Níbi ìfọwọ́ṣe ètò ìgbéṣẹ̀ “Renewed Hope Mechanisation Programme” ní Abuja ní ọjọ́ Mọ́ńdè kan, Ààrẹ Bola Tinubu sọ pé Alexander Zingman, oníṣòwò ọmọ orílẹ̀-èdè Belarus, jẹ́ ọmọ ilé-ìwé rẹ̀ ní Chicago State University (CSU).
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Zingman wà níbi ayẹyẹ náà, Tinubu ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́” àti “aládùúgbò” nígbà tó wà ní CSU.
Tinubu sọ pé: “Gbogbo yín, Alex jẹ́ aládùúgbò mi dáadáa, ó sì lọ sí ilé-ìwé kan náà pẹ̀lú mi ní Chicago. Mo gbàgbọ́ pé ilé-ẹ̀kọ́ gíga wa yóò dúpẹ́ púpọ̀ pé a ń ṣe èyí níhìn-ín lónìí.”
Ọ̀rọ̀ ààrẹ náà ti mú ìbéèrè dìde nípa àríyànjiyàn tó yí ìwé-ẹ̀kọ́ rẹ̀ ká àti àwọn ìṣòwò Zingman, pàápàá ní Áfíríkà. Púpọ̀ nínú àríyànjiyàn náà dá lórí ìwé-ẹ̀kọ́ Tinubu.
KÍ NÍ A MỌ̀ NÍPA ZINGMAN?
Zingman jẹ́ oníṣòwò kan láti Belarus. Ní oṣù kìíní, ọdún 2019, wọ́n yàn án sípò agbẹjọ́rò aláṣẹ fún Zimbabwe ní orílẹ̀-èdè Belarus. Oníṣòwò ọmọ orílẹ̀-èdè Belarus yìí kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòwò ní Áfíríkà, pàápàá ní Zimbabwe àti Congo.
Wọ́n sábà máa ń so Zingman pọ̀ mọ́ àwọn ohun àmúṣe ìṣòwò ní AFTRADE DMCC, ilé-iṣẹ́ kan tó dá sí Dubai, tó jẹ́ olùgbéṣẹ́ nínú ohun èlò iṣẹ́-àgbẹ̀ àti ti ìwakùn. Ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn kan fi síta sọ pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olúgbégbòrò ilé-iṣẹ́ náà.
Ní Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ibì kan lórí X, ohun ìgbàlódé ibaraẹniṣe alámì krọọsi, ti o n jẹ́ Twitter tẹ́lẹ̀ lórí ayélujára tó ní orúkọ ilé-iṣẹ́ náà fi àwòrán ránṣẹ́ tó ya níbi ìfọwọ́ṣe ètò ìgbéṣẹ̀ “Renewed Hope Mechanisation Programme” ní Abuja.
Àkòrí ọ̀rọ̀ yìí sọ pé: “Àṣeyọrí tó gbòǹgbò fún AFTRADE DMCC! Lánàá ni wọ́n ṣe ìfọwọ́ṣe ètò ìgbéṣẹ̀ “Renewed Hope Mechanisation Programme” ti Nàìjíríà. Èyí jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì sí ìyípadà iṣẹ́-àgbẹ̀ orílẹ̀-èdè náà, a sì láyọ̀ láti kópa nínú ìdàgbàsókè àti ìmúṣiṣẹ́gbòrò ti Nàìjíríà!”

Ní oṣù kẹta, ọdún 2021, wọ́n mú Zingman ní Democratic Republic of Congo (DRC), lórí ẹ̀sùn gbígbé ohun ìjà lọ́nà àìtọ́. Wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ méjìlá, láìsí ẹ̀sùn kankan. Ó sẹ́ gbogbo ẹ̀sùn náà.
