Rabiu Kwankwaso, ẹni tí ó jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kano tẹ́lẹ̀rí tí ó sì tún jẹ́ Adijedupo fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú New Nigeria Peoples Party (NNPP) ti sọ wí pé ìjọba òun kò yá owó kankan ní ọdún mẹ́jọ tí òun fi ṣe ìjọba Ìpínlẹ̀ náà.
Kwankwaso sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kọkànlá ní ibi ifiọ̀rọ̀jomitoroọ̀rọ̀ tí a pè àkòrí rẹ̀ ní Àwọn Adíje, eléyìí tí Kadaria Ahmed, onísẹ ìròyìn dari rẹ̀.
“Rabiu Kwankwaso kò yá náírà kan ní ọwọ́ bánkì tàbí ẹni kankan yálà ní orílẹ̀-èdè yìí tàbí òkè òkun,”Gómìnà tẹ́lẹ̀rí náà ni ó sọ bayìí.
Ó tún sọ síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé “mo jẹ́ Gómìnà tí kò yá owó rárá, àti pé kamaparọ, èmi kò fẹ́ràn owó yíyá. Eléyìí nìkan kọ́, nígbà tí wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́bí Gómìnà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbèsè ni mo banilẹ tí mo sì san láàárín ọdún mẹ́rin.
“Mo kùnà nínú ìdíje fún iyannisipo ní ọdún 2003. Lẹ́hìn ọdún mẹ́jọ tí mo padà ṣé’jọba, mo tún bá gbèsè nilẹ, eléyìí tí mo tún san láàárín ọdún mẹ́rin. Mo fi ìjọba Ìpínlẹ̀ Kano silẹ laijẹ gbèsè náírà kan.”
Ó tún sọ̀rọ̀ kan náà ní ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù kọkànlá nígbà tí ó lọ sí ibi ìpàdé àwọn tí ó ń díje fún Ipò Ààrẹ pẹ̀lú àwọn ará ìlú tí ilé-isẹ ẹ̀rọ amohunmaworan tí a mọ sì Channels Television ṣe agbekalẹ rẹ̀.
Ní ìdáhùn sí ìbéèrè bí yóò sese ètò isuna laijẹ gbèsè síi, Kwankwaso sọ lẹẹkansi pé gẹ́gẹ́bí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kano rí, ìjọba òun kò yá owó rí.
“Ní Kano, a kò ní ìṣòro eto isuna tí owó nínà ju owó tí a má rí lọ nítorí wí pé a máa ń ṣe àkíyèsí owó tí ó ń wọlé, a sì máa ń wo nkan tí ó se kókó láti ṣe. Èmi kìíse ẹni tí ojú máa ń kán láti yà owó ṣe ohunkóhun,“ Kwankwaso ni ó wí báyìí.
“Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yìí ní owó lọpọlọpọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní kò sì owó ní orílẹ̀-èdè yìí kò mọ ni tàbí ó fẹ́ ṣe èké. Owó wà láti ṣe itọju ẹni kọ̀ọ̀kan wa ni Orílẹ̀-èdè yìí.
“Ati ṣe tẹ́lẹ̀rí ní Kano láti ọdún 1999 di ọdún 2003. A bá gbèsè púpọ̀ nilẹ, a sì san gbogbo rẹ̀. Lẹ́hìn ọdún mẹ́jọ nígbà tí mo padà tún di Gómìnà, mo bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbèsè tí ó jẹ ọgọrun mílíọ̀nù ni ọ̀nà púpọ̀ niti owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà, a ṣí san gbogbo rẹ̀ kí ń tó fi ìjọba sílẹ̀ ní ọdún 2015.
“Owó yíyá láti ọwọ́ bánkì tàbí ènìyàn ni mo ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. A kò yá owó rárá fún ọdún mẹ́jọ tí mo fi se/jẹ́ Gómìnà.”
Ni ọdún 2021, nínú ifọrọwaniẹnuwo tí ó se pẹ̀lú ile-isẹ amohunmaworan tí a mọ sí Arise Tv, Kwankwaso fi ẹ̀sùn kan Abdullahi Ganduje, ẹni tí ó jẹ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kano lọ́wọ́lọ́wọ́ pé ó kó Ìpínlẹ̀ náà sínú gbèsè púpọ̀. Lẹẹkansi, Kwankwaso ní wí pé òun kò yá náírà kan ni gbogbo ọdún mẹ́jọ tí òun fi jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ náà.
Ǹjẹ́ òtítọ́ ni wí pé Ìpínlẹ̀ Kano kò yá owó kankan nígbà tí Kwankwaso jẹ Gómìnà?
Kwankwaso jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kano láàárín ọdún 1999 àti ọdún 2003.
Mo kùnà idije láti ṣe Gómìnà ni ìgbà kejì ní ọdún 2003. Lẹ́hìn èyí, a yàn-án gẹ́gẹ́bí minisita fún ètò ààbò láti ọdún 2003 di ọdún 2007.
A dibo yàn-án wọlé ní ìgbà kejì gẹ́gẹ́bí Gómìnà fún Ìpínlẹ̀ Kano ní ọdún 2011.
