Charly Boy, gbajúgbajà ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ti sọ pé ọmọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Nnamdi Kanu, olórí Indigenous People of Biafra (IPOB), àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń jà fún òmìnira ní gúúsù oòrùn Nàìjíríà, se àṣeyọrí nínú idije kan tí wọ́n pè ní international world brain competition.
Charly Boy sọ ọ̀rọ̀ yìí nínú atẹsita kan lórí X, ohun ìgbàlódé alámì krọọsi, tí wọ́n ń pè ní Twitter tẹ́lẹ̀, ní ọjọ́rú.
“Ọmọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Nnamdi Kanu ti se ohun ìwúrí ní àgbáyé nípa dídi ẹni àkọ́kọ́ tó ṣàṣeyọrí nínú ìdíje ẹ̀kọ́ ìṣirò, èdè oyinbo àti èdè orílẹ̀ èdè Russia nínú ìdíje kan tí wọ́n pè ní international world brain competition”, báyìí ni atẹsita Charly Boy yìí se sọ.
“Ọmọ ọdún mọ́kànlá ọlọ́pọlọ pipe yìí fi ọwọ́ rọ́ àwọn olùdíje bii tirẹ ṣẹ́hìn ni orílẹ̀ èdè United Kingdom (UK) nípa ṣíṣe ipò kìíní nínú idanwo èdè òyìnbó. Ó tẹ̀ síwájú láti ṣàṣeyọrí ju gbogbo àwọn tí wọ́n jọ díje, ó sàfihàn pé ọlọ́pọlọ pípé ni ohun ní àgbáyé.
Àṣeyọrí yìí sàfihàn ọmọ yìí gẹ́gẹ́bí ìkan nínú àwọn ọmọ tí ọpọlọ wọn pé jù ní àgbáyé,” báyìí ni ọ̀rọ̀ tí Charly Boy fi síta yìí se wí.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ẹẹdẹgbẹrun àti mejilelaaadọta àti igba ló wo ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹrinlelogun ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹrin àti ẹẹdẹgbẹta ló ti pín ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀ta àti àádọ́rùn-ún ó dín ìkan ló ti fi ọ̀rọ̀ yìí pamọ́.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan àti irínwó tí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí sọ̀rọ̀ lorisirisi ọ̀nà. Àwọn ènìyàn kan tiraka láti wádìí ọ̀rọ̀ yìí lọ́wọ́ Grok, ohun kan tí ó máa ń se iranlọwọ fún X láti fi òye yé àwọn ènìyàn, àwọn ènìyàn mìíràn sì sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí dára gan-an ni.
Atẹsita Charly Boy yìí kùnà láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan kan.
Charly Boy kò sọ ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀, kò sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan pàtó. Fún àpẹẹrẹ, kò sọ àkọlé ìdíje yìí, tàbí orúkọ ẹni tí ó ṣàṣeyọrí yìí.
ÀBÁJÁDE ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Ní ọjọ́ kẹrìnlá sí ọjọ́ kẹtàdínlógún, osù kẹfà, ọdún 2025, ìdíje kan tí a mọ̀ sí British Neuroscience Olympiad (BNO) wáyé lórí ayélujára ni osù kẹjọ, ọdún 2025, ní London.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè kópa nínú ìdíje yìí. Ìdíje yìí fẹ́ jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́mọdé mú ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ sayẹnsi ní ọ̀kúnkúndùn tàbí kí wọ́n tẹra mọ.
Àwọn olùdíje yóò dáhùn ìbéèrè nípa ìmọ̀ sayẹnsi.
Mehul Rathi ni wọ́n dárúkọ gẹ́gẹ́bí ẹni tí ó se ipò kìíní, Pouria Karimi ló se ipò kejì, Hannah Weissmann ló se ipò kẹta.
Ìdíje mìíràn tí wọ́n pè ní “Brain Up International Championship 2025” tún wáyé ní UK, eleyi sì fẹ́ mọ bí ìmọ̀ ìṣirò àwọn adije se tó.
Wọ́n kò dárúkọ àwọn ènìyàn ti wọ́n ṣàṣeyọrí nínú ìdíje yìí. Àmọ́, wọ́n dárúkọ ẹnì kan tó ń jẹ́ Mayra Shaik gẹ́gẹ́bí ẹni tí ó ṣàṣeyọrí jù nínú ọ̀rọ̀ kan tí ẹnì kan fi síta lórí Instagram, ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán tàbí fídíò síta.
International Brain Bee, ìdíje mìíràn, tún wáyé. Àmọ́, orí ayélujára ni wọ́n ti ṣe ètò yìí ni orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.
Ohun tí ó sún mọ́ “world brain competition” ní UK ni ètò BNO.
CableCheck, ti TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára, se àyẹ̀wò tí àwọn elédè òyìnbó ń pè ní Google reverse image search fún àwòrán (fọ́tò) ọmọ yìí tí Charly Boy pè ní ọmọ Nnamdi Kanu. Ohun tí a rí kò bá fọ́tò yìí mu.
Fọ́tò tí a rí jẹ́ ti Alejandro Cooper, ọ̀dọ́mọdé ọkùnrin òsèré ọmọ orílẹ̀ èdè Namibia kan, tí ó ṣàṣeyọrí nínú ètò kan tí wọ́n sì fi ‘ọ̀dọ́mọdé òsèré tó mọ eré se jùlọ ní Afíríkà’ dáa lọ́lá ní orílẹ̀ èdè Burkina Faso.
Cooper, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá gba àmì ẹ̀yẹ yìí fún ipa tí ó kó nínú fíìmù (film/movie) kan tí wọ́n pè ní ‘Lukas’, tí Philippe Talavera darí rẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé isẹ́ ìròyìn ní Namibia ni wọ́n gbé ìròyìn nípa ìdánilọ́lá yìí.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Àwòrán/fọ́tò inú ọ̀rọ̀ tí Charly Boy fi síta yìí kìí se ti ọmọ Nnamdi Kanu. Kò sì tún yé wa “ìdíje ọpọlọ” tí Charly Boy ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣàṣeyọrí nínú àwọn ìdíje pàtàkì tí wọ́n se ní UK ní ọdún 2025 kò tan mọ́ Kanu.