Ọ̀rọ̀ kan lórí ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára sọ pé Francis Nwifuru, gómìnà Ìpínlẹ̀ Ebonyi dá àwọn kọmisọnna marundinlọgbọn àti àwọn mìíràn tó yàn sípò dúró lẹ́nu iṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ nítorí pé wọ́n kò wá sí ibi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọmọ ọkùnrin gómìnà.
Ọ̀rọ̀ yìí, èyí tí IgboHistory&Facts fi síta lórí ohun ìgbàlódé íbaraẹnise alámì krọọsi (X), tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀, ti ní àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹtadinlọgọfa tí wọ́n ti ríi. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan àti ọọdunrun ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rin ó dín mẹ́tàlá ló pín in, àwọn ènìyàn marunlelẹẹdẹgbẹta ló sọ̀rọ̀ nípa ẹ.
Ọ̀rọ̀ yìí ní àwòrán Nwifuru pẹ̀lú ìyàwó àti ọmọ rẹ̀. Àwọn ènìyàn mìíràn tí wọ́n ń lo ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára (social media) fi ọ̀rọ̀ yìí sórí ayélujára níbí, níbí, àti níbí.
Ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, Nwifuru dá àwọn kọmisọnna marundinlọgbọn, àwọn olùrànlọ́wọ́ àgbà mẹ́rìnlá fún gómìnà yìí, àwọn olùrànlọ́wọ́ mẹ́rìnlélógún fun gómìnà yìí tí wọ́n kéré sí àwọn olùrànlọ́wọ́ àgbà àti àwọn ọ̀gá pátápátá ní àwọn ẹ̀ka isẹ ìjọba (permanent secretaries) dúró fún ìgbà díẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ nítorí pé wọn kò wá sí ibi ayẹyẹ pàtàkì kan ti ìjọba Ebonyi se.
Gómìnà yìí sọ pé àwọn tí òhun dá dúró yìí kò gbọ́dọ̀ wá sí ibi iṣẹ́ fún oṣù kan, wọn kò sì ní gba owó oṣù fún oṣù kan yìí àti wí pé wọn kò gbọ́dọ̀ bu ọwọ́ lu ìwé iṣẹ́ ìjọba kankan nígbà tí wọ́n kò nìí fi wá sí ibi iṣẹ́.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck se àyẹ̀wò ibi íbaraẹnise orí Facebook tí ó jẹ́ ti gómìnà yìí, a sì ríi pé fọto (àwòrán) tí wọ́n lò fún ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ èyí tí wọ́n lò nígbà ayẹyẹ ìdúpẹ́ ọjọ́ ìbí ọmọ gomina yìí tó jẹ́ obìnrin tó wáyé ní ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹtadinlọgbọn, oṣù keje, ọdún 2025, ọjọ́ méjì kí Ìpínlẹ̀ Ebonyi tó kéde ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́ yìí.
CableCheck tún kàn sí Monday Uzor, ọ̀gá àwọn onísẹ́ ìròyìn (chief press secretary) fún gómìnà Ebonyi yìí. Uzor ní ọ̀rọ̀ yìí kìí se òótọ́.
Uzor sọ pé ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́ yìí jẹ́ ohun tí gómìnà náà se láti dá sẹ̀ríyà fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba yìí nítorí pé wọ́n kùnà láti wá sí ibi ìdíje kan (basic school sports competition), tí Universal Basic Education Board sètò ẹ ní Ìpínlẹ̀ náà.
Uzor sọ pé Nwifuru sọ fún Patricia Obila, igbá-kejì gómìnà, kó ṣojú òhun níbi ìdíje yìí, gómìnà yìí sì sọ pé kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba mìíràn lọ síbẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn kò lọ.
“Gómìnà lọ sí ibì kan, ó sì sọ pé kí igbá-kejì òhun lọ ṣojú òhun níbi ìparí ìdíje tí wọ́n pè ní basic school sports competition, tí Universal Basic Education Board (UBEC) ṣètò ẹ. Àmọ́sá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn kọmisọnna àti àwọn mìíràn tí gómìnà yàn sípò kò lọ sí ibi ayẹyẹ yìí,” báyìí ni Uzor se sọ fún CableCheck.
“Nígbà tí gómìnà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó gbé ìgbésẹ̀ nítorí pé kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí irú nkan báyìí ṣẹlẹ̀ rèé.” “Oníkatikati ni àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ̀rọ̀ yìí. Wọ́n mọ ọ̀rọ̀ tó jẹ́ òótọ́.”
“Àwòrán ọ̀rọ̀ yìí kò ní ohunkóhun se pẹ̀lú ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Wọ́n ya àwòrán yìí níbi ayẹyẹ kan tí gómìnà lọ ní oṣù keje, ọdún 2025,” Uzor lo sọ báyìí.
CableCheck tún se àyẹ̀wò ibi íbaraẹnise ti Obila lórí Facebook. A ríi pé ètò tí àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa ẹ yìí wáyé ní ọjọ́ ẹtì, ọjọ́ karundinlọgbọn, oṣù keje, ọdún 2025, ọjọ́ méjì kí ọmọ Nwifuru obìnrin tó se ọjọ́ ìbí rẹ̀.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan sọ pé Nwifuru dá àwọn kọmisọnna àti àwọn ènìyàn mìíràn tó yàn sípò dúró lẹ́nu iṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ nítorí pé wọ́n kò wá sí ibi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọmọ rẹ̀ obìnrin kìí se òótọ́.