Dakore Egbuson-Akande, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà Nollywood fi àwọn fọ́nrán kàn sí ojú òpó rẹ̀ lórí ìkànnì ibaraẹnisọrẹ (Instagram). Fọ́nrán náà ṣ’àfihàn ìjàmbá omiya’le, àgbàrá ya ṣọọbu tí ń da àwọn ènìyàn láàmú ni agbègbè Niger Delta orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Dakore ní ontẹle tí ó pọ̀ tó mílíọ̀nù kan lé ní irínwó lórí oun àmúlò ìgbàlódé ayélujára náà.
Òṣèré obínrin náà fí fídíò mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sí ojú òpó rẹ̀ ni ọjọ́ àìkú, ìkan nínú àwọn fọ́nrán wọ̀nyí ṣ’àfihàn ọkọ̀ bọ̀gìnì funfun kan tí ó ń gbìyànjú láti kọjá sódì kejì nínú àgbàrá òjò.
Ṣùgbọ́n, ọkọ̀ náà há sí àárín ọ̀nà lẹ́yìn tí ẹkun omi fìí sí ẹ̀gbẹ kòtò kan. Lẹ́yìn o rẹyin, ọkọ̀ náà bọ́ sí inú kòtò botilẹjẹpe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tó wà ní sàkání ìṣẹ̀lẹ̀ náà pariwo.
“A ti finá sórí òrùlé sùn!!! Ìṣẹ̀lẹ̀ abanilẹru lo ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pàápàá ni Niger Delta, inú mi bajẹ fún orílẹ̀-èdè mi Nàìjíríà. Ni ìgbà wo ni àwọn olùdarí wa máa bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìtọ́jú àwọn ènìyàn?” Egbuson-Akande kọ èyí sí ojú òpó rẹ̀.
Àwọn aṣàmúlò ojú òpó bù ọwọ ìfẹ́ lú fọ́nrán ọkọ̀ bọ̀gìnì yìí ati àwọn fónrán márùn-ún tó s’àfihàn bí àgbàrá òjò se ṣọṣẹ ní àwọn agbègbè kan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ni ìgbà ẹgbẹrun mẹ́fà àti ẹgbẹ̀rin dín ní mọ́kànlélógún (6,779). Kò sí àyè fún àwọn ènìyàn láti wo èsì fún ọ̀rọ̀ náà.
TheCable ṣe ìwádìí fídíò náà, èsì ìwádìí wà nì yìí:
Ifiidiododomulẹ
A se itọpinpin àwòrán àti ẹyin wa (reverse image search) lórí àwòrán tí a gba silẹ láti inú fọ́nrán àkọ́kọ́ yìí nípa lílo Labnol, ohun àmúlò ìgbàlódé tí a fi ń se ìwádìí oríṣun/ibi tí àwòrán àti àwọn mìíràn tó jọọ́ ti wá lórí ayélujára.
Àbájáde ìwádìí wa fihàn pé, fọ́nrán yìí ti wà lórí ayélujára láti ọdún 2017, àwọn olùmúlò sì ti lòó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, láti fi s’àfihàn ẹkun omi ní agbègbè míràn káàkiri àgbáyé. Kódà, wọ́n ti lo fọ́nrán náà fún Tropical Cyclone Dineo, èyí tí ó jẹ́ ìkan nínú afẹ́fẹ́ ìjì líle tó burú jùlọ tó ṣẹlẹ̀ ní iha ìwọ̀ oòrùn ti òkun orílẹ̀-èdè India (south-west Indian Ocean) àti agbede-méjì gúsù (southern hemisphere)
Ìwádìí ìwé ìròyìn TheCable fihàn pé wọ́n gbà fídíò náà silẹ ni Chaman ni ìlú Pakistan, ni ìgbà tí àgbàrá òjò bá ìlú náà fínra ni ọdún 2017.
Ní ìgbà tí a wo fídíò náà ni kíkún, a ríi wí pé àwọn ènìyàn tó n wòran nínú fídíò náà gbìyànjú láti ṣe iranlọwọ fún àwọn èrò inú ọkọ̀ náà.
Àbájáde ìwádìí: Wọn gba fọ́nrán yìí silẹ láti ọdún 2017 ni ìlú Pakistan, kìíse Nàìjíríà bí òṣèré tíátà yìí ti wí.