Fídíò kan tí àwọn ènìyàn ń pín kiri lórí TikTok, ibì kan lórí ayélujára tí áwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán tàbí fídíò síta sọ pé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n wà nínú fídíò yìí nígbà tí wọ́n fi ẹ̀hónú hàn sí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà kí wọ́n lè tú Nnamdi Kanu, olórí Indigenous People of Biafra (IPOB), àwọn ènìyàn kan ní gúúsù ilà oòrùn Nàìjíríà tí wọ́n ń jà fún òmìnira láti máa se ìjọba ara wọn sílẹ̀, ní Abuja.
Àwọn ènìyàn pín fídíò yìí ní ọjọ́ ajé, ogúnjọ́, osù kẹwàá, ọdún 2025, nígbà tí àwọn ajàfúnẹ̀tọ́ (activists) áwọn ènìyàn kóra wọn jọ ní orísirísi ibi ní Abuja tí wọ́n sìí ń fi ẹ̀hónú hàn pẹ̀lú ohun tí wọ́n pè ní #FreeNnamdiKanuNow.
Ẹni tí ó se ètò ẹ̀hónú yìí ni Ọmọ́yẹlé Sòwòrẹ́, ẹni tí ó ti díje du ipò Ààrẹ rí, tí ó sì ti ń sọ pé kí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà tú Kanu sílẹ̀ ní àtìmọ́lé láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2025.
Láti ìgbà tí wọ́n tí tún fi àwọn agbófinró mú Kanu ní osù kẹfà, ọdún 2021, ó ti wà ní àtìmọ́lé àwọn òṣìṣẹ́ ààbò ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà tí a mọ̀ sí Department of State Services (DSS), níbi tí ó ti lọ ń fojú ba ilé ẹjọ́ ní Federal High Court, ní Abuja.
“Èyí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Abuja,” báyìí ni àkòrí fídíò yìí tí wọ́n fi síta lórí TikTok se sọ.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rin àti ogójì ni wọ́n ti wo fídíò yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹtadinlọgọta àti ọọdunrun ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn tí wọ́n ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún ni wọ́n pín ọ̀rọ̀ yìí.
Àwọn ènìyàn tún fi àkòrí yìí sójú àwòrán Kanu níbi tí ó ti dìka tí ó sì nọ ọwọ́ sínú afẹ́fẹ́, tí àṣíá (flag) Biafra sì wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fi ẹ̀hónú hàn nínú fídíò yìí ní wọ́n ń rìn ní àwọn òpópónà tí kò jẹ́ àwọn ibi tí wọ́n wà ní Abuja.
ÀBÁJÁDE ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck se àkíyèsí pé àṣíá orílẹ̀ èdè Nepal ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fi ẹ̀hónú hàn nínú fídíò yìí mú dání.
A se ohun tí àwọn elédè òyìnbó ń pè ní reverse image search (àyẹ̀wò síse nípa dídá orí nǹkan padà/délẹ̀) láti se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí. Àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí fi hàn wá pé osù kẹsàn-án, ọdún 2025, ni àwọn ènìyàn fi fídíò yìí síta nígbà tí àwọn ọdọ́ ni Nepal ń fi ẹ̀hónú hàn ní orílẹ̀ èdè náà.
Ọ̀rọ̀ tí ìjọba Nepal sọ pé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí kò gbọ́dọ̀ lo àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára (social media platforms) mẹrindinlọgbọn mọ́ ló fa rògbòdìyàn yìí.
Nígbà tí rògbòdìyàn yìí bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀ si, ìjọba Nepal fún wọn láyé láti máa padà lo àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára mẹrindinlọgbọn yìí.
BÍ CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Fídíò ẹ̀hónú tó ṣẹlẹ̀ ní Nepal ni fídíò yìí. Kìí se fídíò àwọn ọmọ Nàìjíríà ní Abuja tí wọ́n ń fi ẹ̀hónú hàn nítorí pé wọ́n fẹ́ kí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà tú Kanu sílẹ̀ ní àtìmọ́lé.