Kashim Shettima, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Bornu tẹ́lẹ̀rí tí ó sì tún jẹ́ oludije fún Ipò igbá-kejì Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) ni ọdún 2023, sọ láìpẹ́ yìí pé ìpínlẹ̀ Èkó lóní ọrọ̀ ajé kẹta tí ó tóbi jùlọ ní ilẹ̀ Áfíríkà.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Bornu tẹ́lẹ̀rí náà sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ ajé, ní ibi ìpàdé ọdọọdún ẹgbẹ́ àwọn agbẹjọro ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (NBA–Nigerian Bar Association Conference), ní ibi tí ó ti ṣe aṣojú fún Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, ẹni tí ó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ òsèlú APC ní ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó sì tún jẹ́ olùdíje fún ipò Ààrẹ nínú ibo àpapọ̀ tí ọdún 2023.
Nínú àlàyé rẹ̀ lórí ìdí tí ipò ààrẹ fi tọ́ sí Tinubu láàrín àwọn olùdíje tókù, Shettima sọ pé ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Èkó ni ó wà ní ipò kẹta nínú àwọn ọrọ̀ ajé tí ó tóbi jùlọ ní Áfíríkà.
“Ní ìgbà tí Tinubu jẹ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 1999, ọkọ̀ fún àwọn aláìsàn kansoso ló wà lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba Èkó. Ẹgbẹ̀ta mílíọ̀nù náírà ni ó ń wọlé sí àpò ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó,” Shettima ló sọ báyìí.
“Nibayii, oókànléláàádọ́ta biliọnu náírà ni ó ń wọlé fún Ìpínlẹ̀ Èkó lóṣooṣù, ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Èkó ni ìkẹta tó tóbi jùlọ ní Áfíríkà,” ó fi eléyìí kún ọ̀rọ̀ rẹ.
Incoming Vice President, Senator Kashim Shettima breaking the entire table at the NBA Conference earlier today pic.twitter.com/bmB2TAZFSU
— Daddy D.O🇳🇬 (@DOlusegun) August 22, 2022
Kìíse ìgbà àkọ́kọ́ tí oludije fun ipò igbá-kejì Ààrẹ náà máa gbé àhesọ náà nìyí.
Nínú fọ́nrán kan tí wọn ti ṣ’atunpin ní ọpọ ìgbà lórí ìkànnì abẹ́yẹfò (Twitter) ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹjọ, Shettima ní wí pé: “Oun tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nílò ní àsìkò yìí ni adarí tí yóò mú ìyípadà gidi bá orílẹ̀-èdè wa…Tinubu ni rẹkọdu tí ó dára nígbàtí ó ṣe ìjọba. Ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Èkó ni ìkẹta tó tóbi jùlọ ní Áfíríkà.”
Wọn kọ́kọ́ pín fọ́nrán náà sí ojú òpó kan l’órí ìkànnì abẹ́yẹfò tí a mọ sí @Progressive4BAT, èyí tí màá ń se àtìlẹ́yìn Tinubu. Àwọn olùmúlò ojú òpó yìí sì ti wo fọ́nrán náà ni ọ̀nà ọkẹ mẹ́fà àbọ̀.
Ní ọjọ́ kẹfà, oṣù kẹjọ, Festus Keyamo, mínísítà fún ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tó tún jẹ́ agbẹnusọ fún igbimọ ìpolongo ìdìbò Ààrẹ fún Tinubu ṣ’atunpin fọ́nrán náà si ojú òpó rẹ lori abẹ́yẹfò pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ifori yìí: “ẹ wí dáadáa, ọlanla jùlọ.”
Ní ìgbà kan rí, Tinubu sọ wí pé Ìpínlẹ̀ Èkó ni ìlú tó ní ọrọ̀ ajé tó tóbi jùlọ ní Áfíríkà.
Ní oṣù kẹrin, ọdún 2022, Tinubu ni ìpàdé pẹ̀lú àwọn agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin fún àwọn Ìpínlẹ̀ mẹẹdogun ni ibi àpéjọ kan ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó.
