TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Rárá, Nàìjíríà kò fi àwọn ọmọ iṣẹ́ ológun rán sẹ sí Ísírẹ́lì láti dá rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ dúró
Share
Latest News
Ḿbà, Naijiria ézipụ̀ghị̀ ńdị́ ágha ńkwàdó ùdó nà òbòdò Isreal
No, Nigeria no send peace support mission go Israel
A’a, Najeriya ba ta tura tawagar taimakon zaman lafiya zuwa Isra’ila ba
Ǹjẹ́ Tinubu àti Alexander Zingman lọ sí ilé-ìwé kan náà? Èyí ni ohun tí a mọ̀
Tinubu nà Alexander Zingman ọ̀ gàrà ótù ụ́lọ̀ákwụ́kwọ́? Lèé íhé ányị́ mà
Tinubu go di same school wit Alexander Zingman? Na wetin we sabi be dis
Shin Tinubu ya halarci makaranta daya da Alexander Zingman? Ga abin da muka sani
Did Tinubu attend same school as Alexander Zingman? Here is what we know
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Rárá, Nàìjíríà kò fi àwọn ọmọ iṣẹ́ ológun rán sẹ sí Ísírẹ́lì láti dá rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ dúró

Yemi Michael
By Yemi Michael Published June 28, 2025 4 Min Read
Share

Ìròyìn lati inú fídíò Facebook kan sọ pé Nàìjíríà fi àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ sí orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì kí rògbòdìyàn lè lọ sílẹ̀ níbẹ̀.

Fídíò kan tí àwọn ènìyàn ń pín kiri lórí Facebook, ohun ìgbàlódé Ibaraẹnisọrẹ orí ayélujára, sọ pé Nàìjíríà ti fi àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ sí Ísírẹ́lì (Israel) láti da wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ dúró.

Ọkùnrin agbóhùnsáfẹ́fẹ́ kan tó ń ròyìn fún ibùdó kan tí wọ́n pè ní TBC News ló sọ bẹ́ẹ̀ nínú fídíò kan tí ó dín díẹ̀ ní ìṣẹ́jú kan.

Ohùn kan tó fihàn pé ọmọ ogun kan ń sọ̀rọ̀ sọ pé: “Nàìjíríà dúpẹ́ lọ́wọ́ pípàṣẹ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ààbò ìlú sí àwọn alájọṣepọ̀ tó ṣe pàtàkì lágbàáyé.”

“Èyí jẹ́ ìrìn àjò ọ̀rẹ́ kii ṣe ogun.

“Àwọn ọmọ ogun náà yóò kópa nínú ètò ìṣọ̀kan tí wọ́n ṣe láti mú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àgbáyé àti ìṣọ̀kan láàárín àwọn orílẹ̀-èdè gbòòrò.”

Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà sọ pé àwọn olùṣọ́ àgbáyé yìn ètò yìí, wọ́n sì pè é ní àmì ìdarí Áfíríkà nínú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ààbò àgbáyé.

Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà fi ọ̀rọ̀ náà síta ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kẹfà, ọdún 2025.

Ní àkókò ìròyìn yìí, fídíò náà ti ní àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹta àti igba tí wọ́n fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹẹdẹgbẹta àti mẹ́fà ló pín in, àwọn ènìyàn irínwó àti àádọ́rin ó dín marun-un ló sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí.

Fídíò náà jáde ní àkókò kan tí ìjà láàárín Ísírẹ́lì àti orílẹ̀ èdè Iran ti gbòòrò, tí ogun náà sì ti wọ ọ̀sẹ̀ kejì.

Àwọn orílẹ̀-èdè, títí kan Nàìjíríà, àti àwọn adarí àgbáyé ti fi ìbẹ̀rù hàn, wọ́n sì rọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè yìí láti dá ọwọ rògbòdìyàn yìí dúró.

Ṣùgbọ́n, ṣé Nàìjíríà dá sí ọ̀rọ̀ náà nípa rírán àwọn ọmọ ogun sí Ísírẹ́lì láti dá rògbòdìyàn yìí dúró?

AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ

CableCheck ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ yìí nípa ṣíṣe àyẹ̀wò àwọn kókó ọ̀rọ̀ inú ọ̀rọ̀ yìí, a kò sì rí ìròyìn kankan tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀.

Àwọn aláṣẹ fún eto ìjọba àpapọ̀ (the Presidency), àwọn elétò ààbò (Defense Headquarters-DHQ and Ministry of Defense) kò fi ọ̀rọ kankan síta nípa ọ̀rọ̀ yìí.

