TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Ǹjẹ́ Nàìjíríà ni Orílẹ̀ èdè kẹfà tí àwọn ènìyàn ti ń gba ẹ̀mí ara wọn jù ní àgbáyé?
Share
Latest News
FACT CHECK: Is Nigeria 4th fastest-growing economy in the world in 2025?
FACT CHECK: How true are Obi’s claims about poverty rate in Nigeria, China and Indonesia?
FACT CHECK: No, Finnish court didn’t approve Simon Ekpa’s extradition to Nigeria
FACT CHECK: Is Cardinal Arinze eligible to be elected as the next Pope?
Rárá, Jonathan kò sọ pé Tinubu yóò se àṣeyọrí nínú ètò ìdìbò fún Ipò Ààrẹ ní ọdún 2027
A’a, Jonathan bai yi hasashen nasarar Tinubu a zaben shugaban kasa na 2027 ba
No, Jonathan no predict Tinubu victory for 2027 presidential election
Ḿbà, Jonathan ágbaghị àmà na Tinubu gà-èmérí ńtùlíáka ónyé ísíàlà ǹkè áfọ̀ 2027
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Ǹjẹ́ Nàìjíríà ni Orílẹ̀ èdè kẹfà tí àwọn ènìyàn ti ń gba ẹ̀mí ara wọn jù ní àgbáyé?

Yemi Michael
By Yemi Michael Published December 23, 2024 7 Min Read
Share

Adesanmi Akinsulore, profẹsọ (ọjọgbọn) ní Obafemi Awolowo University (OAU) àti Obafemi Awolowo University Teaching Hospital (OAUTH) (ilé ìwòsàn tí a ti ń kọ nípa ètò ìlera), ní Ilé ifẹ, ní Ìpínlẹ̀ Ọsun, sọ pé Nàìjíríà ni Orílẹ̀ èdè kẹfà tí àwọn ènìyàn ti ń gba ẹ̀mí ara wọn jù ní àgbáyé.

Gẹ́gẹ́bí ìwé ìròyìn Punch se wí, Akinsulore sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ibi idanilẹkọ, ètò kan tí Still Waters Mental Health Foundation se agbekalẹ rẹ̀ ní Ladoke Akintola University of Technology (LAUTECH), Ogbomoso, Oyo State.

Ó ní ìjọba gbọ́dọ̀ gbé igbesẹ gidi laifi àsìkò ṣòfò nípa ọ̀rọ̀ yìí, pàápàá jù lọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

“Ẹni kan gba ẹ̀mí ara rẹ̀ láàrin àwọn marunlelogun tí wọ́n gbé irú igbesẹ yìí. Ní ọdún 2021, gbígba ẹ̀mí ara ẹni jẹ́ nnkan kẹta tí ó fa ikú fún àwọn ọdọ tí ọjọ́ orí wọn kò ju ọdún mẹẹdogun sí ọdún mọkandinlọgbọn lọ ní àgbáyé”, báyìí ni wọ́n ní Akinsulore se wí.

“Ojúṣe gbogbo wa ni làti dojú kọ ìṣòro yìí. A gbọ́dọ̀ fọwọ́ so ọwọ pọ̀ láti se atilẹyin fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti kó ògo ayé já.”

ALAYE NÍPA KÍ ÈNÌYÀN GBA Ẹ̀MÍ ARA RẸ̀ 

Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ tí World Health Organization (WHO), àjọ eleto ìlera fún àgbáyé se sọ, iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ju ẹẹdẹgbẹta ẹgbẹ̀rún ni wọ́n gba ẹ̀mí ara wọn ní ọdọọdún. WHO sọ pé ikọọkan nínú àwọn ènìyàn yìí ló fẹ́ gba ẹ̀mí ara rẹ̀ bíi ìgbà ogún.

Àjọ yìí sọ pé gbígba ẹ̀mí ara ẹni jẹ ohun kẹrin tí ó máa ń fa ikú fún àwọn ènìyàn jù láàárín àwọn ènìyàn tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹẹdogun sí ọdún mọkandinlọgbọn (ọkùnrin àti obìnrin) ní gbogbo àgbáyé. WHO fi kún ọ̀rọ̀ wọn pé ìdá àádọ́rin pẹ̀lú mẹ́ta gbígba ẹ̀mí ara ẹni yìí máa ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn ènìyàn kò ti lowo lọ́wọ́.

Àwọn ohun tí ó lè fa kí ènìyàn gba ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ìrẹ̀wẹ̀sì, aisedeedee tí ọtí máa ń fà, àdánù/kí ènìyàn pàdánù nǹkan, aisowo/ìṣòro tó jọ mọ owó, airẹnibase/didawa, kí a máa jẹ́ kí ènìyàn rò pé kò daaato, wàhálà ibaraẹnise, ara riro àti àìsàn, rògbòdìyàn, èébú àti ìṣẹ̀lẹ̀ airotẹlẹ.

Àwọn ènìyàn tí ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ènìyàn kan tí wọ́n gba ẹ̀mí ara wọn tàbí tí wọ́n fẹ́ gba ẹ̀mí ara wọn laipẹ.

Ní oṣù kẹwàá, ọdún 2024, Ìròyìn sọ pé Ọmọlará Bámidélé, arákùnrin kan tí ó jẹ́ ẹni ọdún mejidinlọgọta pa ara rẹ̀ ní ìlú Igburowo, ní ìjọba ìbílẹ̀ Odigbo, ní Ìpínlẹ̀ Ondo.