Well said, your Excellency. pic.twitter.com/V15XXVs4Ex
— Festus Keyamo, SAN, CON, FCIArb (UK) (@fkeyamo) August 6, 2022
Nígbà kan rí, Tinubu sọ pé ọrọ ajé ìpínlè Èkó ló tóbi jùlọ ní Áfíríkà
Nínú Ìròyìn náà ti Daily Trust gbé jáde— ni ìgbà tí Tinubu ń ṣe ipolongo ara rẹ ṣaaju ìdìbò abẹle fún oludije sí ipò ààrẹ ní ègbé òsèlú APC, o ni imọ ijinlẹ nipa ìṣàkóso gẹgẹbi Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó tẹ́lẹ̀rí náà ni ó ran ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́ láti jẹ́ ilu tó ní ọrọ ajé tó tóbi jùlọ ní Áfíríkà.”
“Wọn tọ mi láti ní ọkàn akin, èyí sì ràn mí lọ́wọ́. Láì gba owó kánkan láti ọwọ FAAC-Federal Account Allocation Committee, mo mú idagbasoke bá ìpínlẹ̀ Èkó. Ní ọjọ́ òní yìí, Ìpínlẹ̀ náà lóní ọrọ ajé tó tóbi jùlọ ní Áfíríkà. Ó tó kí ń gbéraga. Mo fẹ́ tún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà náà ṣe báyìí” Tinubu lo sọ báyìí.
Ṣé lóòótọ́ ni wí pé ìpínlẹ̀ Èkó kò gbà owó kánkan láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀ ní ọdún 1999 si 2007? Ǹjẹ́ òótọ́ ni ọ̀rọ̀ àwọn oludije ẹgbẹ́ òṣèlú APC yìí-Shettima àti Tinubu-nípa ọrọ ajé ìpínlẹ̀ Èkó?
Àbájáde ìwádìí wà nìyí
Ǹjẹ́ òtítọ́ ni wí pé Ìpínlẹ̀ Èkó kò rí owó kankan gbà láti ọwọ ìjọba àpapọ̀ ni ìgbà tí Tinubu jẹ Gómìnà ìpínlẹ̀ náà?
Ní ọjọ́ àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹtàdínlọgbọn, oṣù kẹta, ọdún 2004, ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó se ètò ìdìbò láti dá ìjọba ìbílẹ̀ mẹtadinlọgọta silẹ ní ìbámu pẹ̀lú òfin Ìjọba ìbílẹ̀, òfin karùn-ún ti ọdún 2002 ti ìpínlẹ̀ Èkó (Local Government Areas Law No. 5 of 2002 of Lagos State).
Ìpínlẹ̀ Ebonyi, Katsina, Nasarawa ati Niger náà dá ìjọba ìbílẹ̀ tuntun sílẹ̀ ní ìgbà kannáà pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Èkó.
Olusegun Obasanjo, ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìgbà tí a dá àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà silẹ, nínú lẹta tó kọ sí Nenadi Usman, mínísítà nígbà náà fún ètò isuna/ìnáwó ní: “Gẹ́gẹ́bí o ti mọ̀ pé ilé ìgbìmọ̀ aṣofin kò tíì ṣe ìpèsè tí ó tọ́ fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tuntun wọn yìí, ṣíṣe ètò ìdìbò lábẹ́ tàbí ìpèsè owó fún èyíkéyìí nínú wọn láti àpò ìjọba àpapọ̀ kò tọ̀nà sí òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
“Nítorínáà, láti isinsinyi, má ṣe ètò owó kankan láti àpò ìjọba àpapọ̀ fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ yìí tàbí Ìpínlẹ̀ míràn tó tápà sí òfin náà títí di ìgbà tí wọn yóò fi padà sí ìjọba ìbílẹ̀ tí òfin gbà láàyè ní ìbámu pẹ̀lú apá kinni ìṣètò àkọ́kọ́ tí ìwé òfin yìí.”
Lẹ́yìn àṣẹ yìí, àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ tí òfin yìí bá wí gba oun tí òfin sọ ṣùgbọ́n ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó lọ sí ilé ẹjọ fún atunpalẹ ọ̀rọ̀ náà.
Yemi Osinbajo, agbẹjọro fún ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó nígbà náà jiyàn pé ní abala ejileniọgọjọ, apa kẹrin àti ikarun ti ìwé òfin ọdún 1999, agbára àṣẹ lásán ni Obasanjo ní, kò ní ti ṣíṣe òfin tàbí láti túmọ̀ òfin, débi tí yóò dá owó fífún ijoba ìbílẹ̀ dúró.
Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ dá ẹjọ́ pé Obasanjo kò ní agbára láti dá owó ìjọba ìbílẹ̀ láti ọwọ ìjọba àpapọ̀ dúró. Ilé ẹjọ́ náà tún pá ní àṣẹ pé kí wọn fún Ìpínlẹ̀ Èkó ní owó náà.
Àmọ́sá, ìdájọ́ yìí kò ṣe idanimọ àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tuntun tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó dá silẹ yìí.
Ìjọba àpapọ̀ se àìgbọràn sí ìdájọ́ náà, ó dá owó fífún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Èkó dúró láti oṣù kẹrin ọdún 2004 títí di ìparí ìjọba Tinubu ati Obasanjo. Ìjọba àpapọ̀ lábẹ́ ìṣàkóso Ààrẹ Umar Musa Yar’adua, ẹni tí ó se ìjọba lẹhin Obasanjo fún ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó ní owó náà.
TheCable bá Muda Yusuf sọ̀rọ̀. Ó jẹ́ olùdarí Lagos Chamber of Commerce and Industry (LCCI) tẹ́lẹ̀rí láti jẹrisi àhesọ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó kò gba owó kankan láti àpò ìjọba àpapọ̀.
“Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Èkó ni ìjọba àpapọ̀ kò fún ní owó kankan. Wọn fun ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó fúnra rẹ ní owó” onímọ̀ nípa ọrọ̀ ajé yìí ni ó wí báyìí.
Data láti ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ (Central Bank of Nigeria -CBN) ti orílẹ̀-èdè Nàìjíría fihàn pé Ìpínlẹ̀ Èkó gba biliọnu mọkanlaleniẹẹdẹgbẹrìn mílíọ̀nù (N11.7 billion) èyí tí ó jẹ owó tí ìjọba àpapọ̀ máa ń fún àwọn ìjọba Ìpínlẹ̀ àti àwọn ìjọba ìbílẹ láti se àtìlẹ́yìn fún wọn ní ọdún 2001. Àwọn ọna asopọ sí ayélujára tí CBN ti yóò fi iye tí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó gbà ní àárín ọdún 1999 ati 2007 ni ìgbà tí Tinubu jẹ Gómìnà, ni a kò rí mọ́.
Data tí a rí gbà láti ọ́fíìsì olùṣirò àgbà Nàìjíríà (Office of the Accountant-General of the Federation-OAGF), BudgIT, nínú ìwé data tí ìpínlẹ̀ Èkó tí wọn tẹ jáde ní ọdún 2018, ló ṣàfihàn pé ìpínlẹ̀ Èkó gba ìpín mejidinniaadọta biliọnu ó lé ní miliọnu mejileniọgọta(N48.62 billion) láti apo ìjọba àpapọ̀ ní ọdún 2007 ki Tinubu tó gbé ìjọba silẹ.
Àbájáde
Kò sì ìgbà kankan lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba Tinubu tí ìpínlẹ̀ Èkó kò rí owó tí ìjọba máa ń fún àwọn ìjọba àti ijoba ìbílẹ̀ gbà. Àwọn Ìjọba ìbílẹ Ìpínlẹ̀ Èkó nikan ni ìjọba àpapọ̀ kò fún ní owó ní ọdún 2004 si 2007. Irọ́ ni àhesọ pé ìpínlẹ̀ Èkó kò rí owó gbà láti àpò ìjọba àpapọ̀.
Ǹjẹ́ ìpínlẹ̀ Èkó rí ẹẹdẹgbẹrin mílíọ̀nù náírà gẹ́gẹ́bí IGR- Internally Generated Revenue, owó tí Ìpínlẹ̀ Èkó fúnra rẹ pa ni ọdún 1999 bi Shettima ti wí?
Shettima sọ pé Èkó rí ẹẹdẹgbẹrin mílíọ̀nù náírà gẹ́gẹ́bí IGR ni ọdún 1999 àti wí pé owó náà ti di oókànléláàádọ́ta biliọnu náírà ní oṣù.
