TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Ẹdó ni ẹhonu #EndBadGovernance tí àwọn ènìyàn pín fídíò rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀, kìí se Ìbàdàn
Share
Latest News
FACT CHECK: Is Nigeria 4th fastest-growing economy in the world in 2025?
FACT CHECK: How true are Obi’s claims about poverty rate in Nigeria, China and Indonesia?
FACT CHECK: No, Finnish court didn’t approve Simon Ekpa’s extradition to Nigeria
FACT CHECK: Is Cardinal Arinze eligible to be elected as the next Pope?
Rárá, Jonathan kò sọ pé Tinubu yóò se àṣeyọrí nínú ètò ìdìbò fún Ipò Ààrẹ ní ọdún 2027
A’a, Jonathan bai yi hasashen nasarar Tinubu a zaben shugaban kasa na 2027 ba
No, Jonathan no predict Tinubu victory for 2027 presidential election
Ḿbà, Jonathan ágbaghị àmà na Tinubu gà-èmérí ńtùlíáka ónyé ísíàlà ǹkè áfọ̀ 2027
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Ẹdó ni ẹhonu #EndBadGovernance tí àwọn ènìyàn pín fídíò rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀, kìí se Ìbàdàn

Yemi Michael
By Yemi Michael Published October 23, 2024 4 Min Read
Share

Ní ọjọ́ ajé, àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń lo ohun ìgbàlódé ibaraẹnise sọ pé àwọn afiẹhonu hàn kan ní Ìbàdàn, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sọ pé kí àwọn òṣìṣẹ́ ológun gba ìjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Bọla Tinubu.

Nínú fídíò ìṣẹ́jú kan yìí, ọkọ̀ kan tí ó ní ẹ̀hìn tí ó lè fi gbé àwọn ènìyàn tí àwọn òṣìṣẹ́ ológun/sójà wà nínú rẹ̀ ni a rí tí ó ń rìn díẹ̀díẹ̀ lójú ọ̀nà tí àwọn ènìyàn kan sì ń fi ẹhonu hàn níwájú rẹ̀.

A gbọ ohun ọkùnrin kan tó ń pariwo pé: “Tinubu gbọ́dọ̀ lọ. A fẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ ológun Nàìjíríà gba ìjọba. N kò mọ ìdí tí wọ́n fi ń bẹ̀rù.”

Àwọn ènìyàn tí pín fídíò yìí lọpọlọpọ lórí àwọn ohùn ibaraẹnise/ibaraẹnisọrọ bíi fesibuuku , ohun ibaraẹnise àlámì krọọsi àti Wasapu.

Ẹnì kan tí ó ń lo X tí a mọ̀ sí @SabinaNkiru tí ó ní àwọn ènìyàn tí ó lè ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá tí wọ́n ń tẹ̀lée fi fídíò kan síta tí àkòrí rẹ̀ sọ pé: “Àwọn afiẹhonu hàn ní Ìbàdàn dí ọ̀nà fún àwọn ọkọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ológun, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ wọ́n pé kí ló dé tí ẹ̀ru se ń bà wọ́n láti gba ìjọba lọ́wọ́ Tinubu.”

Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan àti ẹẹdẹgbẹrin ni wọ́n ti rí  ọ̀rọ̀ náà tí a fi pamọ níbí. Àwọn ènìyàn méjìdínlógún ló ti fi í síta gẹ́gẹ́bí wọ́n se kọọ.

Ẹlòmíràn tí ó ń lo X tí a mọ̀ sí @PrinceUjay, tí ó ní àwọn ènìyàn tí wọ́n ń tẹ̀lée tí wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún marundinlogoji fi fídíò náà síta pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé:

“Nǹkan di wàhálà síi ní Ìbàdàn bí àwọn afiẹhonu hàn tí wọ́n dí ọ̀nà tí àwọn ọkọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ológun yóò gbà kọjá tí wọ́n sì ní kí àwọn òṣìṣẹ́ ológun gba ìjọba, wọ́n ní ìnira ìgbà ìjọba Tinubu yìí kò ṣeé fara dà.”

Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjì ni wọ́n ti rí ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ènìyàn mẹtadinlọgbọn ló fi síta gẹ́gẹ́bí wọ́n ṣe kọọ. A fi pamọ níbí.

