Ọ̀pọ̀lọpọ̀ atẹjade lórí àwọn ohun ibaraẹnise ìgbàlódé ti sọ pé òjò arọfẹku tàbí òjò omiyale, èyí tó rọ̀ tó kówàhálà bá àwọn ará orílẹ̀-èdè United Arab Emirates (UAE) ṣẹlẹ̀ nítorí pé wọ́n fi kẹ́míkà wá òjò tipátipá.
Ọ̀rọ̀ yìí, tí ó wà lórí X, ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí a mọ̀ síTwitter tẹ́lẹ̀, Facebook, ohun ìgbàlódé ibaraẹnise lórí ayélujáraàti Instagram, ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí àwọn ènìyàn ti máa ń pín àwòrán nǹkan tàbí ti ara wọn, fihàn pé UAE kó èrè òjò tíwọ́n fi tipátipa wá.
ÒJÒ ÀRỌ̀FẸ́Ẹ̀Ẹ́KÚ TÓ RỌ̀ NÍ DUBAI
Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún, ọdún 2024, àwọn ilé wọlẹ̀ nígbà tí òjò tí ó yẹ kí o rọ̀ ní ọdún kan rọ̀ ní ọjọ́ kan sí méjì ní Dubai, tí ó sì fa kí omi ya wọlé, tí ó sì tún fa kí àwọn ènìyàn fi ọkọ̀ wọn sílẹ̀, tíwọ́n sì sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.
Òjò yìí ba iṣẹ́ jẹ́ ní ibi tí àwọn ènìyàn ti ń wọ ọkọ̀ Òfurufú.Àwọn ènìyàn sì sọ pé òhun ni ó fa ikú àwọn ènìyàn bíimọkandinlogun ní Oman, tí ó sì jẹ́ kí ènìyàn méjì sọnù.
Dubai jẹ́ ìkan nínú àwọn àgbègbè tí ó wà lára orílẹ̀-èdè tí a mọ̀ sí UAE. Aginjù ni Dubai. Ó sì jẹ́ ibi tí òjò kò kìí fi bẹ́ẹ̀ rọ̀. Òrùn ibẹ̀ ju òjò ibẹ̀ lọ.
Ooru máa ń pọ̀ ní oṣù kẹfà sí oṣù kẹsàn-án. Oṣù kìíní ọdún niòtútù máa ń pọ̀ jù níbẹ̀.
Láti ọdún 1949, ìgbà tí orílẹ̀-èdè náà bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àkọsílẹ̀ bíìgbà ṣe rí, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sọ pé òjò yìí àti omi tó jẹ́ kó yawọlé ni ó pọ̀ jù.
Àjọ tí a mọ̀ sí National Centre of Meteorology sọ pé òjò náà jẹ́ kí orílẹ̀-èdè náà ní omi. Lára omi yìí sì wọlẹ̀ ṣinṣin.
KÍ NI JÍJẸ KÍ ÒJÒ RỌ̀ NÍ TIPÁTIPÁ?
Eléyìí jẹ́ fífà kí òjò rọ̀ ní tipátipá nípa lílo kẹ́míkà. Àwọn orílẹ̀-èdè tí òjò kò fi bẹ́ẹ̀ máa ń rọ̀ bíi UAE ló máa ń ṣe nǹkan báyìí.
Wọ́n máa ń fa òjò ní àkókò tí wọ́n bá nílò rẹ̀.
Àwọn kẹ́míkà tí wọ́n máa ń lò ni silver iodide, potassium iodide, sodium chloride tàbí dry ice (solid carbon dioxide).
Àmọ́sá, òjò tí a kò fọwọ́ fà ní tipátipá máa ń rọ̀ nígbà tí ohun bíomi bá di nǹkan bíi gaasi tí ó sì padà di omi. Eléyìí ni a mọ̀ síòjò.
ǸJẸ́ FÍFI KẸ́MÍKÀ FA ÒJÒ LÈ FA KÍ IRÚ ÒJÒ YÌÍ RỌ̀?
Àwọn onímọ̀ sayẹnsi sọ pé eléyìí kò lè ṣẹlẹ̀.
Òjò tí ó pọ̀ jù kí ti ọdún 2024 tó rọ̀ ní UAE, rọ̀ ní ọdún 1976.
Ní ìgbà ìfiọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú GB News, ìwé ìròyìn kan níorílẹ̀-èdè United Kingdom (UK), Maarten Ambaum, onímọ̀ nípa ojú ọjọ́ (meteorology) ní University of Reading, sọ pé UAE kò ní ohun èlò tí ó lè fa adúrú òjò tó rọ̀ ní Dubai ní ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kẹrin, ọdún 2024.