Debt Management Office (DMO), ẹ̀ka ìjọba tí ó ń rí sí ọ̀rọ̀ nípa gbèsè kò pèsè data ni ori wẹbusaiti wọn láti ṣe àtìlẹ́yìn ọ̀rọ̀ tí Kwankwaso sọ pé òun yá owó tàbí kò yá owó nígbà àkọ́kọ́ tí ó se Gómìnà ni odun 1999 sì ọdún 2003.
Gbèsè ìta dínkù nibi idamẹwa ọgọ́rùn-ún láàárín ọdún 2011 àti ọdún 2015
Láti data tí a rí gbà ní ọwọ́ ẹ̀ka tí ó ń rí sí ọ̀rọ̀ gbèsè, gbèsè ìta tí Kano jẹ jẹ́ ẹẹrinlelọgọta ó dín ni ẹgbẹ́ta mílíọ̀nù dọla ($63.94) nígbà tí Kwankwaso di gómìnà lẹẹkeji.
Nígbà tí ó parí ìjọba rẹ̀, gbèsè náà tí dínkù sí àádọ́ta mílíọ̀nù àti mẹ́jọ ó dín ní ẹgbẹ̀rún ni ọna ẹgbẹ́ta àti mẹwa dọla ($57.61 million) èyí tí ó jẹ ẹdin bí idamẹwa ọgọ́rùn-ún.
Gbèsè tí Ìjọba Ìpínlẹ̀Kano jẹ àwọn ayanilowo ni Nàìjíríà lé síi ní ìdá ẹgbẹ̀rún
Data tí a rí gbà lọ́wọ́àjọ tí ó ń ṣe ètò nípa gbèsè ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi yé wa pé láàárín ọdún 2011 àti
2015, ní ìgbàkejì tí Kwankwaso ṣe/jẹ Gómìnà, gbèsè tí Ìjọba Ìpínlẹ̀Kano jẹ àwọn ayanilowo ni Nàìjíríà lé
síi ní ìdá ẹgbẹ̀rún.
Ni ọdún 2011 nígbà tí àwọn oludibo fi ìbò yàn-án gẹ́gẹ́bí gómìnà lẹẹkeji, gbèsè tí ó wà nílẹ jẹ́ biliọnu mẹ́fà ó dín mílíọ̀nù mẹ́tàlá naira (N5.87 billion). Ní ọdún 2015 nígbà tí ó kúrò ní ipò gómìnà, gbèsè Ìpínlẹ̀ náà jẹ́ biliọnu marundinniaadọrun naira, èyí tí ó jẹ èlé ọna ẹgbẹ̀rún àti mẹjọ.
Ní àìsí àní-àní, pupọsi gbèsè owó tí a ya ni ìlú Nàìjíríà kò pọndandan kí ó jẹ́ òun ti ó ṣẹlẹ̀ nípa pé kí a yawosi nígbà tí a bá wo àwọn òun bíi lílé owó èlé àti owó karakata òkè òkun.
Ní idakeji ẹwẹ, àyẹ̀wò ìwé ìròyìn TheCable jẹ́ kí a ríi pé ìyàtọ̀ owó wá sí owó karakata ilẹ̀ òkè òkun kìí se òun tí ó se okùnfà bí gbèsè ṣe pọsi gan-an.
Kí a má pa irọ, owó Nàìjíríà jẹ aarunleniaadọjọnáírà sì dọla kan owó ilẹ Amẹ́ríkà ní ọdún 2011 àti ìgbà náírà ó dín mẹ́ta sì dọla kan owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà ní ọdún 2015.
Abdullahi Ganduje, gómìnà Ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́lọ́wọ́ sọ pé Ìpínlẹ̀ náà yà owó
Kí Kwankwaso àti Ganduje tó di ọ̀tá ara wọn, Ganduje, ẹni tí ó jẹ igbá-kejì Kwankwaso nígbà tí Kwankwaso jẹ́ gómìnà tí ó sì di gómìnà ni ọdún 2015 lẹ́hìn tí Kwankwaso ṣe gómìnà sọ pé kò burú kí ẹni tí ó se ìjọba síwájú òun yìí fi gbèsè biliọnu ọdúnrún náírà sílẹ̀-eléyìí tí ó ju iye tí ẹka ijọba tí ó ń rí sí ọ̀rọ̀ gbèsè sọ wí pé Ìpínlẹ̀ náà jẹ.
“Èmi kò rò wí pé Kwankwaso ṣe òun ti ó burú nípa fífi gbèsè pupọ sílẹ̀ nítorí pé a ṣe ètò òun tí a ṣe, ó sì jẹ ajọmọ àti àjọṣe òun àti èmi”, Ganduje ni ó wí báyìí.
O tún bù ẹnu lu àwọn tí wọn sọ wí pé Kwankwaso dá Ìpínlẹ̀ náà ní gbèsè nípa owó yíyá. Ó si tún sọ wí pé owó yíyá ko burú, owó epo ti ó lọ silẹ ni ó fa airowona.
