Fídíò kan tí àwọn ènìyàn ń pín kiri ti sàfihàn ìgbà tí àwọn ènìyàn kan pa Musa Uba, ọ̀gá àwọn òṣìṣẹ́ ológun ní ìpínlẹ̀ Borno, ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Àwọn ènìyàn ní àwọn kan tí wọ́n ń pè ní Islamic State West Africa Province (ISWAP) ni wọ́n paá lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n sá pamọ́ tí wọ́n sì kọlu àwọn ọkọ̀ àwọn ọmọ ológun (soldiers) àti ti àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò kan tí wọ́n ń pè Civilian Joint Task Force (CJTF) ní Borno, ní ọjọ́ ẹtì kan.
Lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n kọlu wọn, àwọn ènìyàn sọ pé àwọn oníwà jàgídíjàgan (insurgents) kan mú Uba.
Onyechi Anele, agbẹnusọ fún àwọn òṣìṣẹ́ ológun sọ pé àwọn ènìyàn fi ọ̀rọ̀ yìí síta ní ọjọ́ abamẹta (Satide). Ó sọ pé ọ̀gá àwọn òṣìṣẹ́ ológun (brigadier general) yìí bá àwọn “oníwà jàgídíjàgan” yìí jà pẹ̀lú “agbára gidi”, èyí tí ó jẹ́ kí àwọn òníwa jàgídíjàgan yìí tuka, wọ́n sì sá lọ.
Àwọn ènìyàn ní Uba fi fídíò kan síta, ó sì sọ pé òhun wà láàyè, wọn kò pa òhun lára, apá òhun sì ká ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
ISWAP sọ pé irọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Anele sọ. Wọ́n ní àwọn gba ẹ̀mí ọ̀gá àwọn òṣìṣẹ́ ológun yìí lẹ́hìn ìgbà tí àwọn múu.
Ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, Bọlá Tinubu, ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sọ pé òótọ́ ni pé àwọn ènìyàn yìí pa Uba.
Lẹ́hìn ìgbà tí ISWAP sọ pé àwọn paá, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pín fídíò ọ̀rọ̀ yìí lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára (social media platforms), wọ́n sàfihàn fídíò yìí ní ìgbà díẹ̀ kí Uba tó kú.
Nínú fídíò yìí, a rí Uba níbi tí ó ti jókòó sílẹ̀ kí wọ́n tó yìnbọn fun lórí.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck, ti TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára rí àwọn ohun kan tí ó lè jẹ́ kí ènìyàn gbàgbọ́ pé fídíò yìí kìí se òótọ́, tí ó sì jẹ́ kí a mọ̀ pé artificial intelligence (AI) ni wọ́n fi se fídíò yìí.
Nínú fídíò yìí, wọ́n yín ìbọn. Àmọ́, Uba kò subú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Dípò kí ó subú, ó se díẹ̀ kò tó mára lọ silẹ, èyí tí kìí ṣẹlẹ̀ tí ènìyàn kan bá súnmọ́ ènìyàn láti yìnbọn fún ẹnì kan (close-range shooting).
“Wà ri pé ó ti ń subú kí ìbọn tó bàá,” báyìí ni Timothy Avele, ẹnì kan tó mọ̀ nípa ètò ààbò se sọ fún CableCheck.
CableCheck tún ríi pé kò sí àpá kankan tí ó sàfihàn pé wọ́n yin ìbọn fún ẹni yìí.
Lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n yin ìbọn, a ríi pé ẹ̀jẹ̀ kò fọ́nká, ara ẹni yìí kò mì, a kò sì rí ohunkóhun tó sàfihàn pé ìbọn bàá lórí. Ohun tí a rí kò sàfihàn pé wọ́n yin ìbọn fún ẹni yìí.
Ẹ̀jẹ̀ máa rọ́ jáde lára ẹni tí wọ́n bá yin ìbọn fún lórí. Kò sí àpá irú nnkan báyìí, ibi tí ẹni yìí wà sì mọ́, ẹ̀jẹ̀ kò jáde, kò sì sí àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ní àyíká ẹni yìí.
Àkíyèsí tí a tún se ni pé, fìlà tí Uba dé kò yẹ̀ kúrò lórí rẹ̀. Irú ìbọn tí wọ́n bá yín fún ènìyàn báyìí máa gbá fìlà dànù tàbí kí ó yẹ̀ẹ́ kúrò lórí.
CableCheck lo Deepfake Offensive Toolkit (DOT, a programmable deepfake offensive and detection software solution) láti ṣàyẹ̀wò fídíò yìí.
A ríi pé AI ni wọ́n fi se fídíò yìí.