Awon ènìyàn tí ń pín àwòrán Peter Obi, Ólùdíje fún ipò aàrẹ ni ẹgbẹ́ òsèlú Labour Party (LP) ní ọdún 2023 tí wọ́n ní ó yà pẹ̀lú Musiliu Akinsanya, ọ̀gá fún àwọn onisẹ àwọn ọkọ̀ (mọto) tí wọ́n fi máa ń gbé èrò ní Ìpínlẹ̀ Èkó, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn mọ sí MC Olúọmọ, tí Aàrẹ Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn gẹ́gẹ́bí ọ̀gá pátápátá fún àwọn onisẹ ọkọ (mọto) tí wọ́n fi máa ń gbé èrò ní Nàìjíríà (National Union of Road Transport Workers (NURTW) láti yẹẹ sí.
Wọ́n búra fún Olúọmọ ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kọkànlá, ọdún 2024 gẹ́gẹ́bí olórí pátápátá fún NURTW ní Nàìjíríà.
Nínú àwòrán yìí tí àwọn ènìyàn pín lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrọ (Wasapu-WhatsApp), ó dàbí ẹni pé Obi ló dúró sí ẹgbẹ́ Olúọmọ, ẹni tí ó wọ ‘agbádá.’
Àwòrán tí àwọn ènìyàn sọ pé Obi wà nínú rẹ̀ yìí tí goldmynetv fi síta ní àkòrí tí ó sọ pé Obi ti ṣe tán láti se isẹ pẹ̀lú Olúọmọ.
“Peter fi ìmọrírì tí ó ní sí MC Olúọmọ hàn, ó se ìlérí pé òhun yóò pawọ pọ̀ láti se isẹ pẹ̀lú rẹ̀!”, báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí se wí.
AYẸWO TÍ A SE
TheCable (TheCable Newspaper), ìwé ìròyìn orí ayélujára se àyẹ̀wò àwòrán yìí nípa ohun tí wọ́n ń pè ní reverse image search ní èdè òyìnbó. A ríi pé asọ agbádá tí Olúọmọ wọ̀ nínú àwòrán yìí náà ló wọ̀ ní ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ó bẹ̀rẹ̀ isẹ gẹ́gẹ́bí ọ̀gá pátápátá fún àwọn onisẹ àwọn mọto tí wọ́n fi máa ń gbé èrò.
TheCable tún ríi pé kò sí ilé isẹ ìròyìn tí àwọn ènìyàn ní ìgbàgbọ́ nínú isẹ wọn tó gbé ọ̀rọ̀ yìí jáde.
A kò sì rí ọ̀rọ̀ yìí lórí ibi tí àwọn ènìyàn ti máa ń gbé ohun tí wọ́n ń ṣe sí orí ayélujára (wẹbusaiti-website) tí goldmyne.
Ayẹwo ọ̀rọ̀ yìí nípa lílo fotoforensic, ohun tí àwọn ènìyàn máa ń lò fún digital photo forensics fi hàn wá pé ìyàtọ̀ wà lára asọ tí Obi wọ̀ nínú àwòrán yìí àti asọ yìí tó wọ̀ ní ibòmíràn.
Wọ́n se isẹ sí ara asọ funfun tí Olúọmọ nìkan wà nínú ẹ, kò sí isẹ asọ lára aṣọ Olúọmọ lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí àwọn ènìyàn ti máa ń pín àwòrán ara wọn (Instagram). Àwọ̀ tí ó wà lára asọ tí a rí lórí Instagram sì tún yàtọ̀. Eléyìí túmọ̀ sí pé ó ṣòro láti gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí.
Ẹ lè rí/ka àbájáde àyẹ̀wò yìí níbí.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Wọ́n dá ọgbọ́n irọ sí àwòrán yìí ni kí àwọn ènìyàn lè rò pé òótọ́ ni. Ohun tí wọ́n ní àwòrán yìí jẹ́ kìí se òótọ́.