Àbájáde wa nìyí
Gẹ́gẹ́bí data tí ó ti ọdọ CBN wá tí wọn tọkasi nínú ìwé àkọsílẹ̀ ti Research Academy of Social Sciences, ìpínlẹ̀ Èkó rí biliọnu mẹrinla naira gẹ́gẹ́bí IGR ni ọdún 1999, èyí tó túmọ̀ sí pé Ìpínlẹ̀ náà ń rí biliọnu kan l’oṣù (N1.2 billion).
Èyí yàtọ̀ sí ẹẹdẹgbẹrin mílíọ̀nù náírà tí Shettima sọ àti ẹgbẹta mílíọ̀nù náírà tí àwọn oníròyìn ń gbé ká.
Ní ìgbà tí Tinubu gbé ìjọba silẹ ni ọdún 2007, Èkó bẹ̀rẹ̀ sí í rí ẹ̀taléníọgọ́rin biliọnu náírà (N83. 02 billion) èyí tí ó jẹ biliọnu mẹfa l’oṣù (N6.9 billion). Láàrin ọdún 1999 si 2007, ìdàgbàsókè IGR ìlú Èkó jẹ́ ìpín ọọdunrun lé ní àádọ́rin dín ní méjì àti ẹtaleniọgọta(468.63 percent), èyí tó túmọ̀ sí àfikún tó jọjú.
Akinyemi Ashade, kọmíṣọ́nnà tẹ́lẹ̀rí nípa ètò ìnáwó ní ìpínlẹ̀ Èkó sọ pé ní ọdún 2018, IGR olosoosu ti ìlú Èkó jẹ́ biliọnu mẹrinleniọgbọn (N34 billion).
Tí a bá ní kí a se data IGR tí àjọ ètò ìṣirò-National Bureau of Statistics (NBS) gbé jáde ní aipẹ yii, àkọsílẹ̀ wọn fún idakeji ọdún 2021 fihàn pé ìpínlẹ̀ Èkó rí biliọnu igba àti àádọ́rin dín ní mẹta náírà (N267 billion) ní oṣù kẹfà àkọ́kọ́ ọdún 2021, èyí tó túmọ̀ sí pé ìpínlẹ̀ Èkó rí biliọnu mẹrinleniogoji àti ẹẹẹdẹgbẹta miliọnu náírà (N44.5 billion)-kìíse ookanlelaadọta biliọnu naira (N51 billion) tí Shettima wí.
Àbájáde
IGR ìpínlẹ̀ Èkó ni ọdún 1999 nígbà tí Tinubu jẹ Gómìnà kìíse ẹgbẹta mílíọ̀nù l’oṣù (N600m) bí ìròyìn tí wí bẹẹ sì ni kìíse ẹẹdẹgbẹrin mílíọ̀nù (N700m) tí Shettima sọ. IGR ìpínlẹ̀ Èkó lọ́wọ́lọ́wọ́ kìíse oókànléláàádọ́ta biliọnu náírà. Ṣùgbọ́n, ní osoosu, Èkó ń rí biliọnu mẹrinlelogoji àti ẹẹẹdẹgbẹta miliọnu náírà. Irọ́ ni àhesọ méjèèjì.
Ṣé lóòtó ni wí pé ìlú Èkó ló ní ọrọ ajé kẹta tó tóbi jùlọ ní Áfíríkà?
TheCable ṣewádìí àhesọ yìí ti Shettima àti Tinubu sọ nípa ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Èkó. Shettima sọ pé ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Èkó ni ìkẹta tó tóbi jùlọ, Tinubu ní òun ló tóbi jù.
Láti mọ̀ nípa bí ọrọ ajé orílẹ̀-èdè kan ṣe tó, Muda Yusuf, olùdarí LCCI-Lagos Chamber of Commerce and Industry tẹ́lẹ̀rí sọ pé, Gross Domestic Product (GDP) jẹ oun kan pàtàkì tí wọn máa ń fi se oṣuwọn ọrọ ajé tàbí mọ bí ọrọ ajé ṣe tó.
“GDP per capita tí máá ń pín ọjà abẹle pẹ̀lúpẹ̀lú iye ènìyàn tó wà ní ìlú ni wọn fi máa ń se oṣuwọn nítorí ó máa ń ṣ’afihan bí àwọn ènìyàn ṣe ń ṣe dáadáa sí,” Yusuf ló sọ báyìí.
