Lẹ́hìn ìgbà tí àwọn oníwà jàgídíjàgan kan kọlu àwọn ènìyàn tí wọ́n ń jọ́sìn ní ẹ̀ka Christ Apostolic Church (CAC) ní Òkè ìṣẹ́gun ní Eruku ní ìpínlẹ̀ Kwara ní ọjọ́ kejìdínlógún, osù kọkànlá, ọdún 2025, àwọn àwòrán kan sàfihàn pé àwọn ènìyàn kan gbé ìbọn dání láti dá ààbò bo ara wọn, èyí sì ti di ohun tí àwọn ènìyàn ń pín kiri lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára.
Ẹnì kan se fídíò ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nígbà tó ń ṣẹlẹ̀, ó sì fi sí orí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára (social media platforms).
Àwọn ènìyàn mẹ́ta lára àwọn tí wọ́n ń jọ́sìn ni wọ́n pa, wọn sì fipá gbé àwọn ènìyàn mejidinlọgbọn lọ nígbà ìkọlù yìí.
Ìkọlù yìí ṣẹlẹ̀ láàárín ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn ń sọ pé àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni ni àwọn oníwà jàgídíjàgan yìí ń kọlù jù àti ọ̀rọ̀ tí Donald Trump, ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà sọ pé ohun yóò rán àwọn ọmọ òṣìṣẹ́ ológun sí Nàìjíríà láti dá wàhálà yìí dúró tí ìjọba Nàìjíríà kò bá gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ.
Ìkọlù àwọn ilé ìjọsìn àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni ti pọ̀ sí ní Nàìjíríà, èyí ló jẹ́ kí àwọn ènìyàn máa sọ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ní láti bẹ̀rẹ̀ sí ní dá ààbò bo ara wọn.
Láàárin ìkọlù yìí, àwọn ènìyàn kan bẹ̀rẹ̀ sí ní pín àwọn àwòrán tó sàfihàn àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni tí wọ́n gbé ìbọn dání.
ÀWÒRÁN TÍ WỌ́N YỌ NÍNÚ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀FẸ̀ NI ÀWỌN ÈNÌYÀN PÈ LÓÒÓTỌ́
Ní ọjọ́ kìíní, osù kejìlá, ọdún 2025, Oriental Times, ibì kan tí wọ́n ti máa ń gbé ìròyìn jáde fi àwòrán kan síta tó sàfihàn ọkùnrin kan tó gbé ìbọn AK-47 àti Bíbélì dání ní ẹ̀gbẹ́ obìnrin kan.

Àkòrí àwòrán yìí sọ pé: “A rí pasitọ Nàìjíríà tó ń wàásù tó gbé ìbọn AK-47 dání lori títì.”
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹrin àti ẹẹdẹgbẹta ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rin àti ọgọrin ló sọ̀rọ̀ nípa ẹ, àwọn ènìyàn igba àti ọgbọ̀n ló pín in.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck lo Google Lens láti se reverse image search. A ríi pé àwòrán yìí jẹ́ ti àwòrán àwòrán fídíò kan tí ẹnì kan tí wọ́n ń pè ní Pastor Destiny, ẹnì kan tó máa ń se àwọn ohun ẹ̀fẹ̀ fi síta.
Ẹni yìí fi fídíò yìí síta lórí ibi íbaraẹnisọrẹ rẹ̀ tó ń jẹ́ REAL DON DADDY, ní ọjọ́ kẹrinlelogun, osù kọkànlá, ọdún 2025, ó sì sàfihàn ara rẹ̀ àti obìnrin kan tó ń se ìwàásù lórí títì, obìnrin yìí sì gbé ìbọn AK-47 àti Bíbélì dání.
Destiny kanjú mọ́ àdúrà àti ìwàásù, ó sì ń fi àwàdà síi.
ÀWÒRÁN ÀWỌN OLÙJỌSÌN TÍ WỌ́N GBÉ ÌBỌN DÁNÍ TÍ WỌ́N FI AI SE
Àwòrán mìíràn tí àwọn ènìyàn ti ń pín kiri ni èyí tó sàfihàn àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń lọ sí ilé ìjọsìn àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni pẹ̀lú ìbọn AK-47 nínú ilé ìjọsìn àwọn elesin ìgbàgbọ́. Àwọn ènìyàn ti pín àwòrán yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà lórí ayélujára. Ara àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí síta sọ pé ilé ìjọsìn yìí wà ní ìpínlẹ̀ Kwara.
Ní ọjọ́ kejì, osù kọkànlá, ọdún 2025, ẹni kan tó ń jẹ́ @BLEXGUY lórí X, ohun ìgbàlódé íbaraẹnise alámì krọọsi ti wọ́n ń pè ní Twitter tẹ́lẹ̀ fi ọ̀rọ̀ yìí síta pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé: “A ki yín kúu ọjọ́ ìsinmi láti Kwara…dá ààbò bo ara rẹ. Má dúró de ètò ààbò.”

