Àwọn atẹsita kan lórí àwọn ohun ibaraẹnise ìgbàlódé (social media) sọ pé Netflix (orí ohun tí wọn ti máa ń ṣe àfihàn fíìmù) ti yọ àwọn fíìmù tí Toyin Abraham, arábìnrin osere gbé jáde kúrò lórí ibi tí wọ́n ti ń gbé fíìmù jáde yìí.
Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù keje, ọdún 2024, ẹni kan tí a mọ sí @Kadunaresident, ara àwọn tí wọn máa ń lo ohun ìgbàlódé alámì krọọsi (X) tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀ sọ pé ibi tí wọ́n ti máa ń ṣe àfihàn fíìmù náà ti yọ àwọn fíìmù tí osere náà wà nínú rẹ̀ kúrò lórí Netflix.
“Kére o: mo gbọ́ pé Netflix ti yọ gbogbo àwọn fíìmù Toyin Abraham lónìí? Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ jọ̀wọ́ ṣe pẹ̀lẹ́. Ìyá ènìyàn kan ni,” báyìí ni ẹni yìí tí ó ń lo X ṣe kọ atẹsita náà.
Àwọn ẹgbẹ̀ta ó lé ní mẹrindinlogoji ẹgbẹ̀rún ènìyàn ló rí ọ̀rọ̀ náà. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti igba ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yì. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rin àti mẹ́jọ ló pín ín.
Àwọn ènìyàn pín ọ̀rọ̀ náà níbí àti níbí.
BÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢE RÍ
Abraham jẹ́ ìkan lára àwọn gbajumọ osere tí àwọn ènìyàn ti kàn ní àbùkù nítorí pé ó ti Ààrẹ Tinubu lẹ́hìn nígbà ìdìbò Ààrẹ ọdún 2023.
Àwọn ènìyàn fi ẹ̀sùn kan osere náà pé ó fi àwọn agbofinro mú ẹnì kan tí wọn ń pè ní Big Ayọ̀ tí ó máa ń ṣe iṣẹ́ kí àwọn ènìyàn lè mọ nǹkan síi ati ìyá rẹ̀ nítorí pé ó sọ ọ̀rọ̀ tí ó lè ba Abraham lórúkọ jẹ́.
Ayọ̀ fi ẹ̀sùn kan Abraham pé ó gba owó lọ́wọ́ Tinubu láti fi tọju orí ọkọ rẹ̀ tí a mọ̀ sí Kolawole Ajeyemi tí irun rẹ̀ ti pá jẹ se.
“Arábìnrin @toyin_abraham1, walai aiye ẹ ti tà! O gba owó Tinubu, o fi ṣe hair transplant fún ọkọ ẹ. Òpònú aláìnílàákàyè,” báyìí ni atẹsita yìí ṣe wí. Wọn ti yọ ọ̀rọ̀ náà kúrò lórí X.
Nígbà tí osere náà ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn ti máa ń pín àwòrán nǹkan tàbí ti ara wọn (Instagram), ó sọ pé ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe òótọ́. Ó ní òhun kò sọ pé kí àwọn agbofinro mú ìyá Ayọ̀. Ó sọ pé nǹkan tí òhun ṣe ni pé òhun fi ẹjọ́ náà sún àwọn ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí ìwà tí kò dára lórí ayélujára.
Ó ní òhun kò ní gbà kí àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ tí kò dára sí àwọn ọmọ òhun. Ó ṣe ìlérí pé òhun yóò dojú ìjà kọ àwọn tí wọn máa ń sọ̀rọ̀ òhun ní àìda ní orí ayélujára àti pé òhun yóò sì bá wọn fàá gan-an ni.
Ọ̀rọ̀ yìí bí àwọn ènìyàn nínú lórí X. Lára àwọn ènìyàn yìí sì kọ ìwé sì Netflix àti Prime Video (ibì kan mìíràn tí wọn ti máa ń ṣe àfihàn fíìmù lórí ayélujára) pé kí wọ́n yọ àwọn fíìmù rẹ̀ kúrò lórí àwọn ibi tí wọ́n ti ń fi fíìmù hàn yìí nítorí pé osere náà ‘lo agbára ní ọ̀nà tí kò yẹ.”
Ikan lára àwọn tí ó ń lo X fi lẹ́tà (ìwé) yìí hàn, ó sì ní kí àwọn ènìyàn má wo fíìmù osere náà. Àwọn ènìyàn mìíràn dá ẹ̀rù ba osere náà. Wọ́n ní pé àwọn yóò fi ẹjọ́ rẹ̀ sun àwọn tí wọn ni àwọn ohun ìgbàlódé ibaraẹnise (social media owners) tí àwọn agbofinro kò bá tú big Ayọ̀ sílẹ̀ ní àtìmọ́lé.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ
Láti lè mọ bóyá irọ tàbí òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí, TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe àyẹ̀wò bóyá Netflix ti yọ àwọn fíìmù osere yìí.
A ríi pé àwọn fíìmù tí osere náà wà nínú rẹ̀ bíi ‘Ijakumọ’, ‘malaika’, ‘prophetess’, ‘Elevator Baby’, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn sì wà lórí Netflix.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Netflix kò yọ àwọn fíìmù Abraham tàbí dá síse àfihàn àwọn fíìmù rẹ̀ dúró.