Fídíò kan tí ó ní Peter Obi, olùdíje fún ipò Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nínú ẹgbẹ́ òsèlú Labour Party (LP) nígbà ìdìbò ọdún 2023, ti sàfihàn rẹ̀ nígbà tí ó ń polówó ibi ìdókòwò kan tí wọ́n ń pè ní “AfriQuantumX” ti di ohun tí àwọn ènìyàn ti ń pín kiri lórí ayélujára.
Nínú fídíò yìí, a rí Obi níbi tí ó ti ń sọ fún àwọn ènìyàn pé àwọn ènìyàn tí wọ́n dá ibi ìdókòwò yìí sílẹ̀ ní àtìlẹ́hìn òun àti ti ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà.
“Ó tó gẹ́! Àsìkò tó fún àwọn ènìyàn wa láti lówó lọ́wọ́. Ọmọ Nàìjíríà kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ mọ̀ èyí lónìí. O lè rí owó tí ó tó mílíọ̀nù méje náírà ní osù/osoosù,” báyìí ni ohùn ẹni kan tó ń sọ̀rọ̀ nínú fídíò yìí se wí.
“Àwọn ènìyàn tí wọ́n ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni wọ́n ti fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀, èyí kò ṣẹlẹ̀ nítorí pé wọ́n ya ọ̀lẹ, wọ́n fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀ nítorí pé wọ́n rí nǹkan gidi tó máa máa mú owó gidi wọlé fún wọn ni.”
“Wọ́n fẹ̀hìn tì kí ìgbà ìfẹ̀hìntì wọn tó tó, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbé ayé tó buyí kún ènìyàn. AfriQuantumX, ibi ìdókòwò tuntun kan tí èmi àti ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà se àtìlẹ́hìn fún ló jẹ́ kí eléyìí seése fún wọn,” báyìí ni fídíò yìí ní Obi se sọ.
Ibì kan tí ó ń jẹ́ “News24” ló fi fídíò yìí síta lórí ayélujára.
Àkòrí ọ̀rọ̀ yìí sọ pé: “AfriQuantumX-àǹfààní tí ènìyàn kò gbọ́dọ̀ pàdánù rẹ̀! Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún irínwó náírà, ní ọjọ́ méje, wàá ní mílíọ̀nù méjì náírà nínú ibi ìfowópamọ́ rẹ ní banki. Èyí kìí se ìlérí, ohun tó dájú tí àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ń se ni. Má fi àsìkò ṣòfò, ìforúkọsílẹ̀ yóò parí láìpẹ́-gbé ìgbésẹ̀ nísinsìnyí!”
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Wọ́n fi ohun àṣopọ̀ (link) sí inú ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà tí a gbé ọwọ́ lè ohun ìtọ́kasí/àṣopọ̀ yìí (click a link), ó gbé wa lọ sí ojú ibì kan/wẹbusaiti (website) kan tó jọ ti Channels Television, ilé isẹ́ amóhùnmáwòrán kan ní Nàìjíríà. Àmì ìdánǹkanmọ̀ (logo) tó wà lórí wẹbusaiti yìí kò gbé ènìyàn lọ sí ibi tí ènìyàn ti lè rí àwọn ọ̀rọ̀ kà (home page) nípa wẹbusaiti yìí.
Wẹbusaiti yìí ní fídíò Seun Ọkinbaloye, adarí eto òsèlú kan tí a mọ̀ sí ‘Politics Today’, ibi tí ó ti máa ń fi ọ̀rọ̀ wá ènìyàn lẹ́nu wò tí Channels Tv máa ń se, níbi tí wọ́n ti ń fi ọ̀rọ̀ wá Obi lẹ́nu wò.
Wọ́n se àyípadà sí fídíò yìí láti lè jẹ́ kí ó dàbí ẹni pé Ọkinbaloye àti Obi ń sọ̀rọ̀ nípa ibi ìdókòwò yìí.
Ohun mìíràn tí ó tún jẹ́ kí a mọ̀ pé irọ́ ni fídíò yìí ni pé ibi ẹnu Obi rí bálabàla-èyí tí ó jẹ́ kí a mọ̀ pé artificial intelligence (AI), ohun tẹkinọlọji (technology)/ẹ̀rọ ìgbàlódé ni wọ́n fi yí fídíò yìí padà kó lè dàbí òótọ́.
