Fídíò kan tí ó ń ṣe àfihàn Thomas Partey, agbabọọlu ọmọ orílẹ̀ èdè Ghana, tí ó ti gbá bọọlu fún Arsenal tẹ́lẹ̀, sọ pé ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ kan tí wọ́n fi kàn án wáyé nípa ẹlẹyamẹya, tí di ohun tí àwọn ènìyàn ń pín kiri lórí ayélujára.
Nínú fídíò yìí, ohùn kan tí wọ́n gbé lórí àwòrán Partey, tí ó ń sọ̀rọ̀ ní abẹlẹ sọ pé ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ yìí wáyé nítorí pé kò fi ọwọ́ sí ìwé àdéhùn láti gbá bọọlu fún Arsenal.
“Mi o se nnkan yìí. Wọ́n fẹ́ fi ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ kó bá mi ni. Èyí máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹni tí ó bá jẹ́ aláwọ̀ dúdú tí ó sì kọ̀ láti fi ọwọ́ sí ìwé àdéhùn láti gbá bọọlu fún Arsenal,” báyìí ni ohùn kan ní abẹlẹ se sọ.
“Àmọ́, mo se tán láti kojú ohunkóhun. Ó tẹ mi lọ́rùn kí n lọ sí ẹ̀wọ̀n ju kí n gbá bọọlu fún Arsenal.”
Àwọn ènìyàn pín fídíò yìí lórí X, tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀, Facebook àti TikTok. CableCheck se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ti pín. Ẹni kan tí ó ń jẹ́ @sserona12 lórí TikTok ló fi èyí tí àwọn ènìyàn pín gan yìí síta.

Ẹni tí ó ń jẹ́ @sserona12 yìí ní àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún aadọjọ tí wọ́n ń tẹ̀lée lórí TikTok. Ó fi fídíò yìí síta ní ọjọ́ Satide pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé: “Wọ́n fi ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ kan Thomas Partey.” Àwọn ènìyàn mílíọ̀nù márùn-ún ló ti wo fídíò yìí.
Ó lè wo fídíò yìí níbí àti níbí.
Fídíò yìí jáde lórí ayélujára lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n fi ẹ̀sùn márùn-ún, lára èyí tí ó jẹ ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ àti ifiibalopọ lọ ènìyàn lọ́nà tí kò yẹ kan Partey ní orílẹ̀ èdè United Kingdom (UK).
Gẹ́gẹ́bí àwọn Metropolitan Police, àwọn ọlọ́pàá UK se wí, ìwà tí wọ́n ní kò bá òfin mu yìí wáyé láàárín ọdún 2021 àti 2022.
Wọn ní àwọn obìnrin mẹta ló fi ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ kan Partey.
Partey máa sọ bí ọ̀rọ̀ yìí se jẹ́ níwájú ilé ẹjọ́ ní Westminster Magistrates Court, ni ọjọ́ kàrún, oṣù kẹjọ, ọdún 2025.
Awuyewuye nípa àdéhùn fífi ọwọ sí ìwé lẹẹkan si láti gbá bọọlu fún Arsenal, èyí tí ó wà ní àríwá London, kò wáyé mọ́. Àdéhùn bọọlu gbígba fún Arsenal parí ní ọgbọ́n ọjọ́, oṣù kẹfà, ọdún 2025. Èyí túmọ̀ sí pé Partey ni òmìnira láti gbá bọọlu fún ẹgbẹ́ tó bá wùn ún.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck se àkíyèsí pé ibi ẹnu Partey nínú fídíò yìí kò hàn dáadáa, èyí tí ó túmọ̀ sí pé wọn dá ọgbọ́n sí fídíò yìí ni kí àwọn ènìyàn lè gbà pé òótọ́ ni.
Láti lè mọ ibi tí fídíò yìí gangan tí jáde, CableCheck se àyẹ̀wò rẹ̀ lórí Google Lens.
Àbájáde àyẹ̀wò yìí fi hàn pé ẹni kan fi fídíò yìí gangan síta lórí Instagram, ní orí ayélujára, ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹwàá, ọdún 2020, lẹ́hìn ìgbà díẹ̀ tí ó parí àdéhùn láti gbá bọọlu fún Arsenal pẹ̀lú owó tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún marundinlogoji mílíọ̀nù owó UK (£45,000) láti ẹgbẹ́ agbabọọlu Atletico Madrid, tí ó wà ní orílẹ̀ èdè Spain.
Nínú fídíò yìí gangan, Partey ń sọ fún àwọn tí wọ́n ń tẹ̀lée lẹ́hìn/tí wọ́n fẹ́ràn rẹ̀ pé òhun yóò fẹ́ràn láti dara pọ̀ mọ́ Arsenal gẹ́gẹ́bí agbabọọlu tuntun, nígbà tí ó ń mọ rírì fifẹ tí àwọn ènìyàn fẹ́ẹ.
Àwọn ilé isẹ ìròyìn kan tún gbé fídíò yìí jáde. Nígbà tí a tún se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí, a kò rí ọ̀rọ̀ kankan tí Partey sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí lórí ibi tí ó máa ń fi ọ̀rọ̀ sí lórí ayélujára.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Àwọn ènìyàn dá ọgbọ́n sí ọ̀rọ̀ tí wọn ní Partey sọ yìí ni lati lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn rò pé òótọ́ ni.