Àwọn ibi tí àwọn ènìyàn fi ọ̀rọ̀ pamọ sí tí ó dára lórí ayélujára nípa ìtàn ìgbésí ayé Zingman kéré púpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé àtúnkọ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan láti Day Night TV, ìwé ìròyìn Ukraine kan, pèsè àwọn ìṣípayá nípa ìgbésí ayé ìbẹ̀rẹ̀ oníṣòwò ọmọ orílẹ̀-èdè Belarus yìí. Àtẹ̀jáde ìbẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwo náà kò sí mọ́. CableCheck rí ọ̀na asopọ̀ àtúnkọ náà láti orí Wikipedia Zingman.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwo pẹ̀lú Day Night TV, Zingman sọ pé wọ́n bí òun ní oṣù kọ̀kànlá ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, ọdún 1966, ní Minsk, olú-ìlú Belarus. Èyí túmọ̀ sí pé yóò jẹ́ ọmọ ọdún mọkandinlọgọta, ní oṣù kọ̀kànlá, ọdún 2025.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwo náà, wọ́n tọ́ka sí i pé ó gba oyè ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́gbà (Bachelor’s Degree) láti “Belarusian National Polytechnic University”, níbi tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn ènìyàn nípa Robots and Robotic Systems, láàárín ọdún 1985 sí 1989.
Ó fi kún un pé ó kọ́ ìmọ̀ ìṣòwò ní University of Illinois, Chicago, United States, láti ọdún 1991 sí 1995. Ó tún gba oyè ìkẹ́kọ̀ọ́ lẹhin ti àkọ́kọ́gbà (Master Degree) láti ilé-ìwé gíga náà.
Ó sọ pé òhun ṣiṣẹ́ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Soviet Union láti ọdún 1983 sí 1985.
FÍFI ÀWỌN ÌWÉ Ẹ̀KỌ́ ZINGMAN ÀTI TI TINUBU WÉ RA WỌN
Àwọn ìwé ẹ̀kọ́ Tinubu fi hàn pé ó kẹ́kọ̀ọ́yege láti Chicago State University (CSU) ní ọdún 1979 pẹ̀lú oyè ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́gbà (Bachelor’s Degree) nínú ìṣàkóso ìṣòwò, ìmọ̀ ìṣírò, àti ìṣàkóso. Àmọ́sá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àríyànjiyàn ló ti wà lórí àwọn ìwé ẹ̀kọ́ ààrẹ náà.
Kò sí ẹ̀rí tó dájú tó sọ pé Tinubu àti Zingman lọ sí ilé-ìwé kan náà tí a mọ̀ sí CSU. Oníṣòwò ọmọ orílẹ̀-èdè Belarus náà sọ pé òun lọ sí University of Illinois, Chicago (UIC).
CSU àti UIC jẹ́ ilé-ìwé méjì tó wà ní agbègbè Chicago, ní Illinois, ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, ṣùgbọ́n wọ́n kì í ṣe ilé-ìwé kan náà.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tinubu kò sọ pé òun àti Zingman lọ sí ilé-ìwé gíga ní àkókò kan náà, oníṣòwò náà jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá nígbà tí wọ́n gba Tinubu wọ ilé-ìwé gíga CSU ní ọdún 1977, Zingman sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá nígbà tí Tinubu parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní CSU.
Tí a ba wo ohun tí wọ́n kọ nípa Zingman, Zingman kò tíì wá sí USA (United States of America) nígbà tí Tinubu wà ní CSU. Kò sì sí ibì kankan tí a ti lè rí aridájú àkókò gangan tí Zingman wá sí USA.
Àwọn àkọsílẹ̀ nípa Tinubu fi hàn pé ó bẹ̀rẹ̀ isẹ ní Mobil Oil Nigeria Plc gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé ìṣírò ní ọdún 1983.
Nígbà tí Zingman wà ní ọdún kejì rẹ̀ ní UIC, Tinubu jẹ́ sẹ́nátọ̀ (aṣojúsòfin) tó ń ṣojú Lagos West Senatorial District ní Nàìjíríà.
CableCheck fi Ìmeèlì (email) ránṣẹ́ sí UIC láti lè mọ̀ dájú bóyá Zingman lọ sí ilé-ìwé gíga náà, ṣùgbọ́n UIC kò tíì dáhùn ìmeèlì náà nígbà tí a fẹ gbé ọ̀rọ̀ yìí jade.