gbé nnkan lé orí nnkan kan ni.
Àyẹ̀wò tí a tún se fi hàn pé ara àwọn nǹkan tó wà nínú fídíò yìí jẹ́ ohun tí wọ́n yọ nínú ọ̀rọ̀ tí Dangote sọ nígbà tí ẹnì kan se ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú rẹ̀ ní ọjọ́ kejìdínlógún, osù kẹwàá, ọdún 2025, níbi kan tí wọ́n pè ní Future Investment Initiative, ní Riyadh, ní orílẹ̀ èdè Saudi Arabia.
Aṣọ tí Dangote wọ nígbà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yìí ló wọ̀ nínú fídíò yìí. Àyíká inú fídíò yìí sì bá aṣọ yìí mu. Wọ́n yìí ọ̀rọ̀ Dangote nínú fídíò yìí ni. Ọ̀rọ̀ inú fídíò yìí kì í se irú èyí tó sọ nínú fídíò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò gangan tó se, èyí tó fi hàn pé wọ́n yìí ọ̀rọ̀ inú fídíò yìí padà ni.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa fídíò yìí ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹrindinlogun, osù kejìlá, ọdún 2025, Anthony Chiejina, agbẹnusọ Dangote Group sọ pé irọ́ lásán-làsàn ni ọ̀rọ̀ yìí.
Ó ní Dangote kò sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí. Ó ní wọ́n dá ọgbọ́n sí ọ̀rọ̀ yìí ni kí àwọn ènìyàn lè rò pé òótọ́ ni.