Ẹnì kan tí ó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ orí ayélujára tí sọ pé orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti kọlu Burkina Faso pẹ̀lú ohun ìjà olóró, èyí tí ó jẹ́ kí Ibrahim Traore, olórí àwọn òṣìṣẹ́ ológun tí ó tún jẹ́ olórí orílẹ̀ èdè náà dojú ìjà kọ Amẹ́ríkà padà.
Edwuadotv, ẹnì kan tí ó ń lo Facebook, ló fi ọ̀rọ̀ yìí sórí ayélujára ní ọjọ́ kejilelogun, oṣù kẹjọ, ọdún 2025.
“Nígbà tí ohun ìjà olóró Amẹ́ríkà kọlu ibùdó àwọn ọmọ ológun ní àríwá Burkina Faso, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn rò pé Burkina Faso ma gba kámú, èyí tí ó túmọ̀ sí pé wọn kò ní dojú ìjà kọ Amẹ́ríkà padà. Àmọ́, Ibrahim Traore kò sojo, ó jẹ́wọ́ fún Amẹ́ríkà pé akíkanjú olórí ni òhun nípa sísọ pé àkọlù Amẹ́ríkà yìí kò yẹ kó ṣẹlẹ̀ ní Áfíríkà,” báyìí ni ọ̀rọ̀ orí Facebook yìí se sọ.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n ló ti wo fídíò ìṣẹ́jú mẹẹdogun yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan àti ọọdunrun ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn irínwó àti mẹsan ló ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí.
Gẹ́gẹ́bí ẹnì kan tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú fídíò yìí se wí, Amẹ́ríkà pàṣẹ pé kí ibùdó ológun wọn (American military base) ní orílẹ̀ èdè Niger kọlu Burkina Faso pẹ̀lú ohun ìjà olóró láti dojú ìjà kọ ìwà ìjániláyà “(counterterrorism operation).”
“Àdò olóró méjì tí wọ́n ṣètò rẹ̀ kọlu ibi ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ní ìgbèríko kan. Ibì kan tí nkan ti bú gbàmù ba gbogbo ibi ilé ìsọ́ tí wọ́n ti ń se afihan bí ibi ìbáraẹnisọ̀rọ̀ (signal tower) wọn se lágbára tó jẹ́, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì jẹ́ kí ibi ìbáraẹnisọ̀rọ̀ yìí gbaná, ó sì pa ènìyàn mẹ́ta. Àwọn ènìyàn méjì nínú àwọn ènìyàn tí wọ́n kú jẹ́ òṣìṣẹ́ ológun (soldiers), ẹnì kan sì jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ (civilian technician). Àwọn ènìyàn méje yòókù fara pa,” báyìí ni ẹni yìí se sọ.
Ẹni yìí fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé “Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti tàn káàkiri Afíríkà.”
Ọ̀rọ̀ yìí tún jáde lórí ibi kan tí a mọ̀ sí Bright Africa lórí YouTube, ibì kan lórí ayélujára tí áwọn ènìyàn máa ń fi àwòrán/fídíò sí kí àwọn ènìyàn lè wòó. Bright Africa ní àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ẹẹdẹgbẹta tí wọ́n máa ń wo fídíò wọn níbẹ̀.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún àti ọọdunrun lé ní mọkandinlọgọta ni wọ́n ti wo fídíò yìí láti ìgbà tí Bright Africa ti fi sórí ayélujára, ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kẹjọ, ọdún 2025.
O lè wo àwọn fídíò tí àwọn ènìyàn ti fi síta lórí ọ̀rọ̀ yìí lórí YouTube níbí, níbí àti níbí.
Ǹjẹ́ òótọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn fi síta lórí fídíò yìí?
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck, tí TheCable Newspaper, se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí nípa wíwòó bóyá Amẹ́ríkà kọlu Burkina Faso pẹ̀lú ohun ìjà olóró. A kò rí àbájáde tàbí èsì tó jẹ́ òótọ́.
Biotilẹjẹpe ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú fídíò yìí kò sọ pàtó ọjọ́ tí Amẹ́ríkà kọlu Burkina Faso pẹ̀lú ohun ìjà olóró, CableCheck tun se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí, a sì wo irú àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí wọ́n ṣẹlẹ̀ láàárín ọjọ́ kìíní sí ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, oṣù kẹjọ, ọdún 2025, a kò sì lo àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lè si àwọn ènìyàn lọ́nà kí a báa lè rí èsì tó seé gbára lé.
Àyẹ̀wò wa kò gbé esi tó seé gbàgbọ́ jáde nípa ọ̀rọ̀ yìí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ló máa ti gbé irú ìròyìn yìí jáde tó bá ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Amẹ́ríkà kọlu orílẹ̀ èdè Iran pẹ̀lú àwọn ohun ìjà olóró, gbogbo àgbáyé ló mọ̀.
Ní àfikún, ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú fídíò yìí, èyí tí ohùn ẹ jọ ohùn tí wọ́n fi artificial intelligence (AI) se, sọ pé kíkọlù tí Amẹ́ríkà kọlu Burkina Faso yìí wá láti ibi tí àwọn ọmọ òṣìṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà máa ń wà ní orílẹ̀ èdè Niger (American military base in Niger).
Amẹ́ríkà kò ní ibi tí àwọn òṣìṣẹ́ ológun rẹ̀ wà ní Niger mọ́. Ní oṣù kẹsàn-án, àwọn elétò ààbò fún Amẹ́ríkà (US Department of Defense) kó àwọn òṣìṣẹ́ ológun rẹ̀ kúrò ní Niger, èyí tí ó wà ní Sahel, èyí tí ó túmọ̀ sí pé àjọṣe tó wà láàárín Amẹ́ríkà àti àwọn ọmọ ológun Niger ti dópin.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Kò sí ọ̀rọ̀ tó seé gbàgbọ́ nípa ọ̀rọ̀ tí ẹni yìí sọ pé Amẹ́ríkà kọlu Burkina Faso pẹ̀lú ohun ìjà olóró.