Àwọn ènìyàn ti ń pín fídíò kan tí ó ṣe àfihàn afárá tí ó wó lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise lórí ayélujára, orí Facebook, èyí tí ó jẹ́ ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ.
Nínú fídíò ìgbà díẹ̀ yìí, afárá yìí wó bí àwọn ọkọ̀ se ń kọjá ní abẹ́ rẹ̀, àwọn tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ rìn sì sá fún ẹ̀mí wọ́n. Àwọn ọmọ Nàìjíríà kan lórí ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára (social media) fi fídíò yìí síta, wọ́n sì jẹ́ kí ó dàbí pé ó ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà.
Ẹnì kan tí ó ń lo Facebook tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí Goodluck Pyagbara tí àwọn tí wọ́n ń tẹ̀lée lórí Facebook lé ní ẹgbẹ̀rún méje fi fídíò yìí síta pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé: “Báyìí ni afárá tí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) fi biliọnu mẹwa náírà kọ se wó lulẹ̀.”
Eze Ferdinand, ẹnì kan tí òhun náà ń lo Facebook, fi fídíò náà síta pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé: Mo ṣàkíyèsí bí afárá yìí se wó, kí ló fà á?”

Ní ọjọ́rú, ẹni kan tí òhun náà ń lo Facebook tí a mọ̀ sí Abass Tom fi àwòrán fídíò yìí síta, ó sì sọ pé afárá yìí wà ní Lafia, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Nasarawa. Ẹni yìí sọ pé afárá yìí wó “ní ẹ̀hìn ọ̀sẹ̀ mẹta tí wọn sí í, àti wí pé “biliọnu mẹwa náírà” ni wọ́n nọ láti kọ ọ.

“Ìṣẹ̀lẹ̀ yajoyajo. Kére o. Afárá kan wó lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n sí í ní Lafia, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Nasarawa. Biliọnu mẹwa náírà ni wọn nọ lórí ẹ̀,” báyìí ni ẹni yìí se sọ lórí Facebook.
Lẹ́hìn wákàtí díẹ̀, ẹni yìí tún àkòrí yìí kọ, ó sì sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ní Bihar, ní orílẹ̀ èdè India.
“Afárá kan wó lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ mẹta tí wọn sí i ní Khagaria-Aguwani, ní Bihar. Àwòrán fi hàn pé apá kan afárá yìí wó (Ibi tí a ti rí ọ̀rọ̀ yìí: ìwé ìròyìn India Today). Biliọnu mẹwa ni wọ́n nọ láti kọ afárá yìí,”báyìí ni ẹni yìí se sọ.
Ẹni yìí tún tún àkòrí yìí kọ láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn rò pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà.
CableCheck rí bí ẹni yìí se se àwọn atunkọ nígbà tí a se àyẹ̀wò ibi ayélujára rẹ̀.

De Elegantz, ẹnì kan tí ó ní àwọn ènìyàn tí wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá tí wọ́n ń tẹ̀lée lórí Facebook fi àwòrán fídíò yìí síta, ó sì sọ pé Lafia, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Nasarawa ló ti ṣẹlẹ̀.

Ẹni kan tí ó ń jẹ́ @ManishCEO, tí ó ń lo X (tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀), ohun ìgbàlódé íbaraẹnise alámì krọọsi ní India fi fídíò yìí síta, ó ní pé ó ṣẹlẹ̀ ní Bihar, Ìpínlẹ̀ kan ní India.

Ẹlòmíràn tó ń lo X sọ pé Bihar ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Ní àkọ́kọ́, CableCheck se àkíyèsí pé àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní apá ọ̀tún afárá yìí ń sáré sí apá ibi tí afárá yìí ti ń wó dípò kí wọ́n sáré kúrò níbi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Àwọn ènìyàn kìí hùwà/se báyìí tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí bá ṣẹlẹ̀.
Ní èkejì, ọkọ̀ tí a ń pè ní SUV (Sport Utility Vehicle) ti o wà nínù fídíò yìí ń rìn sún mọ́ ibi afárá yìí, ara ibi ọ̀nà yìí tí SUV yìí ń sún mọ́ kò se àfihàn ohun tó wó.
Àwọn igi tí wọ́n wà ní ẹgbẹ́ ọ̀nà méjèèjì kò hàn dáadáa, àti wí pé nígbà tí ohun tí wọn fi gbé afárá yìí dúró wó ní apá ọ̀tún ọ̀nà yìí, ó dàbí pé kò sí igi kankan níbi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Àyẹ̀wò tí a tún se jẹ́ kí a rí ibi íbaraẹnise kan lórí Facebook tí àwọn ènìyàn ti sáábà máa ń pín fídíò tí wọ́n dá ọgbọ́n sí (Artificial Intelligence-AI videos). Ibi íbaraẹnise yìí fi fídíò ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tó ṣeé rí dáadáa síta ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù keje, ọdún 2025.
Ibi íbaraẹnise yìí sọ pé “AI ni wọ́n fi seAI fídíò yìí.”

BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
AI ni wọ́n fi se fídíò yìí. Kìí se òótọ́.