Hope Uzodimma, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Imo sọ wí pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú All Progressives Congress (APC) àti àwọn tí ó sún mọ́ ìjọba rẹ̀ nìkan ni àwọn abankanjẹ ń kọlù ní Ìpínlẹ̀ náà.
Uzodimma fi ẹ̀sùn kan àwọn olóṣèlú pé àwọn ni ó wà ní ìdí aisifọkanbalẹ ní Ìpínlẹ̀ náà.
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Imo náà sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ alamisi ní orí ètò kan lórí ẹ̀rọ amohunmaworan tí a mọ̀ sí Channels Television.
Events of the past have shown clearly that politicians are the ones behind the insecurity in Imo State.
– Sen. Hope Uzodimma, Governor of Imo State.#CTVTweets pic.twitter.com/hW2Pc2vm14
— Channels Television (@channelstv) January 5, 2023
“Ní ọjọ́ eni, nínú ìjíròrò mi pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ọ̀rọ̀ Ìpínlẹ̀ Imo jẹ lógún/kàn, mo fi yé wọn pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti ṣẹlẹ̀ fi yé wa pé àwọn olóṣèlú ni ó wà ní ìdí aisifọkanbalẹ ní Ìpínlẹ̀ Imo,” Uzodimma wí báyìí.
“Fún àpẹẹrẹ, nínú ọ̀rọ̀ agbekalẹ tí mo ṣe, mo fi yé àwọn ènìyàn pé gbogbo àwọn ènìyàn tí wọn ti rí akọlukọgba ní Ìpínlẹ̀ Imo, gbogbo àwọn ilé tí wọn fi iná sun jẹ́ ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú APC àti àwọn tí ó sún mọ́ ìjọba mi.
“Tí o bá wòó, kò sí ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú kankan tí ó rí àkọlù ni Ìpínlẹ̀ Imo, kò sí ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú alátakò tí wọn sun ilé rẹ̀ ní iná. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò sì dawọ dúró.
“O sọ̀rọ̀ nípa Ikedi Ohakim, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Imo tẹ́lẹ̀rí. Ọjọ́ kẹta tí ó pe àpéjọ àjọjẹ-ajọmu fún àwọn tí ọ̀rọ̀ Ìpínlẹ̀ Imo kàn/jẹ lógún tí ó sì rọ̀ wọn pé kí wọ́n ṣe atilẹyin fún ẹgbẹ́ òsèlú APC, ọjọ́ kejì rẹ̀ ni àwọn ọ̀daràn pa àwọn tí ó ń sọọ.
“Nípa ìdí èyí, mo ti gbé ọ̀rọ̀ yìí kalẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Imo, ọwọ́ àwọn agbofinro ti tẹ lára àwọn obayejẹ yìí.
“Mo ti rọ àwọn agbofinro Ìpínlẹ̀ Imo pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ nípa àbájáde ìwádìí wọn àti àwọn ẹni tí ó wà ní ìdí ipaniyan yìí.
“Wọ́n sì máa ṣe gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀. Èmi kò ní ṣe bí ẹni pé ọ̀rọ̀ yìí kò ṣẹlẹ̀. Èmi kò sì níí fi aisifọkanbalẹ àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ yìí ṣe ọ̀rọ̀ òsèlú.”
ISARIDAJU
Ní aipẹ, Ìwé Ìròyìn TheCable gbé ìròyìn nípa bí àwọn ọ̀daràn agbebọnkiri ṣe ń kọlu àwọn olóṣèlú àti oun ìní ní Ìpínlẹ̀ Imo.
Ní ọjọ́ mélòó kan sẹhin, àwọn ọ̀daràn agbebọnkiri kọlu àwọn ọkọ̀ Ikedi Ohakim. Àwọn Ọlọpa mẹ́rin ni ó pàdánù ẹ̀mí wọn.
Nínú oṣù Kejìlá, ọdún 2022, ilé ẹjọ́ kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Owerri àti ilé ẹjọ́ gíga ní ìjọba ìbílẹ̀ Orlu ní Ìpínlẹ̀ Imo ni àwọn agbebọnkiri dá iná sun láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún.
Ní àfikún, nínú oṣù Kejìlá, ọdún 2022, àwọn agbebọnkiri pa Christopher Eleghu, Ólùdíje nínú ẹgbẹ́ òsèlú àwọn òṣìṣẹ́ (Labour Party-LP) fún agbègbè ìṣejọba/isofin Onuimo ní ilé igbimọ asofin ti Ìpínlẹ̀ Imo.
Ní ọjọ́ Kejìlá, àwọn ọ̀daràn agbebọnkiri kọlu ọ́fíìsì Independent National Electoral Commission (INEC), ẹ̀ka ìjọba Àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ń ṣe ètò nípa ìbò ni Owerri, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Imo.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Ọ̀rọ̀ tí Uzodimma sọ wí pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú APC àti àwọn ènìyàn tí ó sún mọ́ ìjọba òun nìkan ni àwọn abankanjẹ ń kọlù kìí se òótọ́/òtítọ́.
Christopher Eleghu, Ólùdíje nínú ẹgbẹ́ òsèlú àwọn òṣìṣẹ́ fún agbègbè ìṣejọba Onuimo rí àkọlù, àwọn ọ̀daràn agbebọnkiri sì gba ẹ̀mí rẹ̀ ní ìlú rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Imo.