Àkọkà/atẹsita kan tí àwọn ènìyàn ń pín ní orí ayélujára sọ pé àwọn ènìyàn fi bẹ́ẹ̀ máa ń ní àìsàn rọpárọsẹ̀ tí wọ́n bá ń wẹ̀ nítorí pé wọ́n ń wẹ̀ “ní ọ̀nà tí kò yẹ” nípa pé wọ́n kọ́kọ́ máa ń da omi sórí kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ní wẹ̀.
Àkọkà yìí sọ pé ọ̀nà yìí máa ń fà kí ẹ̀jẹ̀ rú sí orí kíákíá tí ó sì máa fa àìsàn rọpárọsẹ̀.
“Gẹ́gẹ́bí áwon àyẹ̀wò tí àwọn ènìyàn ṣe káàkiri àgbáyé ṣe wí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ikú tàbí àìsàn rọpárọsẹ̀ nígbà tí àwọn ènìyàn bá ń wẹ̀ ń lé si ní ìgbà dé ìgbà. Gẹ́gẹ́bí àwọn dọ́kítà ṣe wí, ènìyàn gbọ́dọ̀ tẹ̀lé awon òfin kan tí ó bá ń wẹ̀,” báyìí ní àtẹ̀síta yìí ṣe wí.
“Tí ó kò bá wẹ̀ ní ọ̀nà tí ó yẹ, ìwọ náà yóò kú.”
Fídíò tí àwọn ènìyàn ń pín ká yìí fi kún-un pé àwọn dọ́kítà sọ pé àwọn ènìyàn kò gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ máa da omi sórí tí wọ́n bá fẹ́ wẹ̀ nítorí pé ó lè fa ki ẹ̀jẹ̀ lọ káàkiri ara, eléyìí sì lè fa àìsàn rọpárọsẹ̀, pàápàá jù lọ fún àwọn tí ó ní àìsàn ẹ̀jẹ̀ rírú, tàbí orí fífọ́ púpọ̀ gan-an lápá ibí kan lórí.
Ọ̀rọ̀ yìí sọ pé kí àwọn ènìyàn máa bẹ̀rẹ̀ ìwẹ̀ láti ẹsẹ̀, díẹ̀díẹ̀ dé orí.
Àyẹ̀wò tí TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe fi hàn pe wọ́n ti pín ọ̀rọ̀ yìí láti bíi ọdún 2019, nígbà tí olumulo ohun ìgbàlódé ìbáraẹniṣọ̀rẹ́ (facebook) kan tí a mọ̀ sí Mohammd Ullah, pin-in lórí ohun ìbáraẹnisọ̀rẹ́.
Olumulo míràn ní orí ohun ìbáraẹnisọ̀rẹ́ náà tún pín-in.
Wọ́n tún pín ọ̀rọ̀ náà ní ọdún 2020. Àwọn ènìyàn ọọdunrun ni ó fèsì sí ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ènìyàn aadọsan ni ó pín-in. Àwọn ènìyàn marun-undinlaadọrin ló sọ̀rọ̀ nípa ẹ.
Ní ọdún 2021 àti 2022, wọ́n pín ọ̀rọ̀ náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà.
Ní àwọn ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá, àwọn ènìyàn tún ń pín ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àwòrán kan náà ní orí ayélujára.
ÀWỌN OHUN TÍ Ó MÁA Ń FA ÀÌSÀN RỌPÁRỌSẸ̀ ÀTI ÀWỌN OHUN TÍ Ó LÈ FÀ FÚN ỌPỌLỌ
Gẹ́gẹ́bí àwọn tí ó máa ń dẹ́kun àìsàn ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (US Centre for Disease Control) se wí, àìsàn rọpárọsẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹ̀jẹ̀ tí ó bá ń lọ sí àwọn ibì kan ní ọpọlọ bá di tàbí kò lọ mọ́. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa ń jẹ́ kí ọpọlọ kú tàbí kí ó máa lè ṣíṣẹ dáadáa mọ́. Wọ́n ní ó lè fa kí ọpọlọ kú fún ìgbà pípẹ́, tàbí kí ó sọ ènìyàn di òní aibọ ara tàbí kí ó fa ikú.
TheCable lọ sí ààyè ayélujára (websites) àwọn elétò ìlera kan láti lè mọ àwọn ohun tí ó lè fa àìsàn rọpárọsẹ̀. Lára àwọn ààyè ayélujára tí a lọ ni UK national health service, Ilé-ìwòsàn Mayo (Mayo clinic) ati Johns Hopkins Medicine.
Lára àwọn nkan tí wọ́n mẹ́nubà ni àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru (hypertension or high blood pressure), ki ènìyàn sanra tàbí tóbi jù (obesity), àìsàn ìtọ̀ suga (diabetes), ọtí àmujù, wàhálà/iṣẹ́ àsejù (stress), ọjọ́ orí (age), àìsàn ìdílé (family history of health issues) àti ẹ̀yà (ethnicity) tí ènìyàn jẹ́.
Kò sí ààyè ayélujára kankan tí ó mẹ́nuba ‘wíwẹ̀ ní ọ̀nà tí kò yẹ’ bí ohun tí ó ń fa àìsàn rọpárọsẹ̀.
WÍWẸ̀ NÍ Ọ̀NÀ TÍ KÒ YẸ KÒ LÈ FA ÀÌSÀN RỌPÁRỌSẸ̀
Ọmọjowólọ Olúbùnmi, onímọ̀ nípa àìsàn rọpárọsẹ̀ ní òkè òkun (UK), sọ fún TheCable pé irọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí.
Ó sọ pé dída omi sórí máa ń jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ dìpọ̀ tàbí sún pọ̀ tàbí pín. Ó ní bí omi ṣe rí-bóyá ó gbóná tàbí tutù ló máa jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ ṣe bí yóò sese.
“Àmọ́sá, aisedeedee ẹ̀jẹ̀ nínú ọpọlọ ló máa ń fà àìsàn rọpárọsẹ̀. Bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń rìn lára kọ ló ń fàá. Bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń ṣe kò ní ohun kankan ṣe pẹ̀lú omi. Eléyìí túmọ̀ sí pé sayẹnsi (science) kò sọ paato nípa rẹ̀,” onímọ̀ àìsàn rọpárọsẹ̀ yìí ló sọ báyìí.
“Àìsàn rọpárọsẹ̀ kìí ṣẹlẹ̀ báyìí. Ó ní àwọn ìdí kan tí ó fi máa ń ṣẹlẹ̀. Kò ní nkankan ṣe pẹ̀lú bí ènìyàn ṣe wẹ̀, bóyá ó kọ́kọ́ da/bu omi sórí tàbí sí ẹsẹ̀. Kò yí ohunkóhun padà tàbí ní nkankan ṣe pẹ̀lú ẹ rárá.”
“Àwọn nkan tí ó máa ń fà Àìsàn rọpárọsẹ̀ ni ìṣòro bíi àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru, ìtọ̀ suga, èémí/mímí tí kò lọ déédéé. Kí ẹ̀jẹ̀ máa dá lọ sí ọpọlọ máa ń fa àwọn àìsàn rọpárọsẹ̀ kan.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Àhesọ ọ̀rọ̀ lásán-làsàn ni ọ̀rọ̀ pé tí ènìyàn bá kọ́kọ́ da omi sórí tí ó bá fẹ́ wẹ̀ lè fa àìsàn rọpárọsẹ̀.
Irọ́ gbáà ni.
Kò sí ìmọ̀ sayẹnsi tí ó sọ pé òótọ́ ni.