Ẹni kan tí ó ń lo ohun ibaraẹnise ìgbàlódé orí ayélujára sọ pé Donald Trump, aàrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, fẹ́ dá àwọn ènìyàn mílíọ̀nù mẹta àti ẹgbẹ̀rún ni ọ̀nà ẹẹdẹgbẹrìn àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà “tí wọ́n ń gbé ní Amẹ́ríkà ní ọ̀nà tí kò bá òfin mu” padà sí Nàìjíríà.
Ọ̀rọ̀ yìí, tí ó sọ lọ́jọ́ ajé, ogunjọ, oṣù kìíní, ọdún 2025, ọjọ́ tí wọ́n búra fún Trump láti di Ààrẹ, sọ pé dídá àwọn ènìyàn padà sí orílẹ̀ èdè wọn yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kejì tí wọ́n búra fún Trump.
“Donald Trump, ènìyàn mi, ọlọ́lá jùlọ, máa dá àwọn ènìyàn yìí tí wọ́n ń gbé ní Amẹ́ríkà lọ́nà tó lòdì sí òfin padà sí orílẹ̀ èdè wọn ní ọlá. Wo ẹni àkọkọ́ tí wọ́n máa dá padà lórí àkójọ yìí,” @Zaddy_Bruh, ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ yìí, tí asia orílẹ̀ èdè Russia wà ní ẹgbẹ orúkọ rẹ̀ lórí ohun ibaraẹnise ìgbàlódé alámì krọọsi (X) ti orí ayélujára, tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀, fi ọ̀rọ̀ náà síta kí àwọn ènìyàn tó ń tẹ̀lée lè ríi kà.
Gẹ́gẹ́bí ẹni yìí se wí, Nàìjíríà wà ní ipò kẹta nínú àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́jọ tí Amẹ́ríkà fẹ́ dá àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè wọn padà sí orílẹ̀ èdè wọn. Ẹni yìí sọ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ta àti ẹẹdẹgbẹrin ni Amẹ́ríkà fẹ́ dá padà sí Nàìjíríà.
Orílẹ̀ èdè Zimbabwe ni ó wà ní ipò kẹrin. Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí tí Amẹ́ríkà fẹ́ dá padà sí Zimbabwe jẹ ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹẹdẹgbẹrin àti marunlelọgọta, ti orílẹ̀ èdè Ghana jẹ́ mílíọ̀nù kan àti ìgbà, ti orílẹ̀ èdè Mozambique jẹ́ àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rùn-ún àti mẹtalelogun, ti orílẹ̀ èdè Bangladesh jẹ́ àwọn ènìyàn mílíọ̀nù méjì ó dín ní ọgọrùn-ún, báyìí ni ẹni yìí se wí.
Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Brazil tí ẹnì yìí ní Amẹ́ríkà fẹ́ dá padà sí orílẹ̀ èdè wọn jẹ́ mílíọ̀nù méje ó dín ní ọgọ́rùn-ún, ti orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo (DRC) jẹ́ mílíọ̀nù méjì àti ọgọ́rùn-ún, ti orílẹ̀ èdè Mexico jẹ́ mílíọ̀nù mẹtadinlogun àti ẹgbẹrin.
Àwọn orílẹ̀ èdè yìí kò tẹ̀lé ara wọn. Àmọ́, Nàìjíríà ni ẹni yìí kọ́kọ́ dárúkọ.
Láti ìgbà tí ẹni yìí ti fi ọ̀rọ̀ yìí síta, àwọn ènìyàn mílíọ̀nù méjì àti ẹẹdẹgbẹrin ló ti wo/rí ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹrindinlogun ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjì ló pín ín, àwọn ènìyàn egbèje ló fi pamọ, àwọn ènìyàn ẹẹdegbeje ló sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí sọ pé ẹ̀rù ń ba àwọn.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ THECABLE NEWSPAPER SE
Kí ó tó se aseyege nínú ètò ìdìbò nínú oṣù kọkànlá, ọdún 2024, tó fi di Ààrẹ, Trump sọ pé ohun yóò fi òfin de bí àwọn ènìyàn láti orílẹ̀ èdè mìíràn se máa ń wọ tàbí wá sí Amẹ́ríkà ní ọ̀nà tí kò bófin mú.
Ààrẹ Amẹ́ríkà yìí tí máa ń sọ pé àwọn àjèjì tí wọn máa ń wá sí/wọ Amẹ́ríkà lọ́nà tí kò yẹ yìí máa ń jẹ́ kí ìwà tí kò dára tàbí àṣemáṣe pọ̀ sí ní Amẹ́ríkà.
Nígbà tí wọ́n ń búra fún un, ó pa àwọn àṣẹ kan ti wọn yóò di òfin, tí wọ́n yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí ní mú lo lẹsẹkẹsẹ ní ọjọ́ kinni tó bá di Ààrẹ.
Lára àwọn ohun tí wọ́n máa di òfin yìí ni ètò pàjáwìrì tí yóò fi òfin de bí àwọn ènìyàn se ń gba ààlà (border) tó wà láàárín Mexico àti Amẹ́ríkà wọ/wá sí Amẹ́ríkà àti pípa àṣẹ pé kí àwọn tí yóò máa sọ ààlà náà bẹ̀rẹ̀ sí ní mojuto ohun tí kò dára yìí.
