Fídíò kan ní orí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise (social media) sọ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ń fi ẹhọnu hàn ní ọjọ́ Kínní, oṣù kẹjọ, ọdún 2024 nítorí pé àwọn nǹkan wọn gógó ba agọ ọlọ́pàá tó wà ní Nyanya ní Abuja jẹ́.
Fídíò tí kò pé ìṣẹ́jú kan yìí, èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí rí lórí ayélujára ṣe àfihàn àwọn ọdọmode ọkùnrin kan níbi tí wọ́n ti ń ba àwọn ohun ìní àwọn ènìyàn jẹ́ níbi tí àwọn ọlọ́pàá máa ń dúró sí ní òpópónà tí a mọ̀ sí Abuja-Keffi expressway.
Ohùn kan nínú fídíò yìí sọ pé àwọn ọdọmode yìí ba agọ ọlọ́pàá yii tó wà ní ìgbèríko Abuja jẹ́ nítorí pé Nàìjíríà le mọ wọ́n.
Ẹni tí ó fi fídíò yìí sita tí a mọ sí Okezie Atani fi sórí X, ohun ibaraẹnise ayélujára alámí krọọsi tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀. Orúkọ tí Atani ń lò lórí X ni @Onsogbu. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún ló ti rí/wo ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ènìyàn aadọjọ ó lé ìkan ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún àti mẹẹdogun ló pín in.
Ènìyàn kan tún fi fídíò yìí sórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ (facebook) àti ohun ìbáraẹnisọ̀rọ̀ (whatsapp).
IFIẸHỌNUHAN TÍ ÀWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ PÈ NÍ #ENDBADGOVERNANCE
Ní ọjọ́ àlàmísì, oṣù kẹjọ, ọdún 2024, àwọn ọdọ tú jáde ní àwọn ibì kan ní Nàìjíríà láti fi ẹhọnu hàn nítorí pé oúnjẹ wọn gógó, owó epo rọbi ti lọ sókè, àìsíìfọkànbalẹ̀, owó gọbọyi tí àwọn olóṣèlú fi ń ṣe ìjọba ní Nàìjíríà àti àwọn nǹkan mìíràn.
Ìjọba àpapọ̀ bẹ àwọn ènìyàn tó ṣètò ifiẹhọnuhan yìí pé kí wọ́n ṣe sùúrù.
Àwọn ọlọ́pàá sọ pé kí àwọn tó ṣètò ifiẹhọnuhan yìí jẹ́ kí ìjọba dá wọn mọ̀ kí àwọn ẹlòmíràn má baà sọdi nǹkan tí kò dára.
Ní Abuja, àwọn ìjọba sọ pé àwọn tí wọ́n fẹ́ fi ẹhọnu hàn kò gbọ́dọ̀ kọjá MKO Abiola Stadium. Àwọn tí wọ́n ṣètò ifiẹhọnuhan yìí yarí, wọ́n sì lọ fi ìbínú hàn ní agbègbè Eagle Square, Unity Fountain àti àwọn ibòmíràn.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ
Láti lè mọ bóyá àwọn afẹhọnuhan fọwọ́ kan agọ ọlọ́pàá yìí, TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára lo Google Maps àti Google Earth.
Google Maps fihàn wá pé agọ ọlọ́pàá yìí tó ìrìn ìṣẹ́jú márùn-ún tí ènìyàn bá wa mọto láti ibi tí àwọn ọlọ́pàá máa ń dúró sí, ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀.
Google Earth fihàn pé kò sí agọ ọlọ́pàá kankan níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀.
TheCable kàn sí Josephine Adeh, agbẹnusọ fún àwọn ọlọ́pàá ní federal capital territory (FCT). Ó sọ pé àwọn afẹhọnuhan yii kò jó agọ ọlọ́pàá yìí.
Àwọn ọlọ́pàá FCT sọ pé ohun kan tí wọ́n ń pè ní “traffic control container compartment”, ibi tí àwọn ọlọ́pàá máa ń dúró sí ní Nyanya ni wọ́n jó.
“Ìròyìn kan tó ń tàn kiri pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fi ẹhọnu hàn jó agọ ọlọ́pàá ní Nyanya kìí ṣe òótọ́. Nnkan tí wọ́n dáná sun ni container compartment tí ọlọ́pàá máa ń dúró sínú ẹ̀ níbi tí wọ́n máa ń dúró sí,” báyìí ni atẹjade láti àwọn ọlọ́pàá wí.
“Àwọn ènìyàn mẹrin fẹ́ ba agọ ọlọ́pàá tó wà ní Tipper garage jẹ́. Àwọn ènìyàn mẹ́rin tó fẹ́ ṣe nǹkan yìí tí a fura sí ni Mathias Jude, ọmọ ọdún mọkandinlọgbọn, Mohammed Ahmed, ọmọ ọdún mẹtalelogun, Abba Jibril, ọmọ ọdún méjìdínlógún àti Mohammad Haruna, ọmọ ọdún méjìdínlógún. A ti kó wọn,” àwọn ọlọ́pàá ló sọ báyìí.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn sọ pé àwọn afẹhọnuhan dáná sun agọ ọlọ́pàá ní Nyanya kìí ṣe òótọ́. Nǹkan tí àwọn ènìyàn yìí dáná sun ni nǹkan tí ọlọ́pàá máa ń dúró sí (police container compartment) tí wọ́n bá ń darí ọkọ̀ ní Nyanya.