Ẹni kan tí ó ń lo Tiktok, ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn ti máa ń pín àwòrán tàbí fídíò ara wọn sọ pé àwọn asòfin tí fi ọwọ sì ìwé tí ó lè di òfin láti lè pín Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sí méjì.
Nínú fídíò bíi ìṣẹ́jú méjì, ẹni yìí tí a mọ̀ sí @Eddieblisshotline lórí Tiktok sọ pé wọ́n ti dá Ìpínlẹ̀ tuntun sílẹ̀/yọ Ìpínlẹ̀ tuntun láti ara Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹrindinlaadọta àti ẹẹdẹgbẹrun, wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ẹẹdẹgbẹrin ó lé ní marundinlogoji, wọ́n sì pín in ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ookandinlogoje.
Ẹni yìí sọ pé Ìbàdàn, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò dá dúró bíi Ìpínlẹ̀ tí olú ìlú ẹ sì máa máa jẹ́ Ìbàdàn town.
Ẹni yìí tí a mọ̀ sí @Eddieblisshotline sọ pé kí àwọn ènìyàn mọ Ìpínlẹ̀ tí wọ́n yóò dára pọ̀ mọ́ lẹhin ìgbà tí wọ́n bá dá Ìpínlẹ̀ yìí silẹ.
“A mú ìròhìn tuntun wá fún yín, wọ́n ti pín Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sí méjì. Ẹ mọ̀ pé a ní Ìbàdàn àti Ọ̀yọ́, tí Ìbàdàn sì jẹ́ olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nisinyii, wọ́n ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò sì wà, tí Ọ̀yọ́ town yóò jẹ́ olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́,” arábìnrin yìí ló sọ báyìí.
“Bákan náà ni yóò se jẹ fún Ìbàdàn, èyí tí ó jẹ́ olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Nisinyii, Ìbàdàn yóò dá dúró bíi Ìpínlẹ̀, Ìbàdàn town yóò sì jẹ́ olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ìbàdàn. Eléyìí sì ti di òfin.”
Àwọn ènìyàn tí fi ọ̀rọ̀ yìí sórí fesibuuku/ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ (facebook) àti ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí àwọn ènìyàn ti ń pín àwòrán ara wọn (Instagram).
ǸJẸ́ WỌ́N TI DÁ ÌPÍNLẸ̀ MÌÍRÀN ṢÍLẸ̀ LÁTI ARA ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́?
Ní ọjọ́ kejilelogun, oṣù kẹwàá, ọdún 2024, àwọn ọmọ ilé igbimọ asofin kékeré (house of representatives) ka ìwé ohun tí ó lè di òfin yìí láti dá Ìpínlẹ̀ tuntun silẹ láti ara Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbà kejì.
Ẹni tí ó se agbekalẹ ìwé yìí ni Akeem Adeyemi, asofin (lawmaker/rep) tó ń ṣojú Ọ̀yọ́ federal constituency. Ó fẹ́ se àyípadà àwọn ibì kan nínú ìwé òfin fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ọdún 1999 (1999 constitution) láti lè dá Ìpínlẹ̀ tuntun náà sílẹ̀.
Ó sọ pé dídá Ìpínlẹ̀ náà sílẹ̀ se kókó nítorí pé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tóbi. Ó ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló tóbi jù ní gúúsù ìwọ̀-oòrùn (southwest) Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹtalelọgbọn, ó si ní àwọn ènìyàn mílíọ̀nù márùn-ún àti ẹẹdẹgbẹta ó lé ní ọgọrin ẹgbẹ̀rún, ó lé ẹẹdẹgbẹrun ó dín ní mẹ́fà (àbájáde ikaniyan ọdún 2006).
Kí ìwé tí ó lè di òfin tó di òfin, àwọn asofin ilé igbimọ asofin kékeré àti ilé igbimọ asofin àgbà (senate) gbọ́dọ̀ jíròrò lórí rẹ̀ ní ìgbà mẹ́ta pẹlu àwọn ènìyàn tí ọ̀rọ̀ náà kàn ní àwùjọ. Lẹhin ìjíròrò yìí, wọ́n lè fọwọ́ sí tàbí kí wọ́n kọọ sílẹ̀.
Lẹhin ìgbà tí àwọn asofin bá fi ọwọ síi, wọ́n á fi ransẹ sí Ààrẹ kí òhun náà fọwọ́ síi.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé wọ́n ti dá Ìpínlẹ̀ tuntun sílẹ̀ láti ara Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kì í se òótọ́.