Ẹni kan tí wọ́n ń pè ní @Panafrica069 lórí Tiktok, ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán/fídíò síta, ti sọ pé Ibrahim Traore, olórí ijoba Ológun ni Orílẹ̀ èdè Burkina Faso tí sọ pé kí àwọn tó ń ṣòwò tàbí se ọ̀rọ̀ ajé má san owó orí.
Fídíò Tiktok tí ẹnì yìí fi síta ní ọjọ́ kini, oṣù kẹrin, ọdún 2025, ní ohùn ẹni kan tó ń sọ̀rọ̀ ní abẹlẹ pé Traore ti se ohun tí àwọn ènìyàn kò lè gbàgbé nítorí pé ó sọ orílẹ̀ èdè yìí di ibi tí àwọn ènìyàn kò ní máa san owó orí.
Fídíò yìí ní àkòrí tó sọ pé “Ibrahim Traore sọ pé àwọn ènìyàn kò gbọ́dọ̀ san owó orí ní Burkina Faso.” Àwọn ènìyàn tí pín ọ̀rọ̀ yìí ní ìgbà tó ju ẹgbẹ̀rún méje. Àwọn ènìyàn tó ju ẹgbẹ̀rún mọkandinlọgbọn ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ló sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.
Nínú fídíò yìí, a rí ẹni kan tí kò kìí se àkàròyìn gidi tó ń ka ìròyìn kan, ènìyàn kan síi n sọ̀rọ̀ ní abẹlẹ pẹ̀lú àwọn fídíò kan.
Ọ̀rọ̀ tí ẹnì yìí ń sọ ní abẹlẹ yìí sọ pé Elon Musk, ẹni tí ó ni X, ohun alámì krọọsi, tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀, tí ó jẹ́ ohun ìgbàlódé ibaraẹnise, n ròó pé kí ohun gbé isẹ ohun lọ sí orílẹ̀ èdè yìí nítorí pé òhun kò ní san owó orí níbẹ̀.
Ọ̀rọ̀ abẹlẹ yìí tún sọ pé àwọn orílẹ̀ èdè kan fẹ́ fi ìyà jẹ Burkina Faso nítorí ọ̀rọ̀ owó orí yìí. Fídíò Tiktok yìí tún se àfihàn àwọn fídíò mìíràn tí wọ́n sọ àwọn ohun kan tí Traore kò ṣe.
Láti oṣù kẹsàn-án, ọdún 2022, ti Traore tí gba ìjọba, àwọn ènìyàn ti fi àwọn ohun tí wọ́n kìí se òótọ́ àti àwọn ohun tó jẹ́ pé Traore kọ ló ṣe wọ́n sórí ayélujára láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn rò pé ètò ìjọba ẹ dáa. Àwọn ènìyàn sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé nítorí àwọn ohun tí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Russia fa níbi tí a mọ̀ sí Sahel.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Ara àwọn ohun tí ó wà nínú fídíò Tiktok yìí se àfihàn Traore níbi tí ó ti sọ̀rọ̀ níbi kan. Nígbà tí CableCheck lo Google Lens láti se àyẹ̀wò àwòrán yìí, a rí ìròyìn kan tí wẹbusaiti (website) Africa24TV fi síta.
Fídíò tí Traore wà nínú rẹ̀ yìí níbi tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní Academic Excellence Day, ti ọdún 2024, ní Burkina Faso, tó wáyé ní ọjọ́ kẹtalelogun, oṣù kẹjọ, ọdún 2024, ni wọ́n fi gbé ìròyìn náà jáde lórí Africa24TV.

Àwọn ènìyàn lo fídíò Tiktok tí Traore ti sọ̀rọ̀ yìí láti jẹ́ kí ó dàbí pé Traore sọ pé kí àwọn ènìyàn má san owó orí. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ ní Academic Excellence Day, Traore kò sọ̀rọ̀ nípa owó orí. Ohun tí ó se ni pé ó gbóríyìn fún àwọn olùkọ́ ni Burkina Faso fún isẹ dáadáa tí wọ́n ṣe.

CableCheck tún ṣe àyẹ̀wò orí àwọn ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí ìjọba orílẹ̀ èdè Burkina Faso (Burkina Faso government social media accounts). A kò rí ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé Traore sọ pé kí àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè náà má san owó orí.
Ní oṣù Kejìlá, ọdún 2024, ìjọba ológun tí Traore jẹ́ olórí rẹ̀ fi ọwọ sí ètò isuna ọdún 2025 (2025 Finance Act). Nínú ìwé òfin ètò isuna yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ètò owó orí àti àwọn àtúnṣe kan ló wà nínú rẹ̀.
Ara àwọn àtúnṣe yìí sọ pé láti oṣù kìíní, ọdún 2025, àwọn tí wọ́n ń ta nkan tàbí tí wọ́n ń ṣòwò lórí ayélujára yóò máa san owó orí.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Traore kò sọ pé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Burkina Faso kò níí san owó orí mọ.