A fi àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tí àwọn ènìyàn sọ nípa ọ̀rọ̀ náà pamọ níbí àti níbí.

AYẸWO 

Ayẹwo fídíò náà fi yé wa pé ẹni kan tí ó ń lo Tiktok tí a mọ̀ sí @mikkyforlife0 ló fi fídíò náà síta. Àwọn àyẹ̀wò lórí Tiktok ẹni yìí fi yé wa pé wọ́n fi fídíò náà síta ní ọjọ́ kejì, oṣù kẹjọ, ọdún 2024 nígbà tí àwọn ènìyàn se ẹhonu tí wọ́n pè ní #EndBadGovernance ní Nàìjíríà.

Ẹhonu nípa ọ̀wọ́n gógó àwọn nǹkan yìí wáyé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi ní Nàìjíríà láti ọjọ́ Kínní sí ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹjọ, ọdún 2024.

Ní àfikún, àwọn ènìyàn fi ohun ìpolongo ìbò fún Asue Ighodalo, Ólùdíje fún Ipò Gómìnà nínú ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party (PDP) sí orí ohun ìpolówó kan lójú ọ̀nà nígbà ìfiẹhonuhan yìí ní Benin City,olú ìlú Ìpínlẹ̀ Edo.

Àwọn afiẹhonu hàn yìí rìn kọjá òpópónà tí ó dá sí méjì tí ó wà ní iwájú ibi tí àwọn ọkọ̀ ilé epo TotalEnergies máa ń wà ní Benin City. Ilé epo yìí wà ní ojú ọ̀nà tí a mọ̀ sí Upper Mission Road, ní Benin City.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ 

Ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé àwọn afiẹhonu hàn ní Ìbàdàn sọ pé kí àwọn òṣìṣẹ́ ológun gba ìjọba kìí se òótọ́ nítorí pé Benin City ni wọ́n ti ya fídíò náà nínú oṣù kẹjọ nígbà tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń fi ẹhonu hàn nípa àwọn nǹkan tí wọ́n wọ́n gógó ní Nàìjíríà.

TAGGED: #EndBadGovernance protest, Benin, Fact check in Yoruba, Ibadan, News in Yorùbá

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael October 23, 2024 October 23, 2024
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

FACT CHECK: Is Nigeria 4th fastest-growing economy in the world in 2025?

A viral post claims, based on International Monetary Fund (IMF) projections, that Nigeria ranks fourth…

May 9, 2025

FACT CHECK: How true are Obi’s claims about poverty rate in Nigeria, China and Indonesia?

Peter Obi, Labour Party (LP) presidential candidate in the 2023 elections, sparked a debate with…

May 5, 2025

FACT CHECK: No, Finnish court didn’t approve Simon Ekpa’s extradition to Nigeria

On Tuesday, some social media users and blog sites made a post claiming that a…

April 24, 2025

FACT CHECK: Is Cardinal Arinze eligible to be elected as the next Pope?

A social media user has claimed that Francis Arinze, a Roman Catholic cardinal, is the…

April 21, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Rárá, Jonathan kò sọ pé Tinubu yóò se àṣeyọrí nínú ètò ìdìbò fún Ipò Ààrẹ ní ọdún 2027

Ní ọjọ́ ajé, ọ̀rọ̀ kan to sọ pé Goodluck Jonathan, Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ sọ pé Ààrẹ Bọla Tinubu…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

A’a, Jonathan bai yi hasashen nasarar Tinubu a zaben shugaban kasa na 2027 ba

A ranar Talata ne wani rahoto da ke ikirarin cewa tsohon shugaban kasa Goodluck Jonathan ya yi hasashen nasarar Shugaba…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

No, Jonathan no predict Tinubu victory for 2027 presidential election

On Tuesday, one report wey claim sey former President Goodluck Jonathan predict President Bola Tinubu victory for di 2027 presidential…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

Ḿbà, Jonathan ágbaghị àmà na Tinubu gà-èmérí ńtùlíáka ónyé ísíàlà ǹkè áfọ̀ 2027

N’ubọchị Tuesde, ozi na-ekwu na onye bụburu onye isiala Naijiria, bụ Goodluck Jonathan, gbara àmà na onyeisiala Bola Tinubu ga-emeri…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 19, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?