Fọ́nrán kan, èyí ti ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn ti pẹgan Abdulrahman Abdulrazaq, Gómìnà ipinlẹ Kwara, ni wọ́n ṣe atunpin rẹ sí orí ayelujara.
Nínú fídíò ọ̀ún, àwọn ènìyàn náà ń pe gómìnà náà ni olè, bí wọ́n se fi ariwo lée kúrò ní ibi àpéjọ kan.
Àwọn tó ṣ’atunpin fọ́nrán náà gbé àhesọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé láìpẹ́ yìí ni ìgbà tí gómìnà náà àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC-All Progressives Congress, ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́lọ́wọ́ ṣ’abẹwo si ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Kwara Polytechnic, fún ìwọ́de.
Ìkànnì kan lórí oun àmúlò ìgbàlódé fún ibaraẹnidọrẹ (Facebook), Peter Obi Support Group, gbé fídíò náà ni ọjọ́ ajé, àwọn olùmúlò ojú òpó sì ti wòó ní ọ̀nà ẹgbẹtala.
Ojú òpó kan tí a mọ̀ sí Nigeria Youth Movement, ṣ’atunpin fídíò náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìfòrí yìí: ‘Àwọn olóṣèlú tó kọ ẹgbẹ́ APC sílẹ̀ lọ sí ẹgbẹ́ òsèlú PDP, lé Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara danu, wọ́n sì ń pariwo ‘Sai Bukky Bukola Saraki’. Fọ́nrán náà ni àwọn olùmúlò ti wò ni ọna ẹgbẹ̀run ó lé igba, lati ọjọ́ Ìṣẹ́gun
Yàtọ̀ sí Facebook, wọ́n pín fídíò náà sí orí YouTube, WhatsApp àti TikTok.
Ojú òpó kan l’órí Youtube, E-vibez TV, pín fídíò náà l’ọjọ́ ajé pẹ̀lú àhesọ pé gómìnà Abdulrazaq ń gbinyanju láti ṣe ìpolongo ìdìbò ṣáájú ìbò àpapọ̀ ọdún 2023. Àwọn olùmúlò wo fídíò náà ní ọna ọgọ́rùn-ún dín ní ẹgbàárin.
Isaridaju
TheCable lo InVID, ẹ̀rọ ìgbàlódé tí máa ń ṣe ìwádìí orísun fọ́nrán, láti fi ìdí òdodo múlẹ̀, a ríi wí pé fídíò náà ti wà lórí ayélujára l’áti ọdún 2018.
Ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n pín fídíò náà sí orí YouTube, Kwara Gist, ni oṣù kejìlá ọdún 2018, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìfòrí yìí: “iruju bẹ sílẹ̀ ní Ilorin, ni ibi àpéjọ ọlọdọọdun ti Ilorin Emirate Progressive Descendant Union (IEPDU), àwọn ọmọlẹyìn Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Bukola Saraki, fi ipá gba ìṣàkóso àpéjọ náà.”
Ní ọjọ́ kẹsán, oṣù kẹjọ, ọdún yìí, ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara, fèsì sí fídíò náà nínú atẹjade kan lórí oun àmúlò ìgbàlódé fún ibaraẹnisọrẹ, Facebook.
Bashir Adigun, olùdámọ̀ràn nípa ètò ìròyìn òṣèlú si Gómìnà, ló buwọ́lù atẹjade náà pẹ̀lú àkọ́lé yìí: “Fídíò èké nípa Gomina AbdulRazaq: ṣíṣe ìrántí ọjọ́ ìbí ní ìlú Kwara.”
Adigun sọ wí pé fídíò náà ti wà lórí ayélujára láti ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kejìlá, ọdún 2018, ni ìgbà tí àwọn agbéró àti ọmọlẹ́yìn Bukola Saraki, ààrẹ ilé aṣòfin àgbà nígbà náà, se aibikita, wọ́n sì kó rudurudu ba àpéjọ tí Ilorin Emirate Descendants Progressive Union (IEDPU) ṣètò.
Adigun sọ wí pé, wọ́n ya fídíò náà ní ìgbà tí gómìnà ṣi jẹ́ olùdíje, tí ó sì lọ àpéjọ náà gẹgẹbi àlejò pàtàkì tí ìlú abinibi rẹ̀.
Ó fi kún wí pé , àpéjọ kankan kò wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Ìpínlẹ̀ Kwara (Kwara State polytechnic) ní ọjọ́ keje, oṣù kẹjọ, ọdún 2022, ti Gómìnà náà yóò fi wà níbẹ̀.
Ó ní, “ẹni ibi ni àwọn tó ṣ’atunpin fídíò náà, wọn fẹ́ kí àwọn aráyé gbàgbọ́ pé àwọn ènìyàn pẹgan gómìnà tó ń darí ìjọba lọ́wọ́.”
Àbájáde Ìwádìí
Aṣinilọ́nà ní fọ́nrán akálékáko tó ṣ’afihan bi ọgọọrọ ènìyàn ṣe ń pẹgan Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara. Fídíò náà ti pẹ gan-an, wọ́n sì ti gbáà sílẹ̀ láti ọdún 2018.