Àwọn ara ìlú yìí sọ pé wọ́n rí òkú Bámidélé ní ọ̀nà kan pẹ̀lú ohun kan tí wọ́n ń pè ní “Sniper”, ohun kan tí wọ́n fi kẹ́míkà se.

Ní oṣù kẹsàn-án, ọdún 2024, Gabriel Magaji, ọmọ ọdún mejidinlogoji, tí ó ń gbé ní Masaka, ní ìjọba ìbílẹ̀ Karu, ní Ìpínlẹ̀ Nasarawa, pa ara rẹ̀, nítorí pé ìyàwó rẹ̀ ń yan àlè.

ǸJẸ́ LÓÒÓTỌ́ NI PÉ NÀÌJÍRÍÀ NI ORÍLẸ̀ ÈDÈ KẸFÀ TÍ ÀWỌN ÈNÌYÀN TI Ń GBA Ẹ̀MÍ ARA WỌN JÙ NÍ ÀGBÁYÉ?

TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára gbìyànjú láti fi ọ̀rọ̀ wá Akinsulore lẹ́nu wò, ṣùgbọ́n kò fẹ́ jẹ́ kí a mọ ibi tí ó ti rí ọ̀rọ̀ yìí.

Àmọ́sá, àyẹ̀wò tí TheCable se fi ye wa pé, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ tí WHO se wí lórí bí àwọn ènìyàn se gba ẹ̀mí ara wọn, èyí tí àjọ yìí sọ pé àwọn se atunse sí ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù Kínní, ọdún 2024, Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀ èdè kẹtadinlọgọjọ ní gbogbo àgbáyé tí àwọn ènìyàn bíi mẹ́rin ti máa ń gba ẹ̀mí ara wọn nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún.

Àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́wàá tí àwọn ènìyàn ti máa ń gba ẹ̀mí ara wọn jù ní àgbáyé àti bí àwọn orílẹ̀ èdè yìí se tẹle ara wọn ni Lesotho (ìdá mejilelaaadọrin níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn), Guyana (ìdá ogójì níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn), Eswatini (ìdá bíi ọgbọ́n níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn), Republic of Korea (ìdá bíi mọkandinlọgbọn níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn), Kiribati (ìdá bíi mọkandinlọgbọn níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn) àti Micronesia (ìdá mejidinlọgbọn ó lé ní díẹ̀ níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn).

Àwọn orílẹ̀ èdè yòókù ni Lithuania (ìdá mẹrindinlọgbọn ó lé díẹ̀ níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn), Suriname (ìdá marundinlọgbọn ó lé díẹ̀ níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn), Russian Federation (ìdá marundinlọgbọn ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún) àti South Africa (ìdá bíi mẹrinlelogun ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún).

Ayẹwo wa fihàn pé Micronesia ni Orílẹ̀ èdè kẹfà tí àwọn ènìyàn ti ń gba ẹ̀mí ara wọn jù ní àgbáyé.

BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ

Nàìjíríà kọ ni Orílẹ̀ èdè kẹfà tí àwọn ènìyàn ti ń gba ẹ̀mí ara wọn jù ní àgbáyé. Èyí túmọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ tí Akinsulore sọ nípa gbígba ẹ̀mí ara ẹni ní Nàìjíríà kìí se òótọ́.

TAGGED: Fact Check, Fact check in Yoruba, News in Yorùbá, nigeria, Suicide, Suicide Rates

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael December 23, 2024 December 23, 2024
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

FACT CHECK: Is Nigeria 4th fastest-growing economy in the world in 2025?

A viral post claims, based on International Monetary Fund (IMF) projections, that Nigeria ranks fourth…

May 9, 2025

FACT CHECK: How true are Obi’s claims about poverty rate in Nigeria, China and Indonesia?

Peter Obi, Labour Party (LP) presidential candidate in the 2023 elections, sparked a debate with…

May 5, 2025

FACT CHECK: No, Finnish court didn’t approve Simon Ekpa’s extradition to Nigeria

On Tuesday, some social media users and blog sites made a post claiming that a…

April 24, 2025

FACT CHECK: Is Cardinal Arinze eligible to be elected as the next Pope?

A social media user has claimed that Francis Arinze, a Roman Catholic cardinal, is the…

April 21, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Rárá, Jonathan kò sọ pé Tinubu yóò se àṣeyọrí nínú ètò ìdìbò fún Ipò Ààrẹ ní ọdún 2027

Ní ọjọ́ ajé, ọ̀rọ̀ kan to sọ pé Goodluck Jonathan, Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ sọ pé Ààrẹ Bọla Tinubu…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

A’a, Jonathan bai yi hasashen nasarar Tinubu a zaben shugaban kasa na 2027 ba

A ranar Talata ne wani rahoto da ke ikirarin cewa tsohon shugaban kasa Goodluck Jonathan ya yi hasashen nasarar Shugaba…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

No, Jonathan no predict Tinubu victory for 2027 presidential election

On Tuesday, one report wey claim sey former President Goodluck Jonathan predict President Bola Tinubu victory for di 2027 presidential…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

Ḿbà, Jonathan ágbaghị àmà na Tinubu gà-èmérí ńtùlíáka ónyé ísíàlà ǹkè áfọ̀ 2027

N’ubọchị Tuesde, ozi na-ekwu na onye bụburu onye isiala Naijiria, bụ Goodluck Jonathan, gbara àmà na onyeisiala Bola Tinubu ga-emeri…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 19, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?