“Ìpínlẹ̀ Èkó kò ní owó bí àwọn ènìyàn ti ń rò, torí bukata ti pọju, tí a bá wo iye owó tí Ìpínlẹ̀ Èkó ń rí pẹ̀lú iye àwọn ènìyàn tí ó nílò ìtọ́jú. Oun tó yẹ ká béèrè ni, ṣé àwọn ènìyàn ń gbé ìgbé ayé tí ó dára nínú ọrọ ajé yìí?”
Ni ọdún 2020, àjọ tí ó ń ṣe ètò ìṣirò ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Lagos Bureau of Statistics (LBS) se àyẹ̀wò lórí ìlú tó lowo julọ ní ilẹ Áfíríkà niti àpapọ̀ ọrọ ajé ìlú nípa dọla. Àpapọ̀ ọrọ̀ ajé ìlú Èkó jẹ biliọnu mẹrindinniọgọrin($76 billion), ó sì wà ní ipò kẹrin. Àpapọ̀ ọrọ ajé ìlú Cairo jẹ biliọnu mejila-le-ni-igba ($212 billion) èyí tí ó túmọ̀ sí pé Cairo ni ìlú tó ní ọrọ ajé tó tóbi jùlọ ni ilẹ̀ Áfíríkà, Johannesburg ni ó tẹle pẹ̀lú ($131 billion) tí Cape Town pẹ̀lú $121 billion sì wà ní ipò kẹta.
Tí Ìpínlẹ̀ Èkó bá jẹ́ orílẹ̀-èdè
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àpapọ̀ ọrọ ajé ìlú Èkó kéré sí ti àwọn ìlú kan ní Áfíríkà, Ìpínlẹ̀ Èkó figagbágà pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè nípa ọrọ ajé.
Nínú àkọsílẹ ọdún 2021 rẹ, àjọ tí ó ń ṣe ètò ìṣirò tí Ìpínlẹ̀ Èkó fihàn pé àpapọ̀ ọrọ ajé ìpínlẹ̀ Èkó jẹ N26.59 triliọnu, to se déédé $61.9 billion tí a bá lo oṣuwọn pàṣípàrọ̀ ti ìjọba tó wà ní N429.43 ati $38.4 billion tí a bá lo N692 tí aladaani.
TheCable fi ìlú Èkó wé àwọn orílẹ̀-èdè míràn pẹ̀lú data ti ọdún 2021.
A lo oṣuwọn pàṣípàrọ̀ ti Ìjọba láti fi ṣe ìyípadà nọmba ti apapọ ọrọ ajé ìlú ti LBS ati NBS pèsè, a ríi wípé Èkó gbé ipò kọkànlá ní Áfíríkà àti ipò kẹrìndínlógún tí a bá lo oṣuwọn aladaani.
S/N | Country | GDP USD billion |
---|---|---|
1. | Nigeria | $440.7 billion |
2. | South Africa | $419.9 billion |
3. | Egypt | $404.1 billion |
4. | Algeria | $167.9 billion |
5. | Ethiopia | $111.2 billion |
6. | Kenya | $110.3 billion |
7. | Ghana | $77.5 billion |
8. | Angola | $72.5 billion |
9. | Cote d’Ivoire | $69.7 billion |
10. | Tanzania | $67.7 billion |
11. | Lagos | $61.9 billion (Official rate) |
12. | Congo | $53.9billion |
13. | Cameroon | $45.2 billion |
14. | Uganda | $40.4billion |
15. | Lagos | $38.4 billion (Parallel market) |
16. | Sudan | $34.3 billion |
17. | Senegal | $27.6 billion |
A mú nọ́mbà àpapọ̀ ọrọ ajé yìí láti ọdọ ilé ìfowópamọ́ àgbáyé, ṣùgbọ́n kò sí Ìpínlẹ̀ Èkó nibẹ, ti ìpínlẹ̀ Èkó wa láti ọdọ LBS.
Àbájáde
Ìpínlẹ̀ Èkó kọ́ ni ó gbé ipò kẹta láàrin àwọn ìlú tó ní ọrọ ajé tí ó tóbi jùlọ ní Afíríkà bí Tinubu ati Shettima ti wí.
Ṣíṣe àpèjúwe Èkó pẹ̀lú àwọn olú ìlú ní Áfíríkà, a ríi wí pé ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó fúnra rẹ gbà pé ipò kẹrin ni ọrọ ajé rẹ wà ní Afíríkà.