Peter Obi, Oludije fún ipò Ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party (LP) ní ọdún 2023 sọ pé orílẹ̀-èdè South Africa di ìbò láìpẹ́ yìí láìsí aisedeedee tàbí wàhálà kankan.
Obi sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ Satide nígbà tí ó ń ṣàgbéyẹ̀wò ìdìbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti South Africa.
“Àbájáde ìdìbò àìpẹ́ ní South Africa fi orílẹ̀-èdè yìí hàn bíi àwòkọ́se bí ètò ìdìbò gbọ́dọ̀ ṣe rí,” báyìí ni Obi, gómìnà Anambra tẹ́lẹ̀ ṣe wí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise alámì krọọsi (tí à mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀).
“Bí ìdá ọgọ́ta àwọn tí wọ́n forúkọ sílẹ̀ láti dìbò ni wọ́n jáde láti dìbò, bíi ìdá àádọ́rùn-ún ètò ìdìbò ló bẹ̀rẹ̀ lásìkò, èsì sì jáde lásìkò láìsí wàhálà.
“Eléyìí fihàn pé ìdìbò tí kò ní màgòmágó nínú ni. Èsì ìbò tí kò ní tàbí-ṣùgbọ́n nínú tí wọ́n fi sí orí ayélujára fi ye wa pé wọn ń lọ síwájú.”
South Africa di ìbò fún àwọn àgbègbè àti gbogbo orílẹ̀-èdè ní ọjọ́ kọkandindinlọgbọn, oṣù karùn-ún, ọdún 2024. Èsì ìbò bẹ̀rẹ̀ sí ní jáde ní irọlẹ ọjọ́ tí wọn dìbò. Wọ́n sì sọ àbájáde gbogbo ìbò ní ọjọ́ kejì, oṣù kẹfà, ọdún 2024.
Ìbò yìí di ohun tí gbogbo àyè fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí pé ẹgbẹ́ òṣèlú African National Congress (ANC) tí ó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́ pàdánù ọ̀pọ̀lọpọ̀ ijoko ní ilé ìgbìmọ̀ asofin, èyí tí ó jẹ́ kí ó ṣe àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn láti ṣe ìjọba.
Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ANC tí ó ti ń darí ìjọba láti 1994 kùnà láti ní ìbò tí ó pọ jùlọ.
Cyril Ramaphosa, Ààrẹ orílẹ̀-èdè náà gba èsì ìbò yii. Ó ní bí àwọn ènìyàn ṣe fẹ́ ló ṣe rí. Gbígbà tí Ramaphosa gba àbájáde ìbò yìí jẹ́ kí Obi àti àwọn ènìyàn miran gbóríyìn fún un.
Ṣe òótọ́ wà nínú àwọn ohun tí Obi sọ?
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́KỌ́: OBI SỌ PÉ KÒ SÍ AISEDEEDEE TÀBÍ WÀHÁLÀ KANKAN NÍGBÀ ÌBÒ YÌÍ.
Bí a ṣe rí ọrọ yìí sí: Irọ́ ni.
Ara àwọn nǹkan tí Obi sọ ni pé ìbò náà kò ní aisedeedee kankan.
Èyí kìí se òótọ́.
Ní àárọ̀ ọjọ́ kọkanlegbọn, oṣù karùn-ún, ọdún 2024, ojú ìwé ibí tí Electoral Commission (IEC), àjọ tí ó ń ṣètò ìbò ní orílẹ̀-èdè náà parẹ fún bíi wákàtí méjì.
IEC bẹ àwọn ènìyàn ki wọn má bínú láì sọ ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọn sì sọ pé kò sí màgòmágó nínú àbájáde ìbò.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò tẹ the uMkhonto we Sizwe (MK) ẹgbẹ́ òṣèlú tí Jacob Zuma, Ààrẹ orílẹ̀-èdè náà tẹ́lẹ̀ tì lẹhin lọ́run. Zuma sọ pé IEC ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣemáṣe.
Ó ní pé MK ní ẹri màgòmágó tí IEC ṣe nígbà tí ojú ìwé àjọ náà parẹ. Ó sọ pé wọn máa mú inú bí àwọn ọmọlẹ́yìn òhun tí wọn kò bá ṣe àtúnṣe.
Ọ̀RỌ̀ KEJÌ: OBI SỌ PÉ IDÀ ỌGỌ́TA ÀWỌN ÈNÌYÀN TÍ WỌ́N FORÚKỌ SÍLẸ̀ LÁTI DÌBÒ NI WỌN JÁDE DÌBÒ, Ó TÚN NÍ ÀWỌN ỌMỌ SOUTH AFRICA TÓ WÀ NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ MÌÍRÀN DI ÌBÒ.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ SÌ: Òótọ́ wà nínú ọ̀rọ̀ yìí.
Obi sọ pé idà ọgọ́ta àwọn ènìyàn tí wọ́n forúkọ sílẹ̀ láti dìbò ló jáde láti di ìbò.
Gẹ́gẹ́bí South African Government News Agency se wí, idà ọgọ́ta ó dín méjì iye àwọn ènìyàn tí wọn forúkọ sílẹ̀ láti di ìbò ní 2024 ló jáde láti di ìbò.
Idà ọgọ́ta àti mẹ́fà àwọn ènìyàn tí wọn forúkọ sílẹ̀ láti di ìbò ní ọdún 2019 ni wọn jáde láti di ìbò. Eléyìí túmọ̀ sí pé iye àwọn ènìyàn tí wọn jáde láti di ìbò ní 2024 kò tó iye àwọn ènìyàn tí wọn jáde láti di ìbò ní 2019.
Àmọ́sá, òótọ́ ni Obi sọ nípa àwọn ọmọ South Africa tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí wọn di ìbò, eléyìí tí a mọ̀ sí diaspora voting ni èdè òyìnbó.
Láti ọdún 2009 ni òfin tí sọ pé kí IEC ṣètò bí àwọn ọmọ South Africa tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn yóò ṣe di ìbò nígbà ìbò ní South Africa. IEC ṣe irú ètò yìí nígbà ìdìbò tó wáyé ní oṣù karùn-ún, ọdún 2024.
Àwọn ọmọ South Africa tí wọn wà ní orílẹ̀-èdè mìíràn tí wọ́n sì fẹ́ dìbò nígbà ibo South Africa yóò fi àmì idanimọ pé ọmọ South Africa ni àwọn hàn níbi tí ìjọba South Africa lọ́wọ́ sí ní orílẹ̀-èdè tí wọn tí fẹ́ di ìbò.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Irọ́ ni púpọ̀ ọ̀rọ̀ tí Obi sọ nípa ìbò South Africa. Aisedeedee tàbí àwọn ohun tí wọn kù díẹ̀ kaato wà nínú/nígbà ìbò náà. Àwọn ènìyàn tí wọ́n jáde láti dìbò kò tó ìdá ọgọ́ta.
Àmọ́sá, ètò wá fún àwọn ọmọ South Africa tí wọn fẹ́ di ìbò láti orílẹ̀-èdè mìíràn.