Ó tún sọ pé Dubai kò fà òjò tipátipá láìpẹ́, nítorí pé àwọnonímọ̀ tí sọ pé òjò gidi yóò rọ̀.
“UAE ní ohun tí wọ́n lè fi fa òjò. Àmọ́sá, kò sì ohun tí àwọnènìyàn lè lò láti fa irú òjò yìí,” Ambaum ló sọ báyìí.
Ó yẹ kí a tún mọ̀ pé, àwọn tí wọ́n máa ń sọ bí ojú ọjọ́ yóò ṣe rí, lára wọn tí a mọ̀ sí the Global Flood Awareness System (Glofas), èyí tí European Commission ṣàkóso rẹ̀ sọ pé ìkún omiyóò ṣẹlẹ̀ ní agbègbè náà kì òjò yìí tó rọ̀.
Àwon tí wọ́n máa ń sọ bí ojú ọjọ́ yóò ṣe rí yìí máa ń sọ déédéébí ojú ọjọ́ yóò ṣe rí, wọ́n sì máa ń sọ ibi tí ikùn omi yóò gbéṣẹlẹ̀. Tí wọ́n bá sọ pé irú nǹkan báyìí yóò ṣẹlẹ̀, kò sí nǹkan tíàwọn ènìyàn lè ṣe nípa rẹ̀. Ohun tí wọ́n lè ṣe ni pé kí wọ́n kúròní agbègbè náà.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ
TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára bá Taiwo Ogunwumi, onímọ̀ nípa ikùn omi tó lè ya ilé ní Geohazard Risk Mapping Initiativesọ̀rọ̀ láti lè mọ bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe rí. Ó ní pé bí àwọn ènìyàn ṣe ń lo àyíká wọn ló fà á.
Ó sọ pé Biotilẹjẹpe ohun tí wọ́n ní Dubai ṣe yìí lè fa ikùn omi, èyí tí ó túmọ̀ sí pé iye òjò tó rọ̀ ju iye omi tí ilẹ̀ lè fà mu, òjò yìíkò rọ̀ nítorí ohun tí wọ́n ní Dubai ṣe nítorí pé àwọn tí wọ́n máań wo bí ojú ọjọ́ yóò ṣe rí ti sọ pé òjò yóò rọ̀ ní ọjọ́ tí òjòarọfẹku rọ̀ yìí.
“Ohun tí wọ́n ní Dubai ṣe yìí lè fa ikun omi, gẹ́gẹ́bí a ṣe mọ̀ péìdí tí àwọn ènìyàn ṣe máa ń fà òjò tipátipá ni pé kí òjò lè rọ̀ níàwọn agbègbè tí òjò kò sí tàbí tí òjò kò fi bẹ́ẹ̀ ń rọ̀,” Ogunwumiló sọ bayii.
“A kò lè sọ pé ohun tí wọ́n ní Dubai ṣe yìí ló fà ikùn omi nítorípé àwọn tí wọ́n máa ń sọ bí ojú ọjọ́ yóò ṣe rí ti sọ pé òjò yóò rọ̀kí òjò yìí tó rọ̀.”
“Àfọwọ́fa lè fà á. A kò gbọ́dọ̀ fi ohun tí wọ́n ní Dubai ṣe yìí sọpé bí òjò yóò ṣe rí ni eléyìí nítorí pé àwọn ènìyàn kò lo agbegbewọn dáadáa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi.”
Gloria Okafor, olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga ní Nigerian Maritime University, ní ìpínlẹ̀ Delta, sọ pé kii se nǹkan tí wọ́n ní Dubai ṣeni ó fa òjò yìí.
“A kò lè sọ bí ojú ọjọ́ ṣe máa rí. Biotilẹjẹpe ohun tí wọ́n níDubai ṣe yìí lè mú òjò rọ̀, ṣùgbọ́n, òjò eléyìí pọ̀ gan-an,” Okafor ló sọ báyìí.
“Bí àwọn ènìyàn kan ṣe ń lo àyíká wọ́n kò dára. Èyí ló ń fààyípadà ojú ọjọ́ (climate change) tó ń pa àwa ènìyàn lára. Eléyìílè fa irú òjò yìí,” olùkọ́ yìí ló sọ bayi.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Kò sí ẹ̀rí tó dájú tí ó fi yé wa pé ohun tí wọ́n ní Dubai ṣe yìí ló fa òjò arọfẹku tàbí ìkún omi, tí àwọn Yorùbá máa ń pè ní omiyale.