Àyẹ̀wò ibi ẹnu Obi tí a tún se fi hàn pé wọ́n gbé nǹkan kan lè nǹkan kan ni nínú fídíò yìí.
Nígbà tí Cablecheck ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan inú fídíò yìí lórí Google Lens, a ríi pé fídíò ọ̀rọ̀ yìí tó jẹ́ gidi jẹ́ ti ọ̀rọ̀ tí Obi sọ ní ibi eto kan tí wọ́n ń pè ní ‘The Platform Nigeria’, ní osù kàrún, ọdún 2017. Ìgbà méjì ni wọ́n máa ń se ètò yìí ní ọdún.
The Covenant Nation ni àwọn tí wọ́n máa ń se ètò yìí. Ètò yìí jẹ́ ibi tí àwọn olóye tí máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ Nàìjíríà, wọ́n sì tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà àbáyọ fún áwọn ìṣòro yìí.
O lè rí fídíò ọ̀rọ̀ yìí tó jẹ́ gidi wò níbí.
AI ni wọ́n fi se àwọn ijẹrisi (testimonials) tí wọ́n wà lórí wẹbusaiti yìí.
Nígbà tí a wá “AfriQuantumX” lórí Google, a ríi pé banki/ilé ìfowópamọ́ kan tí ó ń jẹ́ GCB Bank ní orílẹ̀ èdè Ghana ti fi ọ̀rọ̀ síta pé àwọn kò ní ohunkóhun se pẹ̀lú ibi ìdókòwò yìí.
Banki yìí sọ pé AfriQuantumX lo àmì ìdánǹkanmọ̀ (logo) tí GCB láti polówó ibi ìdókòwò yìí.
“GCB fẹ́ fi tó àwọn ènìyàn tí wọ́n ń bá banki wa se àti gbogbo àwọn ènìyàn létí pé jìbìtì ni ọ̀rọ̀ kan tí àwọn ènìyàn ti ń pín kiri lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise (social media) lórí ayélujára (internet) tó ń polówó ibi ìdókòwò kan tí ó ń jẹ́ “AfriQuantumX”, tí àwọn ènìyàn rò pé àwa ló fi síta,” báyìí ni ọ̀rọ̀ tí GCB fi síta nípa ọ̀rọ̀ yìí se sọ.
“Ọ̀rọ̀ yìí lo ohun ìdánǹkanmọ̀ GCB lọ́nà tí kò yẹ, ó sì tún lo fídíò tí kò ní ohunkóhun se pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n sìlò yìí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ naa, ọ̀rọ̀ yìí sì dárí àwọn ènìyàn sí wẹbusaiti tí kìí se ti GCB,” GCB ló sọ báyìí.
“GCB kò se ohun kankan tó ń jẹ́ AfriQuantumX. A gba àwọn ènìyàn ní àmọ̀ràn pé kí wọ́n má se tẹ tàbí gbé ọwọ́ lé ohun ìtọ́kasí (click the link) fún ọ̀rọ̀ yii, kí wọ́n máa pín àwọn ohun ìfowópamọ́ wọn (banking details) kankan pẹ̀lú ẹnikẹ́ni, kí wọ́n sì máa fi owó ránsẹ́ sí ẹnikẹ́ni lórí/fún ibi ìdókòwò yìí tàbí nípa ọ̀rọ̀ yìí,” báyìí ni ọ̀rọ̀ tí GCB fi síta se sọ.
Ìwà jìbìtì ni àwọn tó fi ọ̀rọ̀ nípa AfriQuantumX lò láti fi ọ̀rọ̀ yìí síta. Ìwà tó sì kọni lominu ni. Ènìyàn gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún irú nǹkan báyìí.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
AI ni wọ́n fi se fídíò kan tí ó sàfihàn Obi níbi tí ó ti ń polówó AfriQuantumX, ibi ìdókòwò kan. Àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí síta fẹ́ fi si àwọn ènìyàn lọ́nà ni.