Àwòrán kan tí àwọn ènìyàn ń pín kiri ní orí ohun ìgbàlódé ìbáraẹnise (social media) ti ṣe àfihàn àwọn hẹlikọputa tí àwọn ènìyàn fi rọkẹẹti já lulẹ̀ láti ojú Òfurufú.
Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ nípa àwòrán náà sọ pé àwọn Hamas, àwọn afipasenkan tí orílẹ̀-èdè Palestine ni ó já àwọn hẹlikọputa náà tí ó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lulẹ̀ nínú oogun tí ó ń lọ lọ́wọ́ láàárín orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti Hamas.
“Wọ́n tí ń bá àwọn hẹlikọputa Ísírẹ́lì jẹ́,” báyìí ni atẹsita tí @Sentletse, tí ó ní àwọn olutẹnle ọọdunrun ó dín ní mẹtadinlọgbọn ṣe wí ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹwàá, ọdún 2023.
Israeli helicopters getting smashed 💥 pic.twitter.com/po5AL4PRoo
— Sentletse 🇷🇺🇿🇦🇵🇸 (@Sentletse) October 8, 2023
Nínú fídíò yìí, hẹlikọputa méjì, ìkan wá lókè ìkan, tí wọ́n ń fò kí misaili (missiles) tó kọlù wọ́n já lulẹ̀, wọ́n gba iná, wọ́n sì já sí wẹ́wẹ́.
Nígbà tí TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára gbé ìròyìn yìí jáde lédè òyìnbó, àwọn mílíọ̀nù mẹwa àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ènìyàn ni ó wòó. Ẹgbẹ̀rún mẹjọ ènìyàn ni ó fẹ́ràn ọ̀rọ̀ náà, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ènìyàn ló sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
#HamasTerrorists
Two helicopters of Israel Shot down by Hamas#IsraelUnderAttack #Gaza #Sderot #Israël #Palestine #Israel #Hamas #War #AlMayadeen #Palestine #AlAqsaFlood #طوفان_الأقصى #IsraelUnderAttack #mosad #IndiaWithIsrael #TelAviv #KuShiv #IStandWithIsrael #savas pic.twitter.com/ryeisXoax0
— Arun Gangwar (@AG_Journalist) October 7, 2023
Ní ọjọ́ keje, oṣù Kẹwàá, Arun Gangwar, onisẹ ìròyìn, ẹni tí ó sọ pé ohun tí bá oríṣiríṣi àwọn ilé ìròyìn ṣe iṣẹ́, lára àwọn ilé ìṣe ìròyìn bíi India Daily Live, fi àwòrán náà síta. Ó gbe Ísírẹ́lì lẹhin nínú ọ̀rọ̀ tí ó kọ pé: “#HamasTerrorists, hẹlikọputa méjì tí Ísírẹ́lì ni àwọn Hamas tí já lulẹ̀, Gangwar ni ó wí báyìí lórí ohun Ìbáraẹnise tí a mọ̀ sí X (abẹyẹfo, formerly known as Twitter).
Israeli helicopters getting smashed 💥 pic.twitter.com/po5AL4PRoo
— Sentletse 🇷🇺🇿🇦🇵🇸 (@Sentletse) October 8, 2023
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà igba àti mẹrinla ni ó ti wòó/ríi ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ènìyàn ẹẹdẹgbẹta dín ní mọ́kànlá ni ó fẹ́ràn rẹ̀, àwọn ènìyàn aadoje ló ti sọ̀rọ̀ nípa ẹ, àwọn ènìyàn marundinlọgọrun ni ó pín in.
ÀWỌN NKAN TÍ Ó KỌ́KỌ́ ṢẸLẸ̀
Ní ọjọ́ keje, oṣù kẹwàá, ọdún 2023, àwọn afipasenkan Hamas wọnú Ísírẹ́lì ní ọ̀nà aiyẹ láti Gaza láti ojú Òfurufú, ilẹ̀ àti ojú omi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ wàhálà lórí rògbòdìyàn tí ó ti pẹ láàárín Ísírẹ́lì àti Palestine.
Lẹhin ìkọlù náà, àwọn ènìyàn bíi egbèje ni wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn. Àwọn ènìyàn bíi igba ni wọ́n kó sí Àhámọ́.
Àwọn afipasenkan Hamas ni ó ń darí ohun tí ó ń lọ ní Gaza. Gaza wà láàárín Ísírẹ́lì àti Mediterranean sea. Gaza sún mọ́ orílẹ̀-èdè Igipiti (Egypt).
Hamas pe àkọlù náà ní “Operation Al-Aqsa Storm.” Wọ́n ní ọdún méjì ni àwọn fi ṣètò/pilẹ̀ ẹ.
Gẹ́gẹ́bí àwọn adarí afipasenkan ẹgbẹ́ Hamas ṣe wí, rọkẹẹti tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún ni wọ́n fi kọlu Ísírẹ́lì láti fi ìyà jẹ wọ́n fún ṣíṣe mọ́sálásí Al-Aqsa ní orílẹ̀-èdè Jerúsálẹ́mù ní ọ̀nà tí kò yẹ àti pípa àwọn ọmọ Palestine ọgọrun àìmọye.
Bẹ́ńjámínì (Benjamin) Nentayahu, Olórí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lérí pé ohùn yóò pa àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hamas run. Ó sọ fún àwọn tí ó ń gbé ní Gaza kí wọ́n sá àsálà fún ẹ̀mí wọn nítorí pé àwọn ọmọ oogun Ísírẹ́lì yóò fi ojú wọn fí iná.
Njẹ́ fídíò yìí ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìkọlù Ísírẹ́lì láti ọwọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hamas?
ÀYẸ̀WÒ ÌWÉ ÌRÒYÌN THECABLE
Àyẹ̀wò tí TheCable ṣe fi yé wa pé àwọn ènìyàn ti ń pín fídíò yìí láti ọjọ́ keje, oṣù kẹwàá, ọdún 2023, ọjọ́ tí Hamas kọlu Ísírẹ́lì lọ́nà airotẹlẹ. Àwọn ènìyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ tún pín fídíò yìí ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹwàá, ọdún 2023.
Nígbà tí a tún ṣe àyẹ̀wò síi, a ríi pé àwọn ènìyàn ti pín fídíò yìí ní ọjọ́ kẹta, oṣù kẹwàá, ọdún 2023 lórí YouTube, ibi tí àwọn ènìyàn ti máa ń pín àwòrán ara wọn lórí ayélujára. Àwọn tí ó pín in ni a mọ̀ sí Kazinka warrior.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2022, Bohemian interactive, àwọn tí ó ń ṣe ohun ìṣeré tí a mọ̀ sí Arma 3, sọ pé fídíò inú ohun ìṣeré yìí jẹ́ ti oogun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Ukreeni (Ukraine).
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Fídíò tí ó ṣe àfihàn hẹlikọputa méjì tí àwọn ènìyàn fi rọkẹẹti já lulẹ̀ láti ojú Òfurufú kò ní nkankan ṣe pẹ̀lú oogun tó ń lọ lọ́wọ́ láàárín Isírẹ́lì àti Hamas.
Inú ohun ìṣeré Arma 3 ni ó wà.