Ní ọjọ́ Ajé, Abdullahi Sule, gómìnà Ìpínlẹ̀ Nasarawa sọ pé Ìpínlẹ̀ òhun kò yá owó kankan láti ìgbà tí Bọlá Tinubu ti di aàrẹ Nàìjíríà.
Sule sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó se ìpàdé pẹ̀lú àwọn ara Ìpínlẹ̀ Nasarawa, èyí tí ilé isẹ amohunmaworan tí a mọ̀ sí Channels Television ṣe agbekalẹ rẹ̀.
“Mo gbọ pé ẹni kan sọ pé láti ìgbà tí Ààrẹ Tinubu tí di olórí, owó tí ó ń wọlé sí àpò àwọn Ìpínlẹ̀ ti lé síi, àwọn sì fẹ́ mọ ohun tí wọ́n ń fi àwọn owó yìí ṣe,” gómìnà yìí ló sọ báyìí.
“Ẹ lọ sí àwọn àwọn Ìpínlẹ̀, ẹ máa rí àwọn nǹkan tí àwọn gómìnà ń fi àwọn owó yìí se.
“Ní Ìpínlẹ̀ Nasarawa, n kò tí ì yá owó kankan láti ìgbà tí Tinubu ti di Ààrẹ, mo sì lè fọwọ́ sọ̀yà pé a ní ilẹ̀ bíi ẹgbẹ̀rún mẹwa hẹkita tí a fi ń ṣe àgbẹ̀. A sì ti san gbogbo àwọn ohun tí a ń lò, mo lè máa sọrọ síwájú síi.
AYẸWO
Àwọn ọmọ Nàìjíríà fi ìbò yàn Tinubu gẹ́gẹ́bí Ààrẹ ní oṣù kejì, ọdún 2023, wọ́n sì búra fún un ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù karùn-ún, ọdún 2023.
Láti lè se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí, TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣàyẹ̀wò gbèsè owó tí àwọn Ìpínlẹ̀ jẹ àwọn ayanilowo ní Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn lórí ohun ayélujára tí Debt Management Office (DMO) se agbekalẹ rẹ̀ láti ìgbà tí Tinubu ti di Ààrẹ sí àsìkò yìí.
GBÈSÈ OWÓ TÍ NASARAWA JẸ
Ní oṣù kẹfà, ọdún 2023, oṣù kan lẹ́hìn ìgbà tí Tinubu di Ààrẹ, DMO sọ pé gbèsè owó tí Nasarawa jẹ́ àwọn ayanilowo ní Nàìjíríà jẹ́ biliọnu mọkanlelaadọrin ó lé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù naira.
Ní oṣù kẹfà, ọdún 2024, gbèsè yìí lọ silẹ, ó di biliọnu mẹtalelogun àti ẹẹdẹgbẹrun ó lé ogójì miliọnu náírà. Èyí túmọ̀ sí pé ìdá ọgọ́ta àti bíi mẹ́fà ni gbèsè Nasarawa fi lọ silẹ sí ìyè gbèsè ìgbà tí Tinubu di Ààrẹ.
GBÈSÈ OWÓ TÍ NASARAWA JẸ ÀWỌN AYANILOWO NÍ ÀWỌN ORÍLẸ̀ ÈDÈ MÌÍRÀN
Nígbà tí TheCable se àyẹ̀wò ṣíwájú nípa gbèsè tí Nasarawa jẹ, a ríi pé gbèsè náà ti di mílíọ̀nù mejilelaaadọta ó lé pupọ ni owó dọ́là ní oṣù kẹfà, ọdún 2023.
Nígbà tí a tún se àyẹ̀wò ṣíwájú síi, a ríi pé iye tí gbèsè yìí jẹ́ ní oṣù kẹfà, ọdún 2024 ju iye ti ó jẹ́ ní oṣù kẹfà, ọdún 2023.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Ọ̀rọ̀ tí Sule sọ pé ìjọba òhun kò yá owó láti ìgbà tí Tinubu ti di Ààrẹ kìí se irọ.