“A máa dá gbogbo wíwọ Amẹ́ríkà lọ́nà tí kò dára dúró. A sì máa bẹ̀rẹ̀ ètò láti dá àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù tí ìwà wọn kò bá òfin mu padà sí ibi tí wọ́n ti wá,” báyìí ni ẹni yìí sọ pé Trump se wí.
Ààrẹ náà tún sọ pé ìjọba dá ètò kan tí wọn ń pè ní “Remain in Mexico” padà síbí wọ́n se máa ń ṣeé, èyí tí ó sọ pé kí àwọn ènìyàn ti wọ́n ń wá ibi ààbò sì dúró ní Mexico nígbà tí wọ́n bá ń ṣètò wíwá sí Amẹ́ríkà.
Trump kò dárúkọ orílẹ̀ èdè kan. Àmọ́, àwọn ènìyàn ríi/mọ̀ pé kò fẹ́ràn àwọn ènìyàn tí wọ́n wá sí tàbí ń gbé ní Amẹ́ríkà lọ́nà tí kò bófin mú.
Gẹ́gẹ́bí àbájáde ètò kan tí Migration Policy Institute (MPI) se sọ ní ọdún 2024, bíi àwọn ènìyàn mílíọ̀nù mẹrindinlaadọta ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba tí wọ́n wá láti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ni wọ́n ń gbé ní Amẹ́ríkà.
Atẹjade ọdún 2024 yìí wá láti ọwọ US Census Bureau. Àwọn ohun tí wọ́n lo láti mọ iye àwọn ènìyàn tó wá láti orílẹ̀ èdè mìíràn yìí wá láti inú 2022 American Community Survey (ACS), 2023 Current Population Survey (CPS), 2000 Decennial Census àti US Department of Homeland Security (DHS).
Àwọn ohun kan tí a lè rí kà tí DHS ṣẹ̀ṣẹ̀ fi síta fi hàn pé àwọn Mexicans (àwọn ọmọ Mexico) tí ó jẹ́ mílíọ̀nù mẹrin àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹrin ó lé mẹwa nínú àwọn ènìyàn mílíọ̀nù mẹrindinlaadọta ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba tí wọ́n ń gbé ní Amẹ́ríkà ló jẹ́ ọmọ Mexico, ní ọdún 2022, eléyìí tí ó jẹ́ ìyè àwọn ènìyàn tó pọ̀jù tí ó ń gbé ní Amẹrika tí òfin kò fàyè gbà.
Lẹ́hìn Mexico, àwọn ènìyàn tí wọ́n tún pọ̀jù tó tẹ̀lé ìyè àwọn ọmọ Mexico tí wọ́n wá láti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn láti gbé ní Amẹ́ríkà ní ọ̀nà tí kò bá òfin mu wá láti orílẹ̀ èdè Guatemala, El Salvador àti Honduras.
Àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn lára àwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn ènìyàn ti wá láti gbé ní Amẹ́ríkà ní ọ̀nà tí kò bá òfin mu ni Philippines, Venezuela, Colombia, Brazil, India àti China.
Ní ọdún 2023, àwọn ohun tí a lè rí kà láti ọwọ United States Census Bureau fi hàn pé iye àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ń gbé ní Amẹ́ríkà jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀ta àti mẹrin ó lé mẹtadinlọgọrin.
Ó ṣe pàtàkì kí a mọ̀ pé dídá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní Amẹ́ríkà ní ọ̀nà tí kò bá òfin mu padà sí orílẹ̀ èdè wọn jẹ́ ìlànà tí kò lè ṣeé parí tàbí yanjú ní ọjọ kan bí @Zaddy_Bruh ṣe sọ.
Amẹ́ríkà lè ní kí US Immigration and Customs Enforcement (ICE) fi ẹni tí ó ń gbé ní Amẹ́ríkà lọ́nà tí kò bá òfin mu sí àtìmmọ́lé kí wọ́n tó dá ẹjọ́ rẹ̀ tàbí dáa padà sí ibi tí ó ti wá sí Amẹ́ríkà.
Lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n bá fi irú ẹni yìí sí àtìmọ́lé, wọ́n lè ní kí ẹni yìí farahàn níwájú adajọ ní ilé ẹjọ́ tí wọ́n ti ń dá ẹjọ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n wá sí Amẹ́ríkà lọ́nà tí kò bá òfin mu nígbà tí wọ́n ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa dá irú ẹni yìí padà sí orílẹ̀ èdè tí ó ti wá sí Amẹ́ríkà.
Ní àfikún, kò tíì sí ẹ̀ka ìjọba kankan tí ó ti sọ ọ̀rọ̀ tó jọ mọ pé àwọn yóò dá àwọn ọmọ Nàìjíríà tí iye wọn jẹ́ mílíọ̀nù mẹta àti ẹẹdẹgbẹrìn padà sí Nàìjíríà bí @Zaddy_Bruh se wí. Àwọn ilé isẹ ìròyìn tí wọ́n dangajiya tàbí tí àwọn ènìyàn ní ìgbàgbọ́ nínú isẹ wọn kò tíì sọ ọ̀rọ̀ kankan nípa ọ̀rọ̀ yìí.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Kò sí àrídájú tí ó sọ pé Trump tí pàṣẹ pé kí Amẹ́ríkà dá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní Amẹ́ríkà lọ́nà tí kò bá òfin mu padà sí orílẹ̀ èdè wọn.