TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: AI ni fídíò tí ó fi ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ kan Thomas Partey
Share
Latest News
FACT CHECK: Viral image depicting ‘Obasanjo prostrating for Ladoja’ photoshopped
Wike tụ̀rụ̀ àsị́. Peter Obi mèrè ńtụ̀líáká ọ̀chị́chị́ ḿpághárá m̀gbè ọ́ bụ̀ gọ́vánọ̀ Anambra
Irọ́ ni Wike pa. Peter Obi ṣètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra
Wike yayi kuskure. Peter Obi ya gudanar da zaben LG a matsayin gwamnan Anambra
Wike make mistake. Peter Obi conduct LG election as Anambra governor
Video wey show as Thomas Partey dey blame ‘rape’ case on racism na fake
Bidiyon da ke nuna Partey yana zargin shari’ar ‘fyade’ akan wariyar launin fata da aka gyara ta hanyar lambobi
Íhé ńgósị́ ébé Thomas Partey tàrà ị́kpa óké àgbụ̀rụ̀ ụ́tá maka íkpé àkwàmìkó n’íké bụ̀ áká ọ́rụ AI
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

AI ni fídíò tí ó fi ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ kan Thomas Partey

Yemi Michael
By Yemi Michael Published July 11, 2025 5 Min Read
Share

Fídíò kan tí ó ń ṣe àfihàn Thomas Partey, agbabọọlu ọmọ orílẹ̀ èdè Ghana, tí ó ti gbá bọọlu fún Arsenal tẹ́lẹ̀, sọ pé ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ kan tí wọ́n fi kàn án wáyé nípa ẹlẹyamẹya, tí di ohun tí àwọn ènìyàn ń pín kiri lórí ayélujára. 

Nínú fídíò yìí, ohùn kan tí wọ́n gbé lórí àwòrán Partey, tí ó ń sọ̀rọ̀ ní abẹlẹ sọ pé ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ yìí wáyé nítorí pé kò fi ọwọ́ sí ìwé àdéhùn láti gbá bọọlu fún Arsenal.

“Mi o se nnkan yìí. Wọ́n fẹ́ fi ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ kó bá mi ni. Èyí máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹni tí ó bá jẹ́ aláwọ̀ dúdú tí ó sì kọ̀ láti fi ọwọ́ sí ìwé àdéhùn láti gbá bọọlu fún Arsenal,” báyìí ni ohùn kan ní abẹlẹ se sọ.

“Àmọ́, mo se tán láti kojú ohunkóhun. Ó tẹ mi lọ́rùn kí n lọ sí ẹ̀wọ̀n ju kí n gbá bọọlu fún Arsenal.”

Àwọn ènìyàn pín fídíò yìí lórí X, tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀, Facebook àti TikTok. CableCheck se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ti pín. Ẹni kan tí ó ń jẹ́ @sserona12 lórí TikTok ló fi èyí tí àwọn ènìyàn pín gan yìí síta.

A screenshot of the video on TikTok

Ẹni tí ó ń jẹ́ @sserona12 yìí ní àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún aadọjọ tí wọ́n ń tẹ̀lée lórí TikTok. Ó fi fídíò yìí síta ní ọjọ́ Satide pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé: “Wọ́n fi ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ kan Thomas Partey.” Àwọn ènìyàn mílíọ̀nù márùn-ún ló ti wo fídíò yìí.

Ó lè wo fídíò yìí níbí àti níbí.

Fídíò yìí jáde lórí ayélujára lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n fi ẹ̀sùn márùn-ún, lára èyí tí ó jẹ ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ àti ifiibalopọ lọ ènìyàn lọ́nà tí kò yẹ kan Partey ní orílẹ̀ èdè United Kingdom (UK).

Gẹ́gẹ́bí àwọn Metropolitan Police, àwọn ọlọ́pàá UK se wí, ìwà tí wọ́n ní kò bá òfin mu yìí wáyé láàárín ọdún 2021 àti 2022.

Wọn ní àwọn obìnrin mẹta ló fi ẹ̀sùn ìbánifipálòpọ̀ kan Partey.

Partey máa sọ bí ọ̀rọ̀ yìí se jẹ́ níwájú ilé ẹjọ́ ní Westminster Magistrates Court, ni ọjọ́ kàrún, oṣù kẹjọ, ọdún 2025.

Awuyewuye nípa àdéhùn fífi ọwọ sí ìwé  lẹẹkan si láti gbá bọọlu fún Arsenal, èyí tí ó wà ní àríwá London, kò wáyé mọ́. Àdéhùn bọọlu gbígba fún Arsenal parí ní ọgbọ́n ọjọ́, oṣù kẹfà, ọdún 2025. Èyí túmọ̀ sí pé Partey ni òmìnira láti gbá bọọlu fún ẹgbẹ́ tó bá wùn ún.

ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ

CableCheck se àkíyèsí pé ibi ẹnu Partey nínú fídíò yìí kò hàn dáadáa, èyí tí ó túmọ̀ sí pé wọn dá ọgbọ́n sí fídíò yìí ni kí àwọn ènìyàn lè gbà pé òótọ́ ni.

Láti lè mọ ibi tí fídíò yìí gangan tí jáde, CableCheck se àyẹ̀wò rẹ̀ lórí Google Lens.

Àbájáde àyẹ̀wò yìí fi hàn pé ẹni kan fi  fídíò yìí gangan síta lórí Instagram, ní orí ayélujára, ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹwàá, ọdún 2020, lẹ́hìn ìgbà díẹ̀ tí ó parí àdéhùn láti gbá bọọlu fún Arsenal pẹ̀lú owó tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún marundinlogoji mílíọ̀nù owó UK (£45,000) láti ẹgbẹ́ agbabọọlu Atletico Madrid, tí ó wà ní orílẹ̀ èdè Spain.

Nínú fídíò yìí gangan, Partey ń sọ fún àwọn tí wọ́n ń tẹ̀lée lẹ́hìn/tí wọ́n fẹ́ràn rẹ̀ pé òhun yóò fẹ́ràn láti dara pọ̀ mọ́ Arsenal gẹ́gẹ́bí agbabọọlu tuntun, nígbà tí ó ń mọ rírì fifẹ tí àwọn ènìyàn fẹ́ẹ.

Àwọn ilé isẹ ìròyìn kan tún gbé fídíò yìí jáde. Nígbà tí a tún se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí, a kò rí ọ̀rọ̀ kankan tí Partey sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí lórí ibi tí ó máa ń fi ọ̀rọ̀ sí lórí ayélujára.

BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ

Àwọn ènìyàn dá ọgbọ́n sí ọ̀rọ̀ tí wọn ní Partey sọ yìí ni lati lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn rò pé òótọ́ ni.

TAGGED: factcheck, Factcheck in Yorùbá, News in Yorùbá, Rape Case, Thomas Partey

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael July 11, 2025 July 11, 2025
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print

POPULAR POSTS

Advertisement

FACT CHECK: Viral image depicting ‘Obasanjo prostrating for Ladoja’ photoshopped

An image showing a person prostrating for Rashidi Ladoja, the Olubadan-in-waiting and former governor of…

July 11, 2025

Wike tụ̀rụ̀ àsị́. Peter Obi mèrè ńtụ̀líáká ọ̀chị́chị́ ḿpághárá m̀gbè ọ́ bụ̀ gọ́vánọ̀ Anambra

Nyesom Wike, onye minista nke isi obodo Naijiria bụ FCT, kwuru na Peter Obi, onye…

July 11, 2025

Irọ́ ni Wike pa. Peter Obi ṣètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra

Nyesom Wike, minisita fún Federal Capital Territory (FCT), Abuja, olú ìlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, sọ…

July 11, 2025

Wike yayi kuskure. Peter Obi ya gudanar da zaben LG a matsayin gwamnan Anambra

Nyesom Wike, ministan babban birnin tarayya Abuja, ya ce Peter Obi, tsohon gwamnan Anambra kuma…

July 11, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Wike tụ̀rụ̀ àsị́. Peter Obi mèrè ńtụ̀líáká ọ̀chị́chị́ ḿpághárá m̀gbè ọ́ bụ̀ gọ́vánọ̀ Anambra

Nyesom Wike, onye minista nke isi obodo Naijiria bụ FCT, kwuru na Peter Obi, onye bụ buru gọvanọ Anambra steetị…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 11, 2025

Irọ́ ni Wike pa. Peter Obi ṣètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra

Nyesom Wike, minisita fún Federal Capital Territory (FCT), Abuja, olú ìlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, sọ pé Peter Obi, ẹni tí…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 11, 2025

Wike yayi kuskure. Peter Obi ya gudanar da zaben LG a matsayin gwamnan Anambra

Nyesom Wike, ministan babban birnin tarayya Abuja, ya ce Peter Obi, tsohon gwamnan Anambra kuma dan takarar shugaban kasa na…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 11, 2025

Wike make mistake. Peter Obi conduct LG election as Anambra governor

Nyesom Wike, minister of di Federal Capital Territory (FCT), tok sey Peter Obi, forma govnor of Anambra and 2023 Labour…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 11, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?