CableCheck kan sí Edward Buba, agbẹnusọ fun DHQ, fún ìdánilójú, ṣùgbọ́n Buba kò dáhùn.

Kò sí àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé kankan tó gbé ìròyìn nípa ọ̀rọ̀ náà.

CableCheck tún ṣàkíyèsí àwọn àṣìṣe, tó jọ àwọn tí ìmọ̀-ẹ̀rọ atọ́wọ́dá (Artificial Intelligence-AI) ń fa, nínú ìfarahàn agbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà.

Ní ìgbà díẹ̀ àkọ́kọ́ ti fídíò náà bẹ̀rẹ̀, a rí agbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà tí ó wọ aṣọ búlúù, ẹni yìí sì pá lórí. A rí ẹni yiii nínú aṣọ búlúù dúdú, ààlà pupa, ó sì ní irun púpọ̀.

Ẹni yìí ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn tó yára, kò sì sọ̀rọ̀ gbe ẹni kan, ó sì ń pe ọ̀rọ̀ bíi ẹ̀rọ agbelẹrọ tí ó dàbí ti robọti (robot), gbogbo ọ̀rọ̀ yìí jọ ohun tí AI yí padà.

Ní ogunjọ, oṣù kẹfà, ọdún 2025, àwọn elétò ààbò ní Nàìjíríà, fi àwọn ọmọ ogun bíi igba ó dín mẹ́ta ránṣẹ́ sí ECOWAS Mission ní orílẹ̀ èdè Gambia (ECOMIG).

BI CABLECHECK SE RI Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ

Kò sí ẹ̀rí tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé kankan tó fi hàn pé Nàìjíríà ti fi àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ sí Ísírẹ́lì láti dá rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ dúró.

TAGGED: factcheck, Factcheck in Yorùbá, Israel, News in Yorùbá, nigeria, Peace Support Mission

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael June 28, 2025 June 28, 2025
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print

POPULAR POSTS

Advertisement

Ḿbà, Naijiria ézipụ̀ghị̀ ńdị́ ágha ńkwàdó ùdó nà òbòdò Isreal

Ótù ihe ngosị si na Facebook kwuru na Naijiria zipụrụ ndị agha ka ha gaa…

June 28, 2025

No, Nigeria no send peace support mission go Israel

One Facebook video claim sey Nigeria send soldiers go Israel for joint peace support mission.…

June 28, 2025

A’a, Najeriya ba ta tura tawagar taimakon zaman lafiya zuwa Isra’ila ba

Wani faifan bidiyo na Facebook ya nuna cewa Najeriya ta tura dakaru domin aikin hadin…

June 28, 2025

Ǹjẹ́ Tinubu àti Alexander Zingman lọ sí ilé-ìwé kan náà? Èyí ni ohun tí a mọ̀

Níbi ìfọwọ́ṣe ètò ìgbéṣẹ̀ “Renewed Hope Mechanisation Programme” ní Abuja ní ọjọ́ Mọ́ńdè kan, Ààrẹ…

June 28, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Ḿbà, Naijiria ézipụ̀ghị̀ ńdị́ ágha ńkwàdó ùdó nà òbòdò Isreal

Ótù ihe ngosị si na Facebook kwuru na Naijiria zipụrụ ndị agha ka ha gaa kwàdó udo na mba Isreal.…

CHECK AM FOR WAZOBIA
June 28, 2025

No, Nigeria no send peace support mission go Israel

One Facebook video claim sey Nigeria send soldiers go Israel for joint peace support mission. One male broadcaster wey dey…

CHECK AM FOR WAZOBIA
June 28, 2025

A’a, Najeriya ba ta tura tawagar taimakon zaman lafiya zuwa Isra’ila ba

Wani faifan bidiyo na Facebook ya nuna cewa Najeriya ta tura dakaru domin aikin hadin gwiwa na tallafawa zaman lafiya…

CHECK AM FOR WAZOBIA
June 28, 2025

Ǹjẹ́ Tinubu àti Alexander Zingman lọ sí ilé-ìwé kan náà? Èyí ni ohun tí a mọ̀

Níbi ìfọwọ́ṣe ètò ìgbéṣẹ̀ “Renewed Hope Mechanisation Programme” ní Abuja ní ọjọ́ Mọ́ńdè kan, Ààrẹ Bola Tinubu sọ pé Alexander…

CHECK AM FOR WAZOBIA
June 28, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?