Àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń lo ohun íbaraẹnise orí ayélujára tí sọ pé fidio kan tí ó sàfihàn àwọn ọkọ̀ tí wọ́n ṣètò fún ogun jíjà jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà.
Àwọn ènìyàn lo fídíò yìí, èyí tí àwọn ènìyàn pín jù lórí Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ orí ayélujára, láti sọ pé ètò ààbò kò dára ní Nàìjíríà.
Ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹjọ, ọdún 2025, ẹni kan tí ó ń lo Facebook, tí ó ń jẹ́ “Urhobo one love” fi fídíò kan tó sàfihàn àwọn kan tí wọ́n gbé ìbọn dání tí wọ́n fi ipá gba àwọn ọkọ̀ tí wọ́n ṣètò fún ààbò níbì kan.
“Àwọn ẹni yìí ní pé ọlọ́dẹ àti àgbẹ̀ ni àwọn” nínú àkòrí tó wà nínú fídíò yìí. Biotilẹjẹpe ọ̀rọ̀ orí Facebook yìí kò dárúkọ ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀, àwọn ènìyàn tí wọ́n ń tẹ̀lée ojú òpó Facebook yìí sọ pé Nàìjíríà ni ìṣẹ̀lẹ yìí ti ṣẹlẹ̀.
“Àwọn òṣìṣẹ́ ológun gan an kò ní irú àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń jagun báyìí,” ẹni kan tí ó ń lo Facebook ló sọ̀rọ̀ nípa fídíò yìí báyìí.
CableCheck, ti TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára, ṣàkíyèsí pé àwọn ènìyàn ti pín fídíò yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára (social media accounts).
Ẹni kan tí ó ń lo Facebook tí ó ń jẹ́ “Debra O Kalus” tún fi fídíò tó sọ pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fi ìwà ìpayà já àwọn ènìyàn láyà tí wọ́n ń pè ní “boko haram terrorists” kọlu àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní àwọn àgbègbè kan.
“ÀWỌN KAN TÍ WỌ́N Ń FI ÌWÀ ÌPAYÀ JÁ ÀWỌN ÈNÌYÀN LÁYÀ TÍ A MỌ̀ SÍ BOOKHAM KỌLU ÀWỌN ỌJÀ ÀWỌN ÀGBÈGBÈ KAN NÍ ÌPÍNLẸ̀ KWARA NÍ NÀÌJÍRÍÀ”, báyìí ni àkòrí tí ẹni yìí fún ọ̀rọ̀ yìí se sọ.
Ibì kan lórí Facebook tí ó ń jẹ́ “NIGERIANS”, tí ó ní àwọn ènìyàn tí wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún irínwó, fi fídíò yìí síta pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé: “#InsecurityInNigeria àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fi ìwà ìpayà já àwọn ènìyàn láyà sàfihàn àwọn ọkọ̀ àti àwọn ohun ìjagun fún ohun tí wọ́n ń se. Àjọ àwọn ọlọ́pàá, àwọn òṣìṣẹ́ ológun.”
O lè wọ fídíò yìí níbí àti níbí.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck se àyẹ̀wò fídíò yìí nípa lílo Google Lens. Àbájáde àyẹ̀wò yìí fi yé wa pé ọdún 2024 ni ìṣẹ̀lẹ yìí ti ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Burkina Faso.
Àwọn àwòrán kan láti inú àwọn ìròyìn fi hàn pé ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹjọ, ọdún 2024, àwọn ènìyàn kan tí wọ́n máa ń fi ìwà ìpayà já àwọn ènìyàn láyà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Jama’at Nusrat ul-Islam wa al-Muslimin (JNIM), tí ó jẹ́ ara al-Qaeda, tí wọ́n sá pamọ́, kọlu àwọn òṣìṣẹ́ ológun ní gúúsù ilà oòrùn Burkina Faso.
Nígbà tí ìkọlù yìí wáyé, ìròyìn sọ pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fi ìwà ìpayà já àwọn ènìyàn láyà yìí pa àwọn òṣìṣẹ́ ológun (soldiers) ọgọ́rùn-ún, wọ́n sì fipá gba àìmọye àwọn ọkọ̀ tí àwọn ènìyàn kan ṣètò wọn fún ogun jíjà.
O lè ka ìròyìn yìí níbí àti níbí.
Àwòrán inú àwọn ìròyìn yìí bá àwọn àwọ̀ ọkọ̀ àti àwọn igi tí wọ́n wà láìyíká tí a rí nínú fídíò tí àwọn ènìyàn ti pín káàkiri yìí mu.
Ẹni kan tún fi irú fídíò yìí mìíràn sórí X, ohun ìgbàlódé íbaraẹnise alámì krọọsi ti a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Fídíò àwọn ènìyàn kan tí wọ́n gbé ìbọn dání pẹ̀lú àwọn ọkọ̀ tí àwọn ènìyàn kan ṣètò rẹ̀ fún ogun jíjà tí wọ́n ń fipá gbà kò ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà. Burkina Faso ló ti ṣẹlẹ̀.