Matthew Kukah, ojisẹ Ọlọ́run, ẹni tí ó tún jẹ́ bisọọbu fún Sokoto diocese sọ pé Ààrẹ Bọla Tinubu kò fọwọ́ sí ìwé nígbà tí wọ́n ṣe eto agbekalẹ fún àlàáfíà nígbà ìdìbò fún Ipò Ààrẹ ní ọdún 2023.
Kukah sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ ìsinmi nígbà ìpàdé fún ààbò fún ìdìbò ní Ìpínlẹ̀ Edo tí wọ́n se ní ilé ìpàdé kan ní Benin City, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Edo.
“Lára àwọn nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ ni pé Ààrẹ Tinubu nígbà tí ó ń díje fún Ipò Ààrẹ kò fọwọ́ sí ìwé akònífawàhálà. Kìí se ẹ̀bi wa pé àwọn ẹgbẹ́ òsèlú alátakò kò fọwọ́ sí ìwé akònífawàhálà,” bisọọbu yìí ló sọ báyìí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Lára wọ́n sọ pé ọ̀rọ̀ tí bisọọbu sọ yìí kò rí bẹ́ẹ̀.
ÈTÒ FÚN ÀLÀÁFÍÀ NÍGBÀ ÌDÌBÒ NÍ NÀÌJÍRÍÀ
Nítorí àwọn ohun tí kò dára tó ṣẹlẹ̀ kí ìdìbò ọdún 2015 tó wáyé, ijọba Nàìjíríà se agbekalẹ igbimọ fún àlàáfíà (National Peace Committee-NPC) ní ọdún 2014 láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn dibo láìsí wàhálà.
Abdulsalami Abubakar, olórí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ ló jẹ́ olórí igbimọ yìí. Wọ́n tí ṣètò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò àlàáfíà nígbà ìdìbò tẹ́lẹ̀.
Ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kẹsàn-án, ọdún 2024, àwọn ará Edo máa dìbò wọ́n fún Adijedupo fún Ipò Gómìnà tí wọ́n bá fẹ́.
Àmọ́sá, ààbò àwọn olùdìbò ti kọ àwọn ènìyàn lóminú lẹ́hìn ìgbà tí ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party (PDP) kọ̀ láti fọwọ́ sí ìwé pé àwọn kò ní fa wàhálà.
PDP sọ pé àwọn kò fọwọ́ sí ìwé náà nítorí pé àwọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú ètò náà.
Godwin Obaseki, gómìnà Ìpínlẹ̀ Edo fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún ẹgbẹ́ òsèlú All Progressives Congress (APC), lẹ́hìn ìgbà tí àwọn ọlọ́pàá mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú PDP mẹwa tí Obaseki ní wọ́n mú lai sí ìdí pàtó tí wọ́n fi mú wọ́n.
Nígbà tí Kukah ń sọ̀rọ̀ nípa kíkọ̀ tí PDP kọ̀ láti fọwọ́ sí ìwé pé kò ní sí wàhálà nígbà ìdìbò yìí, ó ní pé èyí kìí se ìgbà àkọ́kọ́ tí Adijedupo máa kọ̀ láti fọwọ́ sí ìwé pé àwọn kò ní fa wàhálà nígbà ìdìbò.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ
TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára se àyẹ̀wò àbájáde ètò igbimọ fún àlàáfíà ti ọdún 2023 tí NPC se agbekalẹ rẹ̀. A ríi pé ètò irú èyí ti wáyé lẹ́hìn ìgbà tí ètò ìdìbò méjì di wàhálà ní Nàìjíríà.
Ètò àlàáfíà àkọ́kọ́ wáyé láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ kópa nínú ìdìbò àti àwọn ẹgbẹ́ òsèlú lè ṣe àwọn nǹkan tí Òfin fàyè gbà.
Àwọn Adijedupo fọwọ́ sí ìwé fún àlàáfíà/akonifawahala nígbà ìdìbò ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kẹsàn-án, ọdún 2022.
Àwọn Adijedupo fún Ipò Ààrẹ kó ara jọ ní International Conference Centre (ICC), Abuja láti lè fọwọ́ sí ìwé pé àwọn kò ní fa wàhálà nígbà ìdìbò.
Peter Obi, ẹni tí ó jẹ́ Adijedupo fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú Labour Party (LP), Atiku Abubakar, Adijedupo fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú PDP, Rabiu Kwankwaso, Adijedupo fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú New Nigeria Peoples Party (NNPP) àti Ọmọyẹle Ṣoworẹ, Adijedupo fún Ipò Ààrẹ fún ẹgbẹ́ òsèlú African Action Congress (AAC) wà sí ICC láti fọwọ́ sí ìwé. Tinubu nìkan ni kò sí níbẹ̀. Wọ́n ní ó wà ní United Kingdom.
Kashim Shettima, ẹni tí Tinubu yàn láti jẹ́ igbá-kejì rẹ̀ ló sojú rẹ̀ ní ICC. Àwọn ilé isẹ ìròyìn mìíràn kọ ìròyìn nípa ìfọwọ́síìwé ètò àlàáfíà àkọ́kọ́ ti ọdún 2022, bí ó ṣe wà níbí, níbí àti níbí.
Ètò àlàáfíà kejì èyí tí wọ́n fọwọ́ sínú ìwé fún wáyé ní ọjọ́ kẹtalelogun, oṣù kejì, ọdún 2023. Èyí sọ pé kí àwọn Adijedupo gba èsì ìdìbò bí ó bá se rí.
Tinubu wà níbi tí wọ́n ti fọwọ́ sí ìwé nígbà ètò àti dẹ́kun wàhálà kejì yìí.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Tí a bá wo ẹ̀rí tí ó wà lọ́wọ́ wá, ọ̀rọ̀ tí Kukah sọ pé Tinubu kò fọwọ́ sí ìwé fún àlàáfíà nígbà ìdìbò ọdún 2023 kìí se òótọ́.