Ọ̀pọ̀lọpọ̀ atẹjade lórí àwọn ohun ibaraẹnise ìgbàlódé ti sọ pé ìkan nínú àsíá tí ó wà lẹ́hìn Ààrẹ Bọla Tinubu nígbà tí ó ń bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹjọ, ọdún 2024 jẹ́ ti orílẹ̀-èdè Russia.
Nínú ọ̀rọ̀ tó sọ lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán (television) pẹ̀lú àwọn ọmọ Nàìjíríà, ó sọ̀rọ̀ lórí ifẹhọnuhan tí wọ́n pè ní #EndBadGovernance tí àwọn ènìyàn ṣe káàkiri Nàìjíríà. Nínú ọ̀rọ̀ yìí, Tinubu sọ pé kí wọ́n dá ifẹhọnuhan yìí dúró kí òhun lè bá wọ́n sọ̀rọ̀.
Ó ní pé òhun kò gbà kí àwọn kan lo ifẹhọnuhan náà láti dá wàhálà sílẹ̀. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kò sí àyè fún ẹlẹyamẹya ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ó sọ̀rọ̀ lọpọlọpọ lórí àwọn àṣeyọrí rẹ̀ láti ìgbà tó ti di Ààrẹ. Ó sì sọ ìdí tí òhun fi ṣe àwọn nǹkan tí òhun ṣe. Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn nnkan tí òhun ṣe náà ṣe kókó láti lè jẹ́ kí àyípadà rere dé bá Nàìjíríà.
Àsíá méjì ló wà ní ẹgbẹ Tinubu nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ yìí. Ìkan nínú àsíá yìí jẹ́ ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Èkejì ní àmì mìíràn fún idankanmọ
“Kí ló dé tí àsíá Russia ṣe wà níbi tí àsíá Nàìjíríà wà? Ṣé Tinubu wà ní Russia ni? kí ló ṣẹlẹ̀???” Lára àwọn ènìyàn tó ń lo X ló fi atẹjade yìí síta lórí X, èyí tí ó jẹ́ ohun ibaraẹnise ìgbàlódé orí ayélujára.
Àwọn èsì lábẹ́ atẹjade kan tí ó sọ pé kí àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí sọ pé àsíá Russia ni àsíá náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára àwọn ènìyàn tó fèsì sì ọ̀rọ̀ yìí ni ẹ̀rù bà. Jìnnìjìnnì bá wọ́n. Jìnnìjìnnì yìí ṣẹlẹ̀ sí wọ́n nítorí pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n fi ẹhọnu hàn lórí àwọn nǹkan jíjẹ, mímu àti lílo tó wọ́n gógó gbé àsíá Russia dání dípò ti Nàìjíríà nígbà tí wọ́n ń fi ẹhọnu hàn.
Àwọn ènìyàn kọ́kọ́ rí àsíá Russia náà ní ìgbà ifẹhọnuhan ní Kano ní ọjọ́ àlàmísì. Lẹ́hìn èyí, àwọn ènìyàn tún rí àsíá Russia náà ní Jos, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Plateau àti federal capital territory (FCT) tí a tún mọ sí Abuja.
Àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fi ẹhọnu hàn yìí sọ pé kí Vladimir Putin, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Russia dá sí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan Tinubu pé àwọn nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí wọ́n jẹ́ “ọga” rẹ̀ tí wọ́n sì í ń pàṣẹ fún un ló ń ṣe.
ÀSÍÁ WO LÓ WÀ NÍBI TÍ TINUBU WÀ?
Àwọn àwọ̀ mẹ́rin ló wà lára àsíá kejì yìí. Àwọn àwọ̀ yìí ni àwọ̀ pupa, búlúù, funfun àti àwọ̀ ewé. Àwọn àwọ̀ yìí jẹ́ àwọn àwọ̀ tí a máa ń lò gẹ́gẹ́bí àmì láti fi ṣe àfihàn ẹnì tí ó bá jẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà.
Àsíá tó ní àwọ̀ mẹ́rin yìí jẹ́ ti àwọn òṣìṣẹ́ ológun (armed forces). Lílò rẹ̀ túmọ̀ sí pé Tinubu ni Ààrẹ ati ẹni tí ó ní àṣẹ jùlọ ní Nàìjíríà.
Àsíá yìí kì í ṣe ti Russia. Àsíá Russia ní àwọ̀ mẹ́ta. Àwọn àwọ̀ mẹ́ta yìí jẹ́ àwọ̀ funfun, búlúù àti pupa.