Ọ̀rọ̀ kan tí àwọn ènìyàn ti ń pín kiri lórí ayélujára sọ pé wọ́n ti dá ẹjọ́ ikú fún Okezie Ikpeazu, gómìnà ìpínlẹ̀ Abia tẹ́lẹ̀ nítorí pé wọ́n ní ó kó triliọnu kan náírà owó ijoba sí àpò ara rẹ̀.
Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ yìí se sọ, àwọn oniwadi tọ̀nà owó yìí lọ sí ilé ifowopamọ (banki) Ikpeazu ní orílẹ̀ èdè Australia. Àwọn oniwadi yìí sọ pé owó yìí jẹ́ owó tí ìjọba ìpínlẹ̀ Abia yà sọ́tọ̀ láti kọ́ ibi ọkọ̀ òfuurufú (Abia International Airport) àti ibi ọkọ̀ ojú irin (light rail project).
Ọ̀rọ̀ yìí tún sọ pé ẹni kan tó ń jẹ́ “Adájọ́ Chukwuemeka Nwogu” ni ó dá ẹjọ́ yìí, wọ́n ní ó sì sọ pé ẹ̀rí tó tako Ikpeazu “pọ̀ gan-an” àti wí pé “ìyá tó lágbára jù” ló tọ́ fún “irú ìwà aibikita yìí.”
Ọ̀rọ̀ yìí tún sọ pé ìjọba ń sọ́ gomina tẹ́lẹ̀ náà àti wí pé akitiyan ń lọ lọ́wọ́ lati gba owó yìí padà.
Àwọn ènìyàn tí pín ọ̀rọ̀ yìí lórí X, ohun ìgbàlódé alámì krọọsi tí wọ́n ń pè ní Twitter tẹ́lẹ̀ àti Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ orí ayélujára gẹ́gẹ́bí a tíì ríi níbí, níbí àti níbí.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck, ti TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣàyẹ̀wò apá kejidinlọgọrun ìwé òfin fún àṣemáṣe ni Nàìjíríà. A ríi pé ìwé yìí sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí wọ́n bá jí owó ìjọba tàbí hu ìwà jẹgudujẹra yóò se ẹ̀wọ̀n. Kò sí àgbékalẹ̀ tó sọ pé wọ́n yóò dá ẹjọ́ ikú fún ẹni tí ó bá se nnkan báyìí nínú ìwé òfin Nàìjíríà.
Nígbà tí a se àyẹ̀wò wẹbusaiti ẹ̀ka ìdájọ́ ti ìpínlẹ̀ Abia, a kò rí orúkọ kankan tí ó ń jẹ́ adájọ́ Chukwuemeka Nwogu.
Ní àfikún, kò sí ilé isẹ́ ìròyìn tó seé gbàgbọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ ikú fún Ikpeazu. Tí a bá wo ipò Ikpeazu gẹ́gẹ́bí gómìnà tẹ́lẹ̀, àwọn ilé isẹ́ ìròyìn ní Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn yóò ti sọ̀rọ̀ nípa irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
CableCheck kàn sí John Kalu, kọmisọnna (commissioner) tẹ́lẹ̀ fún ọ̀rọ̀ ajé/òwò ní Abia. Ó sọ pé irọ́ gbáà ni ọ̀rọ̀ yìí. Ó sọ pé Ikpeazu kò se ohun kankan tó lòdì sófin ní ibikíbi ní àgbáyé.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Irọ́ ni ọ̀rọ̀ tó sọ pé wọ́n ti dá ẹjọ́ ikú fún Okezie Ikpeazu nítorí pé ó kó triliọnu kan náírà owó ìjọba sápò ara rẹ̀. Kò sí adájọ́ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Chukwuemeka Nwogu, kò sì sí òfin Nàìjíríà kankan tó se àgbékalẹ̀ ẹjọ́ ikú fún ìwà jẹgudujẹra.