Ó sọ ní ibi kan pé ó yẹ kí àwọn ará Kano gbé oriyin fún Kwankwaso fún àyípadà gidi tí ó muba Ìpínlẹ̀ náà botilẹjẹpe wahala gbèsè wá nilẹ.
“Gbogbo òun tí ó ṣẹlẹ̀ ni mo mọ. Àwọn ènìyàn fẹ́ kí a ṣe nkan gidi púpọ̀ nípa pé owó epo pupọ ń wọlé, àwa náà sì ro wí pé owó náà máa wọlé dédé. Lairotẹlẹ, owó epo ja lulẹ,” Ganduje ní o sọ bayii ní ọdún 2015.
“Kò sí òun tí ó burú kí ìjọba sì ìjọba fi gbèsè sílẹ̀. Àwọn tí ó ń pariwo ni ọjọ́ eni yóò ṣe bákan náà tàbí burú jù bẹlọ tí wọn ba de ipò ìjọba. Ó yẹ kí a gbóríyìn fún Kwankwaso, gómìnà mi, fún isẹ ribiribi tí ó se ni Ìpínlẹ̀ wa.”
Nínú ìròyìn ni ọdún 2015, àwọn agbasẹse Ìpínlẹ̀ Kano sọ wí pé kí àjọ tí ó ń gbógun ti isenkanmọkumọku tú ìdí Kwankwaso fún ẹsun gbèsè biliọnu igba náírà àti bí ó se bá ńkan jẹ́ fún àwọn agbasẹse kí ó tó lọ sí ilé àwọn asofin àgbà.
Ní ọdún 2015, Auduwa Maitangaran, ẹni tí ó jẹ alága àwọn agbasẹse ní Ìpínlẹ̀ náà sọ wí pé àwọn agbasẹse ni ilẹ̀ Kano tí ó lé ní àádọ́ta ni a ti rán lọ s’ẹwọn àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí ó ju ẹgbẹ̀rún ni wọn ti di èrò ilé ìwòsàn nítorí owó wọn tí Kwankwaso kò san.
“A ti pàdánù ọmọ ẹgbẹ́ tí ó ju ogójì tí wọn gbẹmimi lẹ́hìn àìsàn nítorí wí pé wọn kò rí owó tí ìjọba Kwankwaso jẹ wọn gbà,” ó sọ báyìí.
Agbasẹse náà sọ wí pé “Iye ìdá ọgbọ́n owó isẹ ti Kwankwaso gbé fún àwọn àgbàsẹse ni ó san ní ọdún mẹ́rin tí ó fi ṣe ìjọba.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn bí ìdá àádọ́ta agbasẹse ni kò rí owó isẹ wọn gbà nígbà tí ó parí ìjọba.
“Alhaji Idi Bilya, ìkan nínú àwọn agbasẹse kú lójijì nítorí airiowogba àti Alhaji Ibrahim Carpenter, ẹni tí ó jẹ ọmọ ẹgbẹ́ tí ó ní ju àádọ́ta mílíọ̀nù lọ́wọ́ ìjọba Ìpínlẹ̀ Kano tí kò ní tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà lọ́wọ́ báyìí. Ìwà tí ó burú jayi ni èyí,”alága àwọn agbasẹse ni ó sọ báyìí ní ọdún 2015.
Muhammad Garba, Kọmisọna nígbà kan rí fi ẹṣun kan Kwankwaso fún yíyá biliọnu mẹ́rin àti ọgọrun mílíọ̀nù náírà owó àwọn tó ti ṣe iṣẹ́ fẹyinti láti fi kọle.
Ìwé Ìròyìn Daily Trust sọ wí pé Garba sọ wí pé: “Kwankwaso ya biliọnu mẹ́rin àti ọgọrun mílíọ̀nù náírà owó àwọn tó ti ṣe iṣẹ́ fi ẹhin tì láti kọ àwọn ilé tí a kọpọ pẹ̀lú èrò pé yóò ṣe àwọn tí wọn ti ṣe iṣẹ́ fẹhinti náà ní àǹfààní.
“Ṣùgbọ́n, nígbà tí ó ríi pé àwọn ilé náà ti wọnju fún wọn láti gbé, ó dín ìdajì kúrò nínú owó ilé náà. Pẹ̀lúpẹlu èyí, àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn ti fẹyinti lẹnu isẹ náà kò ní owó láti ra àwọn ilé náà.”
Bí a ṣe rí ọ̀rọ̀ yìí sí
Irọ ni ọ̀rọ̀ tí Kwankwaso sọ pé ìjọba òun kò yá owó nígbà tí òun jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Kano. Data tí a rí fihàn pé owó tí Ìpínlẹ̀ Kano yá ní Nàìjíríà lé síi ni ìdá ẹgbẹ̀rún àti mẹjọ. Ní àfikún, ẹni tí ó se ìjọba lẹhin rẹ̀ àti àwọn agbasẹse ní Ìpínlẹ̀ náà sọ wí pé Ìpínlẹ̀ náà jẹ gbèsè gọbọyi (púpọ̀) nítorí wí pé wọn yá owó.