Ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kínní, ọdún 2025, Chinonso Egemba, dókítà tí ó mọ̀ nípa àìlera, tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ẹni tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Aproko Doctor, sọ pé Nàìjíríà ni orílẹ̀ èdè kejì tí ó ní àwọn ènìyàn tí wọ́n pọ̀ jù tí wọ́n ní kòkòrò apasojaara tàbí kòkòrò tó ń fa àrùn eedi, èyí tí ó ń fa aarunisọdọlẹajẹsára ní àgbáyé.
Dókítà yìí fi ọ̀rọ̀ yìí síta lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise alámì krọọsi (X), tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀. Ẹni yìí ní àwọn ènìyàn mílíọ̀nù méjì àti ọọdunrun tí wọ́n ń tẹ̀lée. Ó sọ ọ̀rọ̀ yìí láti fèsì sí ìpinnu tí Ààrẹ Donald Trump ti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà se pé òhun yóò dá owó ìrànlọ́wọ́ kan tí wọ́n ń pè ní president’s emergency plan for AIDS relief (PEPFAR) dúró.
Gẹ́gẹ́bí àjọ tó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé (World Health Organisation-WHO) se wí, PEPFAR ń pèsè owó ìrànlọ́wọ́ fún ìtọ́jú kòkòrò tó ń fa àrùn eedi fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ju ogún mílíọ̀nù tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú aarunisọdọlẹajẹsára, lára àwọn tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹẹdẹgbẹtá àti mẹrindinlaaadọrin àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò tó ọdún mẹẹdogun.
Nínú ọ̀rọ̀ yìí, dókítà yìí se àlàyé àwọn ọ̀nà tí ìpinnu Trump yìí yóò se se àkóbá fún ògùn kan tí a mọ̀ sí antiretroviral drugs, tí àwọn ènìyàn ti àrùn yìí ń se máa ń lò.
Nígbà tí àwọn ènìyàn sọ pé kí dókítà yìí sọ ibi tí ó ti rí ọ̀rọ̀ yìí, ó se àfihàn ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n tẹ̀ síta tí ó wà lórí ààyè ayélujára/wẹbusaiti (website) ti United Nations Children’s Fund (UNICEF).
“Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni orílẹ̀ èdè kejì ní àgbáyé, tí ó ní àwọn ènìyàn tí wọ́n pọ̀jù, tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú kòkòrò tó ń fa àrùn eedi,” báyìí ni dókítà yìí se wí.
Nínú àtẹ̀síta tó jáde ní ọdún 2018, UNICEF sọ pé àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà igba ó dín mẹwa àti ẹgbẹ̀rún kan dín ní àádọ́ta ní Nàìjíríà ni wọ́n kó àrùn yìí ní ọdọọdún, èyí tí ó jẹ́ kó jẹ́ pé Nàìjíríà ni orílẹ̀ kejì tí wọ́n pọ̀ sí jù ní àgbáyé. UNICEF fi kún ọ̀rọ̀ wọn pé àwọn ènìyàn bíi mílíọ̀nù mẹta ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú kòkòrò tó ń fa àrùn eedi yìí. Àtẹ̀síta yìí fi hàn pé ọdún 2015 ni UNICEF tí wá ọ̀rọ̀ yìí.
Ó se pàtàki kí a mọ̀ pé ìyàtọ̀ wà láàárín àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú àrùn apasojaara àti àwọn tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú kòkòrò tó ń fa àrùn eedi. Gbogbo wàhálà nǹkan yìí ń sọ nípa àwọn tó ń gbé pẹ̀lú kòkòrò tó ń fa àrùn eedi, bí àwọn ènìyàn se ń kó àrùn náà sí, àti àwọn ikú tí àrùn yìí fà.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ THECABLE NEWSPAPER SE RÈÉ
Láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ ohun tí ó jẹ́ òótọ́ àti irọ, CableCheck se àyẹ̀wò WHO’s HIV country intelligence dashboard. Ní ọdún 2023, wọ́n fi ọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú kòkòrò tó ń fa àrùn eedi ní bíi àwọn orílẹ̀ èdè mẹrinlelaaadoje síta.
Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé pé orílẹ̀ èdè South Africa ni ó ní àwọn ènìyàn tí wọ́n pọ̀ jù tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú kòkòrò tó ń fa àrùn eedi, àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú kòkòrò yìí níbẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù méje àti ẹẹdẹgbẹrin, orílẹ̀ èdè India ló tẹ̀ lée, àwọn ènìyàn mílíọ̀nù méjì àti ẹẹdẹgbẹta ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú kòkòrò náà, orílẹ̀ èdè Mozambique ló tẹ̀lée pẹ̀lú àwọn ènìyàn mílíọ̀nù méjì àti irínwó. Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ó wà ní ipò kẹrin. Iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú kòkòrò yìí ní Nàìjíríà jẹ́ mílíọ̀nù méjì.
Country | Number of Persons Living With HIV |
South African | 7,700,000 |
India | 2,500,000 |
Mozambique | 2,400,000 |
Nigeria | 2,000,000 |
United Republic of Tanzania | 1,700,000 |
Uganda | 1,500,000 |
Kenya | 1,400,000 |
Zambia | 1,300,000 |
Zimbabwe | 1,300,000 |
Brazil | 1,000,000 |
Ohun tí àyẹ̀wò yìí túmọ̀ sí ni pé Nàìjíríà ni orílẹ̀ èdè kẹrin tí ó ní àwọn ènìyàn tí wọ́n pọ̀ jù tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú kòkòrò yìí ní àgbáyé. Ayẹwo yìí tún fi hàn pé Nàìjíríà ni orílẹ̀ èdè kẹta tí àwọn ènìyàn ti wọ́n ń gbé pẹ̀lú kòkòrò yìí pọ̀ sí jù ní Afíríkà.
Nínú àtẹ̀síta kan tí àjọ tó ń rí sí ètò/ọ̀rọ̀ ìlera fún àgbáyé fi síta nínú oṣù keje, ọdún 2024, àwọn ènìyàn bíi ogójì mílíọ̀nù ó lé ẹgbẹ̀rún mẹsan-an ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú kòkòrò yìí ní ìparí ọdún 2023. Ọ̀rọ̀ yìí kò sọ iye tí àwọn ènìyàn yìí jẹ́ ní orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan.
Àmọ́sá, àwọn ènìyàn bíi mílíọ̀nù mẹrindinlọgbọn ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú kòkòrò yìí ní Afíríkà.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Ọ̀rọ̀ tí dókítà yìí sọ pé Nàìjíríà ni orílẹ̀ èdè kejì tí ó ní àwọn ènìyàn tó pọ̀ jù tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú kòkòrò yìí ní àgbáyé kìí se òótọ́,
Ọ̀rọ̀ tí WHO fi síta jẹ́ kí a mọ̀ pé kì í se òótọ́.