Fídíò kan lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ ti s’àfihàn àwọn tí wọn sejọba níbi tí wọ́n ti ń si ohun kan tí owó kún inú rẹ̀. Fídíò yìí fi yé wa pé Ààrẹ ilé igbimọ asofin àgbà tẹ́lẹ̀rí ti orílẹ-èdè Gabon fẹ́ salọ lẹhin ifipagba ìjọba.
“KÉRE O: Wọ́n ti mú Ààrẹ ilé igbimọ asofin àgbà ti orílẹ-èdè Gabon tẹ́lẹ̀rí pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó nígbà tí ó fẹ́ salọ,” báyìí ni àkòrí fídíò náà ṣe wí.
Nigeria News Updates ni ó ṣe atẹjade ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ènìyàn tí ó ju mílíọ̀nù kan àti àbọ̀ ló rí í. Ẹgbẹ̀rún mẹta àti igba ènìyàn ló sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ẹgbẹ̀rún méjìlá ènìyàn ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí.
Fídíò yìí tán ranyin. Àwọn ènìyàn sì pín-in ní àwọn orí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise (social media) bíi WhatsApp, X (tí a mọ̀ sí twitter tẹ́lẹ̀) àti Tik Tok. Fídíò yìí s’àfihàn àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n wọ unifọọmu àti àwọn ènìyàn kan níbi tí wọ́n ti ń sí ohun kan tí owó wà nínú rẹ̀.
Wọ́n kọ BEAC sì ara àwọn bọndu owó yìí tí ó jẹ́ ti Bank of Central African States.
BEAC yìí ló ń ṣàkóso ọ̀rọ̀ owó àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Economic and Monetary Community of Central Africa. Lára àwọn orílẹ̀-èdè yìí ni Cameroon, Gabon, the Central African Republic (CAR), Chad, the Republic of the Congo àti Equatorial Guinea.
Central African franc (CFA) ni owo tí àwọn orílẹ̀-èdè yìí ń ńọ.
IFIPAGBA ÌJỌBA NÍ ORÍLẸ̀–ÈDÈ GABON
Gabon, orílẹ̀-èdè kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ní epo rọbi púpọ̀ ní Áfíríkà darapọ̀ mọ́ Commonwealth, ní oṣù kẹfà, ọdún 2022 pẹ̀lúpẹ̀lú pé orílẹ̀-èdè Faransé (France) ni ó ń se ìjọba rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Bíi ìdá àádọ́rùn-ún Gabon ní o jẹ́ igbó.
Ní ọgbọ́n ọjọ́, oṣù kẹjọ, àwọn òṣìṣẹ́ ológun ní Gabon fi ipá gba ìjọba. Wọ́n sì yọ Ali Bongo, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Gabon, ẹni tí ó taku sí orí ìjọba, ẹni tí ó sọ ìjọba di nibininmakusi tí àwọn ará Gabon ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ìbò yàn ní ìgbà kẹta sí ipò Ààrẹ.
Ifipagba ìjọba yìí fi òpin sí isejọba Bongo àti ẹbí rẹ̀ pẹ̀lú ìwà nibininmakusi wọ́n tàbí isọjọba di oyè ìdílé wọn (títakú sórí ìjọba) fún bíi ọdún marunlelaadọta.
Àwọn afipagba ìjọba yìí fi Bruce Oligui Nguema, ẹni tí ó jẹ́ ọga nínú iṣẹ́ ológun jẹ olórí ìṣàkóso orílẹ̀-èdè Gabon títí tí wọ́n yóò fi ṣètò ìjọba tí ó yẹ.
Wọ́n fi Bongo sí àtìmọ́lé. Wọ́n mú ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. Wọ́n sì fi ẹ̀sùn pé ó fẹ́ dá ojú ìjọba bolẹ kàn-án.
“A ti pinnu láti jẹ́ kí àlàáfíà wà nípa fífi òpin sí ìjọba yìí.” Ìkan nínú àwọn òṣìṣẹ́ ológun ló sọ bayìí lórí tẹlifisọn tí a tún máa ń pè ní ẹ̀rọ amohunmaworan (television) tí a mọ̀ sí Gabon24.
Nígbà ifiọrọtonileti tí àwọn òṣìṣẹ́ ológun méjìlá ṣe, àwọn ológun ṣe ìkéde pé èsì ìbò tí àwọn ẹgbẹ́ òsèlú alátakò pè ní jìbìtì kò ní ṣe lo mọ́. Wọ́n fi kún-un pe “gbogbo ẹ̀ka ìjọba kò ní agbára kankan mọ́.”
Ní ọjọ́ keje, oṣù kẹsàn-án, ọjọ́ kẹjọ lẹhin tí wọ́n yọ Bongo kúrò ní ipò Ààrẹ, tí wọ́n sì fi sí àtìmọ́lé, àwọn ológun fi sílẹ̀ nítorí “àìlera rẹ̀.”
Ninu ọ̀rọ̀ tí wọn fi tó àwọn ènìyàn létí lórí tẹlifisọn, Ulrich Manfoumbi, agbẹnusọ àwọn òṣìṣẹ́ ológun sọ pé: “Tí ó bá fẹ́, ó lè lọ sí orílẹ̀-èdè míràn fún àyẹ̀wò ara ẹ.”
ÀYẸ̀WÒ ÌRÒYÌN YÌÍ
TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe àyẹ̀wò fídíò yìí pẹ̀lú Yandex. Àyẹ̀wò yìí fi yé wa pé wọ́n ya fídíò yìí ní ọdún 2022.
Wọ́n ya fídíò yìí nígbà tí wọ́n mú Guy Nzouba-Ndama, ẹni tí ó jẹ́ Ààrẹ ilé igbimọ asofin àgbà tẹ́lẹ̀rí, tí ó sì tún jẹ́ olórí ẹgbẹ́ òsèlú alátakò ní Gabon, ní bodè/bọ́dà (border) Gabon nígbà tí ó ń padà bọ láti Congo pẹ̀lú owó tí ó tó bíi mílíọ̀nù méjì uro (two million euros).
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Fídíò tí ó s’àfihàn pé Ààrẹ ilé igbimọ asofin àgbà tẹ́lẹ̀rí ni orílẹ̀-èdè Gabon fẹ́ salọ lẹhin ifipagba ìjọba kìí se òótọ́.
Wọ́n ya fídíò yìí ní ọdún kan sẹhin kí àwọn òṣìṣẹ́ ológun tó fi ipá gba ìjọba.