Àwọn ènìyàn tí wọ́n ju mílíọ̀nù kan ni wọ́n ti rí ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn tí wọ́n ju ẹgbẹ̀rún méjì ni wọ́n ti pín in, àwọn ènìyàn ọọdunrun àti mẹsan-an ni wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí se ọ̀rọ̀ sọ, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹsan-an ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí.
Àyẹ̀wò ti a se síi fi hàn pé artificial intelligence (AI) ni wọ́n fi se àwòrán yìí. Ìdí àkọ́kọ́ ni pé ìka mẹrin ni ọwọ́ ọ̀tún obìnrin tó gbé ìbọn AK-47 dání tó dúró láàárin àwòrán yìí ní.
Ìdí kejì ni pé nígbà tí a ṣàyẹ̀wò àwòrán yìí lórí SynthID, ohun kan tí wọ́n fi máa ń dá àmì sójú tàbí fi nǹkan sójú ọ̀rọ̀, ó sàfihàn pé Google AI ni wọ́n fi sé.
Àwòrán mìíràn tó sàfihàn obìnrin kan tó wọ jakẹti láti dáàbò bo ara rẹ̀ tó gbé ìbọn AK-47 àti Bíbélì dání tí àwọn ènìyàn ti pín kiri ni ẹnì kan ti fi síta lórí Facebook pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé: “ọwọ́ kan pẹ̀lú Bíbélì, ọwọ́ kejì pẹ̀lú ìbọn, èyí ni àsọtẹ́lẹ̀ tí ìwé ẹ̀sìn ti sọ. Nehemiah 4: 3-17. Bàbá, dá ààbò bo àwọn olugbagbọ ní orúkọ Jésù. Ẹ jọ̀wọ́ gbàdúrà fún àwọn olugbagbọ.”

Nígbà tí Cablecheck se àyẹ̀wò àwòrán yìí lórí SynthID, èsì fi hàn pé Google AI ni wọ́n fi sé.
ÀWÒRÁN ÌRÁNṢẸ́ ỌLỌ́RUN TÓ GBÉ ÌBỌN DÁNÍ NÍNÚ ILÉ ÌJỌSÌN ÀWỌN ẸLẸ́SÌN KRISTẸNI TÍ ÀWỌN ÈNÌYÀN TÚN SE NÍ ÀÌMỌYE ÌGBÀ
Àwòrán mìíràn tí àwọn ènìyàn lò tí wọ́n fi sọ pé àwọn ènìyàn ń lọ sí ilé ẹ̀sìn àwọn Kristẹni pẹ̀lú ìbọn láti dá ààbò bo ara wọn jẹ́ ti ọkùnrin kan tó wọ cassock, aṣọ tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ẹlẹ́sìn Kátólíìkì máa ń wọ̀, tó gbé ìbọn dání.

Ibì kan lórí Facebook tí wọ́n pè ní Chinedu Anichi Tv, tó ní àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mejidinlaaadọrun tí wọ́n ń tẹ̀lée fi àwòrán yìí síta pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé: “Eléyìí ni ọ̀nà kan soso tó kù tí àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni fi lè jọ́sìn ní ọjọ́ ìsinmi. Ní tòótọ́, orílẹ̀ èdè kan tó dára ti wà tẹ́lẹ̀.”

CableCheck ríi pé àwòrán ọkùnrin ẹlẹ́sìn Kátólíìkì yìí ti wà lórí ayélujára láti ọdún 2017. Àwọn ènìyàn ti tún àwòrán yìí lò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti lè sọ pé bí nǹkan se rí rèé.
Ní osù karùn-ún, ọdún 2022, TheCable gbé àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ kan jáde láti fi idi ọ̀rọ̀ kan tó sọ pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà nínú àwòrán yìí gbé ìbọn dání láti dá ààbò bo ara rẹ̀ ni ọwọ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fi ẹ̀hónú hàn ní Sokoto, tí wọ́n fẹ́ kí wọn fi àwọn ènìyàn ti wọn fi ẹ̀sùn kan pé àwọn ni wọn pa Deborah Emmanuel sílẹ̀ múlẹ̀.
Deborah jẹ́ ọmọ ilé ìwé tí wọ́n ń pè ní Shehu Shagari College of Education, ní ìpínlẹ̀ Sokoto.
Àwọn ènìyàn kọlu Deborah, wọ́n sì dáná sun ún nítorí pé wọ́n ló sọ ohun tí kò yẹ kó sọ nípa ẹ̀sin ìmàle/mùsùlùmí.