Àwọn àtẹ̀jáde tó ń tàn ràn-ín l’orí ayélujára gbé àhesọ kan pé Akinwunmi Ambode, gómìnà ìpínlè Èkó tẹĺẹ̀rí ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ ́òṣèlú àwọn òṣìṣẹ́.
Àtẹ̀jáde náà sọ pé gómìnà ìpínlè Èkó tẹ́lẹ̀ rí náà fẹ́ díje fún ipò gómìnà ni ọdún 2023 labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn òṣìṣẹ.
https://twitter.com/FRNCitizens/status/1544942524497797121?ref_src=twsrc%5Etfw%7Ctwcamp%5Etweetembed%7Ctwterm%5E1544942524497797121%7Ctwgr%5E%7Ctwcon%5Es1_&ref_url=https%3A%2F%2Fwww.thecable.ng%2Fwp-admin%2Fpost.php%3Fpost%3D721997action%3Deditclassic-editor
Former Governor of Lagos State, Akinwumi Ambode dumps his boss Tinubu, Picks Labour Party Gubernatorial Ticket
The Game Is Getting More Interesting..🙄🔥☀️ pic.twitter.com/d2ztc8TDou
— Adoba Wisdom Daniel (@DanielAdoba) July 7, 2022
Ní ọjọ́ karún, oṣù keje,Leadership Scorecard, ilé ìwé ìròyìn kan gbe àhesọ yìí, pẹ̀lú àtẹ̀jáde tí a lérò pé ó wá láti ọdọ Ambode, èyí tí o gba àwọn ọ̀dọ́ ni ìmòrán pé kí wọ́n gba káàdì ìdìbò àlálòpẹ́, ṣáájú ìdìbò tó ń bọ̀.
“Àwọn ọ̀dọ́ ń bọ̀. Agbára wà lọ́wọ́ wọn. Ẹ lọ gba káàdì ìdìbò àlálòpẹ́ yín. Ọjọ́ iwájú yín ti sún mọ́lé.”
Ní ọjọ́ keje, awuyewuye lórí àhesọ pé Ambode fi ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Party (APC), èyí ní ẹgbẹ́ tí ń ṣe ìjọba àpapọ̀ lọ́wọ́ sílẹ tàn rán-ín lóri Twitter, ìkànnì abẹ́yẹfò.
Ifiidiododomulẹ
Ìwádìí orí ayélujára fihàn pé àtẹ̀jáde tí ó ti pẹ gan ni àtẹ̀jáde tó gbe ìmọ̀ràn Ambode fun àwọn olólùfẹ́/ọmọléyìn rẹ̀ wí pé kí àwọn ọdọ lọ gbà káàdì ìdìbò àlálòpẹ́ wọn. Ọjọ kínní oṣù kejì ọdún yí ni ó fi àtẹ̀jáde náà sí ojú òpó abẹ́yẹfò rẹ̀.
A tún ṣ’àyẹ̀wò ojú òpó gómìnà tẹ́lẹrí náà lórí Twitter, Facebook àti Instagram, a ríi wí pé kò sí ìkéde kankan pé Ambode fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀, fún ẹgbẹ́ alátakò àwọn òṣìṣẹ́.
Tí ọ̀rọ̀ yìí bá jẹ́ òótó, àwọn ilé ìròyìn tó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé á ti gbé ìròyìn náà sùgbọ́n kò sí òun tó jọ bẹ́ẹ̀.
TheCable kàn sí olùrànlọ́wọ́ Ambode àti Julius Abure, alága ẹgbẹ́ Labour Party, ṣùgbọ́n wọn kò fèsì sí ìpè àti ìfọ̀rọ̀ránṣẹ́. A ó sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí gan-an tí wọn bá ti dá wa lóhùn.
Ilé iṣẹ́ ìròyìn, Premium Times bá Ifagbemi Awamaridi, ẹni tí ó jẹ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn òṣìṣẹ́ jomitoro ọ̀rọ̀ ni ẹkún Èkó. Óní irọ́ ní àhesọ pé gómìnà tẹ́lẹ̀rí náà ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn òṣìṣẹ.
Ó ní “Ambode ṣì wà ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ẹgbẹ́ tó ń ṣe àkóso ìjọba lọ́wọ́ lọ́wọ. Kódà, Ambode jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ tọkàn tọkàn, o sì tun farajì, yóò ṣiṣẹ́ fún àṣeyọrí àwọn tó ń díje dupò ní ijoba Ìpínlẹ̀ Èkó ni abẹ́ òsèlú APC àti ìjọba àpapọ̀.”
Àbájáde ìwádìí
Irọ́ gbáà ni àhesọ wí pé Ambode darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn òṣìṣẹ.